Ninalowo ra ilé ńlá fún aya rẹ̀ láti sàmì ọdún 18 lẹ́yìn ìgbéyàwó

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajugbaja oṣere Yoruba, Bolanle Ninalowo ti ra ile nla alaja fun iyawo rẹ, Bunmi ni orilẹede Amerika.

Ninalowo lo fi iroyin ayọ yii lede ni oju opo ikansiraẹni Instagram rẹ.

Nibẹ lo ti ṣafihan ile nla naa pẹlu iyawo rẹ ati awọn mọlẹbi rẹ ti wọn n jade lati inu ile wọn

Ọlọrun lo ṣe eyi eniyan kọ - Ninalowo

Awọn tọkọ-taya naa ni wọn n ṣe ayẹyẹ ọdun mejidinlogun ti wọn ṣe igbeyawo wọn.

Ninu akọle to fi si oju opo Instagram naa lo ti ni Ọlọrun lo ṣe eyi kii ṣe eniyan rara.

Ninalowo tun ṣeleri pe lẹyin eleyii agbegbe Beverly Hills nibi ti awọn ilumọọka eniyan wa loriṣirisi ni ohun yoo ra ile si fun iyawo ohun lẹyin eleyii.

O tun fikun un pe oun sa n ṣiṣẹ nitori naa ko si ohun ti yoo ṣoro lati ṣe fun oun.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

‘’Ko si igbeyawo to pe amọ tọkọ-taya gbọdọ ṣiṣẹ lati jẹ ki igbeyawo yọri si ayo’’

Saaju ni Ninalowo ti gba awọn ololufẹ rẹ ni imọran lori igbeyawo.

O ni bio tilẹ jẹpe igbeyawo oun ko tilẹ dara ni ibẹrẹ, awọn fi ori tii, titi to fi dara fun awọn mejeeji.

O ni igbeyawo ti yoo dara le ma dan to bi o ṣe yẹ, amọ tọkọ-taya gbọdọ gbiyanju lati ri pe igbeyawo naa ni ojutu.

Bakan naa ni o gba tọkọ-taya ni imọran lati sọrọ si ita, ki igbeyawo laarin awọn mejeeji lee gun rege.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2