'INEC kò ṣe ìwádìí Bola Tinubu, irọ́ lásán ni àwọn tó ń sọ bẹ́ẹ̀ kiri ń pa'

Aworan Tinubu ati atederu atẹjade naa

Oríṣun àwòrán, BAT/INEC

Ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC ti sọ pe oun ko tan ina iwadi si oludije ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo aarẹ lọdun 2023, Aṣiwaju Bọla Tinubu gẹgẹ bi awọn kan ṣe n sọ.

Ajọ INEC ṣalaye yii ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Satide.

Iroyin jade laipẹ yii nipa ọrọ ile ẹjọ kan lorilẹede Amẹrika to kan oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu lọdun 1993 eleyi ti awọn alatako rẹ n tẹnumọ kaakiri bayii.

“A ko ṣe iwadii oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu rara,” ni ọrọ ti atẹjade naa ti Festus Okoye to jẹ adari ẹka alukoro ni ajọ INEC gbe sita."

Idi ti INEC fi fọ aṣọ ọrọ mọ lori iroyin naa

Laipẹ yii lẹyin ti iroyin ẹjọ naa jade lawọn kan tun bẹbẹ si nii gbe e kiri pe ajọ INEC ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣe iwadii Tinubu ni ibamu pẹlu ohun ti ile ẹjọ naa gbe sita.

Awọn akọroyin labẹle n sọ pe ile ẹjọ kan ni Chicago n darukọ Aṣiwaju Bọla Tinubu lori ẹjọ gbigbe ogun oloro kan to waye niwaju rẹ lọpọ ọdun sẹyin.

Eyi lo mu ki INEC tete bọ sigboro aye lati sọ pe ko si ohun to jọ eyi o.

“Atẹjade kan n kaakiri eyi ti awọn kan n sọ pe lati ọdọ wa lo ti wa n kaakiri lori ayelujara lati ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun 2022 to n sọ pe ajọ eleto idibo yii n wadii ọrọ ẹsun iwa ọdaran kan lori ọkan lara awọn oludije fun ipo aarẹ ni idibo apapọ to n bọ.

“A fẹ fi da gbogbo aye loju pe kii ṣe ọdọ ajọ INEC ni atẹjade yii ti wa, a ko si ṣe ohunkohun ti wọn n sọrọ nipa rẹ yii.”

Ọgbẹni Okoye ni iṣẹ awọn aṣinilọna ni atẹjade naa, ati pe ayederu patapata ni.

Ki ni awọn eeyan Tinubu sọ lori ọrọ yii?

Igbimọ ipolongo fun Bọla Tinubu ti sọ pe ọpọ igba lawọn ololufẹ Tinubu pẹlu igbimọ ipolongo rẹ ti bọ sita lati sọ pe ko si ohun to jọ iroyin yii.

“Iroyin ofege yi” ti ajọ INEC ṣẹṣẹ tun ṣiṣọ loju otitọ yii ni eyi to tun ṣẹṣẹ waye.

Amofinagba Festus Keyamo, to jẹ Agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo Bọla Tinubu ti sọ pe ki ẹnikẹni maṣe fa orukọ oludije ẹgbẹ oṣelu APC naa sinu ọrọ ipẹjọ ti wọn n sọ lorilẹede Amẹrika ọhun.

“Ko si bi idalẹbi ṣe le wa niwọn igba ti Aṣiwaju kii ṣe olujẹjọ ninu ẹjọ naa”

Festus Keyamọ sọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle kan

“Mo n tuu sọ fun igba igba pe Aṣiwaju ko si ninu awọn ti wọn pe lẹjọ ninu ipẹjọ naa>”

Bakan naa lo tun fi oju opo Twitter rẹ bu ẹnu atẹ lu atẹjade ayederu ti awọn kan fi sita naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post