Àlàyé lórí ohun tó ṣokùnfà ìtúká ìgbéyàwó Ninalowo àti ìyàwó rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajugbaja oṣere tiata, Bolanle Ninalowo. lọjọ Ẹti kede pe oun ati iyawo rẹ, Bunmi Ninalowo ti tu igbeyawo wọn ka.
Ninu ọrọ to gbe sori opo ayelujara rẹ, Ninalowo ni oun ti setan lati gba pe opin ti de ba irinajo oun ari iyawo oun bayii.
Bakan naa lo ni igbesẹ yii yoo fi aye silẹ fun ọjọ iwaju rere.
"Ni bayi, Mo ti gba pe opin ti de ba irinajo yii. Igbesẹ yii ni lati fi aye silẹ fun ọjọ ọla rere
"Igbeṣe yii ba awọn ọmọ mi lọkan jẹ sugbọn ti a nilo fun ọjọ ọla rere."
"Mo ni lati tọju ilera mi nitori n ko le wa laye titi laelae"
Ninalowo tẹsiwaju pe o ṣeeṣe koko fun oun lati se itọju ara oun ati ilera fun igbayegbadun gbogbo mọlẹbi.
O tẹsiwaju pe ni Ọlọrun san oun ni ẹsan to tọ si oun, ko si tun fi iya jẹ oun to ba jẹ pe oun ṣe aṣe,ase
"Ni igbẹyib, gbogbo wa ni ẹri ọkan maama da lamu lori igbesẹ wa.
"Ni bayi, mo ni lati se ounto tọ nitori awọn ọmọ mi nitori mo jiya pupọ lati ma jẹ ki iyapa wa laarin wa.
"Irinajo yoo fun ni okun ati agbara si nitori mo ri mo nilo ifọkanbalẹ lai itẹsiwaju ninu aye mi
"Emi ati iyawo mi ti pinni lati lọ ni ọtọọtọ."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ọdun 2019 ni Ninalowo ati Iyawo rẹ pada lẹyin ti igbeyawo ọdun mejila wọn tuka
Ninalowo ati Iyawo rẹ kede fun araye lọdun 2019 pe awọn ti pada gẹgẹ bi tọkọtaya lẹyin ti wọn kọkọ tuka fun ọdun meji.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Ileeṣẹ iroyin ThePunch ni oun pade iyawo oun lọdun 2004 lọrilẹede Naijiria.
Gẹgẹ bi oṣe salaye, Ninalowo oun ati iyawo rẹ lọ si Amẹrika lọdun 2007, ti wọn si se igbeyawo lorilẹede Amẹrika
Bolanle Ninalowo ati iyawo rẹ gbe fun ọdun mejila ti ipinya to waye laarin wọn.
Ninu alaye rẹ, o ni ounh ni oun fa ipinya naa nitori oun ko ni suuru, ti oun si ni imọ ara ẹni nikan.
Awọn mọlẹbi tọkataya naa lo dasi ọrọ ituka naa, ti wọn si rọ awọn ololufẹ mejeeji lati pada.
Sugbọn bayi, ipinya keji tun ti waye laarin wọn.
Tani ni Bolanle Ninalowo?

Oríṣun àwòrán, Instagram/iamnino_b/
Ọmọ bibi Ikorodu nipinlẹ Eko ni Gbajugba oṣere naa.
O gbe lorilẹede Naijiria funb ọdun mẹẹdogun ko to lọ si Chicago ni orilẹede ni bi to tun gbe fun ọdun mẹẹdogun miiran.
Yatọ si ilẹ tiata ti ọpọ mọ si, o tun ni ile isẹ ọkọ tita
Bolanle Ninalowo ti gba ọpọlọpọ ami ẹyẹ fun ipa to n ko ninu ere tiata.












