Wo àwọn ọna tí o le gbà tó bá jẹ́ pé alábágbé ilé rẹ ń yọ ọ lẹnu

Oríṣun àwòrán, Others
Ọpọ igba ni eeyan si maa n ṣe alabapade irufẹ awọn aladugbo bayii ni ibikibi ti o ba yan lati maa gbe.
Awọn agbegbe kan tilẹ wa to jẹ wi pe awon alabagbe yii gan ni yoo mọọmọ maa wa wahala kiri.
Ohun to buru ju ni pe ki ẹ tun jijọ maa Pin ile iwẹ, ile igbọnsẹ ati yara idana pọ lawọn ile olowo kekere bii kọju si mi ki n kọju si ọ ti awọn ọpọlọpọ maa n pe ni "face me I face you"
Bi o ti wulẹ ko ri o ko gbọdọ gba wahala wọn laaye lati di alaafia ti rẹ lọwọ.
Awọn iwa wahala bayii lee jẹ awon iwa bii idọti, dida ato ile ru, apejẹ alariwo, ija ojoojumọ at'awọn iwa ti ko bofin mu miran.
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pọkún ètò ààbò ní òpópónà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn nítorí ìjínigbé
- Ẹnikẹ́ni tó ń lo pátákó alákọ̀ọ́lé "No parking" ń fi gbaga òfin ṣeré - Ọlọ́pàá Nàìjíríà
- Èmi ní mo fún Afeez Abiodun ní orúkọ 'Ọwọ' tó ń jẹ́ -Yemi My Lover
- Àtúpalẹ̀ àwọn àròsọ márùn ún nípa àyípadà ojú ọjọ́ tí kìí ṣe òótọ́
- I-gbákejì olórí ẹgbẹ́ Ilana Ọmọ Oodua kọ̀wé fi ipò sílẹ̀
- Amnesty International korò ojú sí ìdájọ́ ile-ẹjọ Kano lórí àwọn tó ṣe Tiktok fi fi Ganduje ṣe àwàdà
- À-wọn jàndùkú dáná sun ọ́fíìsì INEC nípìnlẹ̀ Ogun
Bawo ni o ṣe le yanju ọrọ yii?
Fi aala silẹ laarin yin:
Yala wọn fi iwa wọn han lati ibẹrẹ ni tabi rara, tete yaa fi aaye silẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Maṣe b'awọn sere ju. Ni kete ti o ba rii pe wọn ti n kọja aye wọn,
Maṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ohunkohun to ba da yin pọ.
Jẹ ki wọn tete mọ ohun ti o le gba ati eyi ti o ko ni gba ki o to di wi pe wọn n fi obọ lọ ẹ.
Maa ba awon alugbo rẹ ti iwa wọn dara sọrọ:
Bi awọn naa ba n korira irufẹ iwa ti iwọ naa korira wọnyi, yoo fun ọ ni awijare lori awọn to n ṣe nnkan wọnyi ni
Nitori pe yoo tumọ si pé wọn a le ti ẹ lẹyin nigba ti o ba nilo ki o koju iwa aitọ tabi lọ sọdọ baba onile yin.
O ṣeeṣe ki aladugbo yii ni awọn imọran ti o le fi yanju awọn arijagba alabagbe naa.
Maa fi apẹrẹ rere le'lẹ;
bi o ba fẹ pe akiyesi alabagbe rẹ si ohun kan ri iwọ gan ti o.n sọrọ ko si se nnkan yoo, yoo le diẹ.
O n kọminu lori bi alabagbe rẹ ko ṣe n fọ Ile igbọnsẹ, bẹẹ iwọ pẹlu ki n tọju rẹ.
Maṣe fun wọn laaye lati lo alebu rẹ fi gbe iwa aitọ wọn lẹyin.
Ẹ kọkọ sọrọ ni tubi inubi naa:
Rii pe ẹ ti kọkọ sọrọ naa ki o to pariwo lee. Ba wọn sọrọ lori awọn nnkan ti o n ṣe ti inu rẹ ko dun si.
Koda o le yannana rẹ fun un ni ẹyọ kookan.
O tilẹ tun le fun ni ní amoran lori ọna abayọ gan pẹlu.
Da wọn l'ẹkun iwa wọn.
Gbaradi fun wahala to le lori eyi.
Bi ohun ti o ba n ba wọn sọ ba ṣi n ṣẹlẹ, yẹra fun won
ki o si dẹkun ṣiṣe bii oninuure bi o ba wa jẹ pe ko si ọna mira ti o le gbe ọrọ gba ti ko ni da wahala silẹ rii pe o wi ti ẹnu rẹ ki o ye wọn yekeyeke.
Lẹyin eyi fi ọrọ to onile tabi aṣoju rẹ leti:
Bí ọrọ ba de oju kan, o o nilo lati dẹkun ṣiṣe bi omugọ, ki o si pe onile.
Onile le máa fẹ gbọ nipa idamu rẹ, amọṣa bi ọrọ naa ba ti n kọja agbara rẹ, Onile lo gbọdọ da si ọrọ naa o.
- K-unle Afolayan sọ̀rọ̀ sókè nípa nípa sinimá Anikulapo
- Mo gbàgbọ́ nínú tewé tegbò, àsàsí, mo sì gbàgbọ́ nínú -back to sender- torípé ... - Sefiu Alao
- Ojútì, ìrẹ́nijẹ àti ìyà àìkàwé nídìí iṣẹ́ tíátà ti ọ̀pọ̀ òṣèré padà sí fásitì
- -Ọkọ mi kò ráyè wọ ojú ara mi láti já ìbálé lẹ́yìn oṣù kan ta ṣe ìgbéyàwó-
- Òǹwòran bọ́ọ̀lù tó kú di 174, 191 ló fara gbọgbẹ́
- ̀Irìnàjò ojú irin Abuja-Kaduna yóò gbérasọ padà nínú oṣù yìí


















