Ohun tó yẹ kí o mọ̀ rèé nípa ìpàdé G20 Summit tí yóò wáyé lọ́sẹ̀ yìí...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn adari ni orilẹede ogun ni agbagbe yoo ma parapọ si ibi ipade ọlọdọọdun wọn ti yoo waye ni ilu Bali, lorilẹede indonesia.

Ọjọ Iṣẹgun, Oṣu Kọkanla, ọdun yii ni ipade naa yoo waye.

Lara ohun ti wọn yoo ma jiroro le lori ni ọna abayọ lati mu ibugbooro ba ọrọ aje ni agbaye lẹyin ajakalẹ aarun Covid-19.

Kini ipade G20 ati idi ti wọn fi gbe kalẹ?

Apapọ ẹgbẹ G20 naa ni wọn mọ si awọn orilẹede ti idokowo wọn gbe pẹẹli soke julọ ni agbeye.

Ọdun 1999 ni wọn da kalẹ lẹyin eto ọrọ aje kan to dẹnukọlẹ nigba naa lọhun ni Ila oorun Asia.

Ajọ naa lo ni orilẹede mọkanlelogun ati ajọ European Union, amọ wọn ma n gba orilẹede Spain ni alejo lasiko ipade wọn.

Ajọ G7 to gbooro si lo bi G20, eleyii to mu ki orilẹede bii China, Brazil ati India darapọ mọ wọn.

Laarin awọn orilẹede yii, ida marunlelọgọrin eto idokowo ni awọn ni wọn n pese, ti wọn si tun ni awọn araalu to pọju lọ.

Kini wọn fẹ jiroro le lori?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni saa yii, ohun ti ajọ G20 yoo ma jiroro le lori yoo kọja ọrọ eto ọrọ aje lọ lati sọrọ lori iyipada oju ọjọ, ipeṣe ina ọba ati idariji awọn gbese ni agbaye to fi mọ owo ori awọn ileeṣẹ nla ni agbaye.

Ọdọọdun lasiko ipade naa ni aarẹ tuntun yoo jẹ fun Ajọ naa.

Gẹgẹ bi aarẹ ọdun yii, orilẹede Idonesia fẹ ki wọn ṣe ipero ọdun yii ni Bali, ko si da le ori eto ilera ni agbaye.

Bakan naa ni wọn yoo jiroro lori ọna ati mu eto ọrọ aje pada si ipo lẹyin ajakalẹ aarun Coronavirus lagbaye.

Amọ orilẹede Ukraine n beere fun ki wọn yọ Russia kuro ninu ajọ naa pẹlu bi wọn ṣe pinlẹ ogun pẹlu Ukraine.

Awọn orilẹede to wa ni G20...

  • Argentina
  •  Australia
  • Brazil
  • Canada
  •  China
  •  France
  • Germany
  • India
  • Indonesia
  • Italy
  • Japan
  • Mexico
  • Russia
  •  Saudi Arabia
  • South Africa
  • South Korea
  • Turkey
  • United Kingdom
  • United States
  •  European Union.