Ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP fòfin de Kwankwaso àti àwọn míì fún oṣù mẹ́fà

Aworan Rabiu Kwankwaso

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/DrRabiuKwankwaso

Awọn agbagba ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party ti kede pe awọn ti fofin de oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa, Sẹnẹtọ Rabiu Musa Kwankwaso lori ẹsun pe o hu iwa to tako agbekalẹ ẹgbẹ.

Bakan naa ni ẹgbẹ ọhun tun fofin de ẹka to n ri si ọrọ isẹ ninu ẹgbẹ naa.

NNPP wa kede awọn olori ẹgbẹ tuntun eyi ti Dokita Agbo Major yoo ṣe alaga le lori, Ogini Olaposi gẹgẹ bi akọwe ẹgbẹ ati awọn mejidinlogun mii.

Ifofin de yii ni wọn kede pe yoo wa fun oṣu mẹfa gbako.

Ikede naa wa ninu ohun ti ẹgbẹ fi ransẹ lẹyin ipade apapọ to ṣe ni ile itura kan niluu Eko.

Ti a ko ba gbagbe, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹjọ ni ẹgbẹ naa fofin de oludasilẹ ẹgbẹ, Dokita Boniface Aniebonam.

Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, akọwe awọn agbagba ẹgbẹ NNPP, Babayo Muhammed Abudulahi fẹsun kan Kwankwaso lori ibaṣepọ rẹ pẹlu Aarẹ Bola Tinubu, oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ati oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi lai gba asẹ lọwọ ẹgbẹ.

Abdullahi ni ẹgbẹ ti yọ Kwankwaso kiro gẹgẹ bi olori ẹgbẹ lorilẹede Naijiria.

"Iwe ti Kwankwaso ati awọn ẹgbẹ bi The National Movement (TNM) ati National Association of Government Approved Freight Forwarders, (NAGAFF) buwọlu ni ko ni ipa kankan mọ.

"Ẹgbẹ ri ẹri to daju pe Kwankwaso jẹbi ẹsun pe o tako ofin to dirọ mọ agbakalẹ ẹgbẹ oṣelu wa.

"Oṣu mẹfa ni igbesẹ yii ti ẹgbẹ yoo fi pari iwadi ti wọn se .

"Ẹgbẹ ti iwe ti Kwankwaso tọ wọbọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu NNPP ni o ti tako, to si si nnkan miiran ju ki ipinya wa lọ."