Cop 27, Climate change: Àtúpalẹ̀ àwọn nípa àyípadà ojú ọjọ́ tí kìí ṣe òótọ́

Aworan akawe pulanẹẹti lori ẹrọ foonu alagbeka.
    • Author, Marco Silva
    • Role, BBC Climate Disinformation Specialist

As COP27 gets under way, we look at some common misconceptions around climate change.

O ṣe pataki ki awọn adari orilẹ-ede lagbaye wa ọna abayọ si iṣoro ayipada oju ọjọ, amọ pupọ awọn eeyan lo n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri ori ayelujara nipa ọrọ naa.

Ni bayii ti ipade ajọ agbaye lori ọrọ ayipada oju ọjọ, COP27 n lọ lọwọ ni Egypt, iye eeyan to n wa imọ nipa ayipada oju ọjọ lojojumọ n pọ si.

Bi awọn eeyan ṣe n wa imọ nipa ọrọ yii naa ni iroyin ẹlẹjẹ nipa rẹ n pọ si.

Idi ree ti a n ṣe n kọ iroyin yii lati layin lọye.

Ohun ti awon eeyan n sọ: Ko si ohun to n jẹ ayipada oju ọjọ

Awọn ti wọn sọ pe ko si ohun to n jẹ ayipada oju ọjọ maa n gbagbọ pe awọn alagbara kan lo ko ara wọn sibi kan lati maa sọ ọrọ naa lọna ati fi awọn eeyan sinu ibẹru.

Awọn mii gbagbọ pe awọn to n pariwo ayipada oju ọjọ n lo ọrọ naa lati kowojọ si apo ara wọn tabi lati din ẹtọ awọn eeyan lati ṣe ohun to wu wọn ku.

Amọ ṣa, ko si ẹri kankan lati gbe igbagbọ wọn naa lẹyin.

Ẹwẹ, ida mọkandinlọgọrun (99%) awọn onimọ sayẹnsi lagbaye lo gbagbọ pe lootọ ni ayipada oju n bẹ, ewu nla si ni ayipada oju ọhun jẹ fun awọn ọmọ eeyan.

Lati ọdun 1850 ni agbaye ti n mooru ju ti tẹlẹ lọ, eyi to mu ewu lọwọ fun gbogbo ẹda alaaye to n gbe ninu aye.

Osise kan ni agbegbe atang International Zhangjiakou Power Station ni Zhangjiakou ni China lo n fi ina ilewọ ge ọpa irin .

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nigba ti won ba n jo afẹfẹ gaasi , tabi eedu, tabi epo rọbi ni wọn maa n da ọpọ afẹfẹ to lewu sita ni eyi to n ba afẹfẹ jẹ.

Ohun ti awon eeyan n sọ: Iṣoro awọn oyinbo alawọ funfun ni ayipada oju ọjọ

Ayipada oju ọjọ n waye nitori awọn eefi to n lọ lati ori ilẹ aye si oke ninu afẹfẹ, eyii ti o n di oru to n jade lara oorun mu, to si n mu ile aye gbona giri.

Awọn orilẹ-ede to lowo julọ lagbaye, bii ilẹ Gẹẹsi, Germany ati ilẹ Amẹrika lo jẹbi ọrọ naa julọ nitori awọn ileeṣẹ nla nla ti wọn ni.

Fun idi eyi, ọpọ eeyan lawọn orilẹ-ede ti ko rọwọ họri lo gbagbọ pe iṣoro awọn orilẹ-ede nla nikan ni ọrọ naa.

Amọ iwadii ti fi han pe awọn orilẹ-ede ti ko rọwọ họri gan ni iya ayipada oju ọjọ yii yoo jẹ julọ nitori wọn ko ni awọn ohun ati eto to yẹ lati koju rẹ.

Lara awọn wahala ti ayipada oju ọjọ yii ti da silẹ ni ẹkun omi to waye ni Pakistan lẹnu lọọlọ yii.

aworan iwaju patako COP27 lopopona to lọ si ibudo ti ipade isokan agbaye naa ti n waye ni agbegbe Egypt's Red Sea resort of Sharm el-Sheikh.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, COP27 ni ipade ẹlẹẹkẹtadinlọgbọn iru rẹ ni ajó ìṣọkan agbaye to n waye ni i Sharm el-Sheikh, ni Egypt, lati 6 si 18 osu kokanla odun 2022

Ohun ti awon eeyan n sọ: Ayipada oju ọjọ le ṣe awa eeyan loore

Fun awọn ilẹ ti otutu ti maa n mu julọ lagbaye, oru le dabi aanfani nla fun wọn, amọ fun igba diẹ ni.

Fun apẹrẹ, lọdun 2003, Aarẹ Putin ti Russia sọ pe o n tumọ si pe owo ti awọn eeyan n na lori aṣọ to n gba otutu yoo dinku diẹ, bakan naa ni yoo ṣe anfani fun awọn ohun ọgbin atawọn agbẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn onimọ sọ, ayipada oju ọjọ yoo na gbogbo agbaye ni owo ti iye rẹ to tiriliọnu mẹrinlelaadọta dọla ($54tr.)

Wọn tun sọ pe awọn ilẹ oko ni iha Middle East le di aṣalẹ laipẹ ti ajọ agbaye ko ba tete wa ojutu si ayipada oju ọjọ naa.

Lawọn orilẹ-ede ti otutu ti maa n mu pupọ bii Rusia ati Siberia ni ọpọ awọn agbegbe wọn ti n gbẹ bayii.

Eye Adelie Penguin kan lo ba tente sori idi omi lebaa ago faranse ni Dumount d'Urville ni iwo oorun Antarctica.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ikilọ Antarctic Peninsula bo se n yipada ni ayika Antarctica.

Ohun ti awọn eeyan n sọ: Omi okun ko kun ju ti atẹyinwa lọ, igbi omi okun lasan lo n halẹ

Gẹgẹ bii iwadii kan ti ajọ US Space Agency ati NASA ṣe, ayipada oju ọjọ ti n mu ki awọn ilẹ ti yinyin di si maa yọ, eyii to n mu awọn omi okun.

Iwadi ti fi han pe kii kan n ṣe pe awọn igbi omi kan n halẹ lasan ni, okun ti n fẹ si nitori ayipada oju ọjọ.

Awon olugbe Obagi nipinle Rivers n rin we koja ninu agbara ni Naijiria leyin ti ojo arọọrọda rọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awon olugbe Obagi nipinle Rivers n rin we koja ninu agbara ni Naijiria leyin ti ojo arọọrọda rọ.

Ohun ti awọn eeyan n sọ: Ọrọ ayipada oju ọjọ ti bọ sori

Oniruru awọn iroyin to n jade lori ọrọ ayipada oju ọjọ le mu ko da bi pe o ti bọ sori, amọ ọrọ ko ri bẹẹ.

Ọrọ naa ko ni pẹ ju ti awọn adari orilẹ-ede lagbaye ba tete ṣe ojuṣe wọn lati koju ọrọ ayipada oju ọjọ yii.

Awọn onimọ nipa ayipada oju ọjọ ti sọ pe lara awọn ọna abayọ naa ni pe ki awọn orilẹ-ede ṣe adinku si iye eefin ti wọn n tu jade si oju afẹfẹ.