Mo gbàgbọ́ nínú tewé tegbò, àsàsí, mo sì gbàgbọ́ nínú "back to sender" torípé ... - Sefiu Alao

Àkọlé fídíò, Sefiu Adekunle Alao: Mo bá ara mi nídì iṣẹ́ orin ni,
Mo gbàgbọ́ nínú tewé tegbò, àsàsí, mo sì gbàgbọ́ nínú "back to sender" torípé ... - Sefiu Alao
    • Author, Emmanuel James
    • Role, Video Journalist

Adekunle Sefiu Alao gangan ni orukọ rẹ amọ Sefiu Alao ni ọpọlọpọ mọ olorin yii si.

Lagbo awọn olorin Fuji Yoruba, eekan ni Sefiu Alao jẹ ti ọpọlọpọ eeyan si fẹran awọn orin rẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ni pẹlu BBC Yoruba, Sefiu mu wa rinrinajo bo ṣe bẹrẹ ninu iṣẹ to yan laayo.

O ranti gbogbo igba to bẹrẹ orin kikọ ni kekere lasiko to ṣi wa ni ileewe girama.

sefiu alao

Nibayii, agba ọjẹ ni to si ti lo ọdun to le ninu ogoji ninu iṣẹ orin kikọ yii ṣugbọn igba akọkọ to ṣe awo orin jade gan ni ọdun 1990.

“Ko to di pe mo ṣe rẹkọọdu lọdun 1990, mo ti n lọ Cotonou, gba Ajaṣẹ lọ si Gabon”.

“Nigba táwa bẹ̀rẹ̀, orin Krìstẹ́nì ní wọ́n ka Juju sí tí wọ́n sì ka Fuji sí ti Musulumi”.

Alhaji Sefiu ni bi oun ṣe n lọ ile Keu naa loun n kọ Fuji pọ nigba naa.

Nigba to mẹnu ba awọn nnkan ti oju rẹ ti ri lẹnu iṣẹ orin yii, iroyin ko to afojuba ni.