Ṣé pé àwọn "Revrend Sisitá náà ń wo "Blue" fíìmù lórí ayélujára? – Pope Francis dá sọ̀rọ̀

Even nuns watch porn, Pope says

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Poopu ijọ Aguda, Pope Francis ti kilo fun awọn alufaa ijọ naa, lọkunrin ati lobinrin lati sọra fun wiwo awọn fiimu ibalopọ lori ayelujara nitori irufẹ iwa bẹẹ yoo pa ina ẹmi ninu wọn.

Poopu lo sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ kan lori bo ṣe yẹ ki awọn eeyan maa lo ikanni ibaradọrẹ lori ayelujara niluu Vatican.

O ni wiwo fiimu ibalopọ ko dara rara, ọpọ eeyan lo si n wo irufẹ awọn fiimu bẹẹ laye ode oni.

Gẹgẹ bii ohun ti poopu Pope Francis sọ, “O lewu fun ọpọ eeyan… to fi mọ awọn alufa ọkunrin ati obinrin.”

O sọ fun fun awọn alufa na pe “Ẹmi Eṣu maa n gba ibẹ wọ inu aye eeyan.”

Nipa bo ṣe ki awọn eeyan maa lo oju opo ayelujara lọna ti yoo so eso rere, Pope Francis ni ki wọn maa lo ni iwọntuwọnsi, ki wọn si maṣe fi akoko ṣofo lori rẹ.

O ṣalaye pe “Ọkan mimọ, to n fun Jesu laaye lojojumọ ko le maa wo fiimu ibalopọ ko si wa bakan naa.”

Lẹyin naa lo gba awọn eeyan naa niyanju lati fa awọn fidio ibalopọ yọ kuro lori foonu wọn, ki wọn ma ba ko sinu idanwo.”

Yatọ si ijọ Aguda, pupọ ni awọn ijọ kaakiri agbaye lo koro oju si wiwo gbogbo ohun to jọmọ fiimu ibalopọ.