Ọwọ́ NDLEA tẹ bàbá ìsàlẹ̀ àwọn tó ń gbé oògùn olóró, gbẹ́sẹ̀lé kóró tramadol 497,900

Adekaz Hotels

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ọwọ ajọ to n gbogun ti egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, ti tẹ ẹni to ni ile itura Adekaz Hotels, Ademola Afolabi Kazeem, ti ọpọ mọ si Alhaji Abdallah Kazeem Muhammed lori ẹsun egboogi oloro.

NDLEA ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Femi Babafemi fi lede sọ pe awọn mu afurasi naa lẹyin ọjọ mẹwaa ti awọn ti n wa.

Ọjọ kinni, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii ni wọn kede pe awọn n wa afurasi naa lẹyin to kọ lati yọju si ọọfisi wọn nigba ti wọn ti kọkọ fi iwe pe lẹyin ṣaaju.

NDLEA ni iwadii awọn fi han pe afurasi naa lo n ṣe agbatẹru awọn to n gbe oogun oloro cocaine lọ silẹ Dubai atawọn orilẹ-ede mii lagbaye.

Bi ọwọ NDELA ṣe tẹ Adekaz

Ọwọ tẹ ọkunrin ọhun lẹyn ti ọwọ tẹ ọkan lara awọn ọmọlẹyin rẹ, Bolujoko Muyiwa Babalola, to jẹ awakọ ero BRT ni papakọ ofurufu ilu Eko, ti ọkunrin ọhun si sọ pe Adekaz ni baba isalẹ oun.

Ko din ni iwọn ẹẹdẹgbaarun giramu (900 grams) oogun oloro cocain ti wọn ka mọ Bolajoko lọwọ.

Atẹjade naa ni lẹyin ti NDLEA fiwe pe Adekaz to si kọ lati yọju si ọọfisi awọn ni wọn gba ile ẹjọ lọ.

Lara awọn nnkan ti wọn bere lọwọ ile ẹjọ naa ni pe ko gbẹsẹle awọn ile afureasi ọhun to wa niluu Eko ati ilu Ibadan.

Bẹẹ naa ni wọn tun bẹ ile ẹjọ ọhun lọwẹ pe ko gbẹsẹle owo Adekaz ti iye rẹ to okòólénígba dín mẹ́tà miliọnu naira (₦ 217,000,000.00) to wa ni bankii.

Yatọ si ọkunrin naa, NDLEA tun fi ṣikun ofin mu awọn afurasi mii ni ipinlẹ Ogun, Osun, Ondo ati Edo, ti wọn si gbẹsẹle oniruru oogun oloro bii igbo ti iwọn rẹ to tọọnu meje abọ.

NDLEA tun gbẹsẹlekoro oogun tramadol ti iye rẹ di diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ni papakọ ofurufu ilu Eko.