Ìdí tí mi ò fi bínú sí Osinbajio mọ́ lẹ́yìn tó gbé àpótí ìbò takò mí – Tinubu

Oríṣun àwòrán, @MobilePunch
Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ti sọ pe oun ti dariji igbakeji Aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajolẹyin to gbe apoti ibo Aarẹ tako oun.
Tinubu lo sọ ọrọ naa niluu Kano lasiko to n ba awọn alatilẹyin Osinbajo lasiko eto idibo abẹnu ẹgbẹ naa sọrọ.
Gẹgẹ bii ohun ti Tinubu sọ, eeyan maa n tọrọ idariji lọwọ Ọlọrun to si n maa gbọ, nitori naa oun gbọdọ dariji Osinbajo lẹyin to gbe apoti ibo tako oun.
O ni oun ko ni ikunsinu kankan si Osinbajo, oun si ti ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Mi o binu si Osinbajo
Tinubu fi kun pe oun ti ṣabẹwo si Osinbajo nilẹ rẹ lẹyin idibo abẹnu naa, wọn si tun ti ba ara wọn sọrọ lasiko ipade awọn minisita kan.
O ni “Mi o binu si, mo ti lọ sile rẹ lẹyin idibo abẹnu ti a ṣe, mi si tun ri lasiko eto kan ti Aarẹ gbe kalẹ.”
“Ẹni to ba n bẹbẹ fun idariji ẹsẹ lọdọ Ọlọrun gbọdọ jẹ ẹni to n dariji ẹlomiran, ti o ko ba le dariji eeyan, bawo ni Ọlọrun ṣe le dariji iwọ naa?
“O ti tan ninu mi.”
Nibi ipade naa ni adari ẹgbẹ Drone Marshall Support Group, Alwan Hassan, ti rọ Tinubu lati ṣiṣẹ papọ pẹlu Osinbajo atawọn miran ti wọn dije lati di Aarẹ ninu ẹgbẹ naa lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii.
Hassan ni “A ti ṣe ipade pẹlu awọn rẹ, atawọn ọta rẹ gan pẹlu.”
“A fẹ ki iwọ at igbakeji Aarẹ ati gbogbo awọn to ba o dije ninu eto idibo abẹle naa maa ṣiṣẹ pọ loju gbogbo araye, lootọ ni wọn dije amọ iwọ lo jawe olubori.”
Hassan fi da ẹgbẹ naa loju pe awọn yoo ṣiṣẹ fun APC ninu idibo ọdun 2023.
Ti ẹ ko ba gbabe, yatọ si Osinbajo,awọn eeyan mẹtala mii bii Ahmad Lawan, Rotimi Amaechi, Dave Umahi, ati Yahaya Bello lo gbe apoti ibo abẹnu naa amọ Tinubu fidi gbogbo wọn janlẹ.












