Wo iye ìgbà tí àyípadà ti bá owó Nàìjíríà láti ọdún 1959

Oríṣun àwòrán, CBN
Ní ọjọ́rú ni ilé ìfowópamọ́ àgbà ilẹ̀ Nàìjíríà, CBN kéde pé àwọn fẹ́ mú àyípadà bá owó #200, #500 àti #1,000.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí irú àyípadà báyìí yóò máa bá owó Nàìjíríà.
Láti ọdún 1959 tí wọ́n ti ṣe ìdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà láti máa pèsè owó fún àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè yìí ni onírúurú àyípadà ti ń wáyé sí àwọn owó tí Nàìjíríà ń lò.
Ní ọdún 1962 ni àyípadà àkọ́kọ́ wáyé sí owó tí Nàìjíríà kọ́kọ́ pèsè lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí wọ́n ṣe owó lọ́dún 1959.
Lára àwọn owó tí Nàìjíríà kọ́kọ́ pèsè gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè fúnra rẹ̀ lọ́dún 1959 ni pọ́ùn márùn-ún, pọ́ùn kan, ṣílè mẹ́wàá, àti ṣílè márùn-ún.

Oríṣun àwòrán, CBN
Ní ọdún 1965 ni àyípadà bá àwọn owó yìí láti ṣàfihàn rẹ̀ pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti wà ní òmìnira ara rẹ̀ pẹ̀lú àkọlé “Federal Republic of Nigeria” lórí àwọn owó náà dípò “Federation of Nigeria” tó wà l;órí àwọn èyí tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde.

Oríṣun àwòrán, CBN
Lẹ́yìn ogun abẹ́lé tó wáyé lọ́dún 1968 ni ìjọba Nàìjíríà tún mú àyípadà bá àwọ̀ owó pépà ìyẹn ṣílè márùn-ún, pọ́ùn kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àmọ́ àwọn owó ẹyọ wà bó ṣe wà.

Oríṣun àwòrán, CBN
Ní ọdún 1973 ni Nàìjíríà gbé àrà ọ̀tun yọ nípa ṣíṣe owó Náírà àti Kọ́bọ̀, ọdún yìí ni Nàìjíríà láti fòpin sí lílo owó ṣílè àti pọ́ùn.
Àwọn owó tí wọ́n pèsè nígbà náà ni náírà mẹ́wàá, náírà márùn-ún, náírà kan àti àádọ́ta kọ́bọ̀ tó jẹ́ owó pépà, tí owó ẹyọ sì jẹ́ ogún kọ́bọ̀, kọ́bọ̀ mẹ́wàá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Oríṣun àwòrán, CBN
Náírà márùn-ún

Oríṣun àwòrán, CBN
Lẹ́yìn tí wọ́n kọ́kọ́ pèsè àwọn owó náírà àti kọ́bọ̀, ẹ̀ẹmèjì ni àyípadà ti bá owó yìí.
Àyípadà àkọ́kọ́ wáyé nígbà tí wọ́n fi orí olóògbé Sir Abubakar Tafawa Balewa tí wọ́n sì tún pàrọ̀ àwọ̀ owó náà lọ́dún 1984.
Ọdún 2007 ní wọ́n pàrọ̀ owó náírà márùn-ún kúrò ní owó pépà di náílọ̀nù.
Náírà mẹ́wàá

Oríṣun àwòrán, CBN
Lẹ́yìn tí wọ́n kọ́kọ́ pèsè àwọn owó náírà mẹ́wàá, ẹ̀ẹmèjì ni àyípadà ti bá owó yìí.
Àyípadà àkọ́kọ́ wáyé nígbà tí wọ́n fi orí olóògbé Alvan Ikoku síbẹ̀ tí wọ́n sì tún pàrọ̀ àwọ̀ owó náà sí pupa pọ́ńbélé.
Ọdún 2007 ní wọ́n pàrọ̀ owó náírà márùn-ún kúrò ní owó pépà di náílọ̀nù.
Ogún náírà

Oríṣun àwòrán, CBN
Ní ọdún 1977 ní Nàìjíríà kọ́kọ́ pèsè owó ogún náírà níbi tí wọ́n ti kọ́kọ́ fi àwòrán ọmọ Nàìjíríà sórí owó fun ìgbà àkọ́kọ́.
Orí ọ̀gágun Muritala Muhammed tí wọ́n pa ni wọ́n fi orí rẹ̀ sí owó náà.
Ní ọdún 2007 ni wọ́n pàrọ̀ owó náà sí owó náílọ̀nù tó sì wà fún níná títí di àsìkò yìí.
Àádọ́ta náírà

Oríṣun àwòrán, CBN
Nínú oṣù Kẹwàá, ọdún 1991 ni ìjọba tún gbé owó tuntun mìíràn jáde ìyẹn àádọ́ta náírà.
Lọ́dún yìí kan náà ni wọ́n sọ náírà kan àti àádọ́ta kọ́bọ̀ di owó ẹyọ láti kún àwọn owó ẹyọ tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ bí i 25k, 10k àti 1k.
Ní báyìí 50 náírà náà ti wà ní owó náílọ̀nù bí i ti 5, 10, 20 náírà.
Ọgọ́rùn-ún náírà

Oríṣun àwòrán, CBN
Ní ọdún 1999 ní wọ́n kọ́kọ́ pèsè owó ọgọ́rùn-ún náírà èyí tí wọ́n ya orí olóògbé Obafemi Awolowo sórí rẹ̀.
Ọdún 2014 ní wọ́n ṣèàyípadà sí owó yìí láti ṣàmì ọgọ́rùn-ún ọdún tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti wà .
Yàtọ̀ sí àwọ̀ rẹ̀ tí wọ́n yípadà, wọ́n tún ṣe àyípadà sí àwòrán tí wọ́n yà sẹ́yìn rẹ̀ kúrò ní àpáta Zuma sí àwọn ènìyàn tí inú wọn ń dún, tí wọ́n ń jó.
Ní báyìí tí CBN tún ti kéde wí pé àwọn yóò máa ṣe àyípadà sí àwọn owó bí i #200, #500 àti #1,000 BBC Yorùbá yóò máa mú ìròyìn wá fún-un yín ní kété tí àwọn àyípadà náà bá ti jáde.












