Ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí 100 níbi ìgbéyàwó akọsákọ ní ilé ìtúra kan

Àwọn afurasí

Oríṣun àwòrán, DELTA POLICE COMMAND

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta ti nawọ́ gán àwọn ènìyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó akọsákọ kan.

Ọlọ́pàá ní ilé ìtura kan ní ìpínlẹ̀ Delta ni ọwọ́ òfin ti tẹ àwọn afurasí náà ní nǹkan bíi aago méjì òru lọ́jọ́ Ajé lásìkò tí ìgbéyàwó náà ń lọ lọ́wọ́.

Ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìbálòpọ̀ láàárín akọsákọ tàbí abosábo ló jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin, tí ènìyàn sì lè lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá lórí rẹ̀.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Delta, Bright Edafe nínú fídíò kan lórí ìkànnì Facebook ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹjọ ọdún 2023 ní nǹkan bíi aago kan ọ̀sán ni àwọn òṣìṣẹ́ àgọ́ ọlọ́pàá Ekpa ní wọ́n ń wọ́de ní agbègbè Refinery road nígbà tí ọwọ́ tẹ ọkùnrin kan, Chuks Chinye.

Edafe ṣàlàyé Chuks ní òun tí àwọn ọlọ́pàá fi da dúró ni pé ọkùnrin tó múra bíi obìnrin ni.

Ó ní nígbà tí àwọn ọlọ́pàá da a dúró, ó ní òṣèré tíátà ni òun àti pé láti ìpínlẹ̀ Eko ni òun ti wá sí ìpínlẹ̀ Delta láti wá ya sinimá.

Gbogbo àwọn afurasí náà ní àwọn ko jẹ̀bì ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn.

“Àmọ́ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ ẹ́ nínú dada lọ jẹ́wọ́ pé akọ tó máa ń ṣe bí abo ni òun àti pé ibi ayẹyẹ kan ni òun wá ní ilé ìtura Zee Bolos.”

Àwòrán aṣọ àwọn LGBTQ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ní nígbà tí àwọn dé ilé ìtura náà ni àwọn bá àwọn ọkùnrin tí wọ́n fẹ́ẹ̀ tó igba, tí ọ̀pọ̀ wọn múra bí obìnrin.

Ó fi kun pé òun tó ya àwọn lẹ́nu ni pé àwọn rí àwọn méjì nínú àwọn afurasí náà tí ọ̀kan nínú wọn múra bíi ọkọ ìyàwó, tí ẹnìkejì sì múra bí ìyàwó.

Bákan náà ló ní àwọn tún rí fídíò ibi tí wọ́n ti ń so wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti aya.

Edafe tẹ̀síwájú pé nígbà tí àwọn ṣe àyẹ̀wò àwọn afurasí náà dáadáa, àwọn afurasí mẹ́tàdínláàdọ́rin àwọn afurasí ni àwọn fi sí àhámọ́.

Ó ní gbogbo ìwà láti máa kó àṣà àwọn ará ilẹ̀ òkèrè kò sí ní ìbámu pẹ̀lú àṣà Nàìjíríà àti pé àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ tẹ̀lé òfin orílẹ̀ èdè yìí.

“A ti rí ìṣẹ̀lẹ̀ níbi tí àwọn ọkùnrin àgbàlagbà ti ń fipá bá àwọn ọmọdé ọkùnrin sùn, ó burú tó bẹ́ẹ̀ ní àwìjọ lásìkò yìí, ìdí nìyí tí kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ṣe ní ka fi ojú àwọn afurasí yìí hàn.”

Ó ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí àwọn ni àwọn máa gbé àwọn afuurasí náà lọ sí ilé ẹjọ́.

Ó rọ àwọn òbí àti alágbàtọ́ láti mójútó àwọn ọmọ wọn dáadáa pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ń bárin nítorí ọ̀pọ̀ ìwà báyìí ló máa ń wáyé nípa kíkó ọ̀rẹ́kọ̀̀rẹ́.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn ọlọ́pàá yóò máa mú àwọn ènìyàn fún ìbáṣepọ̀ láàárín akọsákọ.

Ní ọdún 2018 ni wọ́n mú James Brown, tó ti di gbajúmọ̀ ní orí ayélujára lásìkò yìí, ní ilé ìtura kan ní Egbeda, ìpínlẹ̀ Eko fún ẹ̀sùn kan náà.

Àwọn bíi ọgọ́ta ni wọ́n mú lásìkò náà ṣùgbọ́n àwọn afurasí náà ní àwọn ọlọ́pàá kò bá àwọn kí àwọn máa ṣe ohunkóhun tó lòdì sí òfin pé àwọn kàn ń ṣe ayẹyẹ lásán ni.