Ìdí tí mó fí takò Tinubu gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ rèé- Dele Momodu

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Ọkan lara awọn agba ọjẹ ninu ẹgbẹ oselu PDP, Dele Momodu ti salaye idi to fi tako oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Momodu ninu atẹjade kan ni ko ki n ṣe igba akọkọ rẹ ti oun yoo sọrọ síta lori Tinubu. O ní oun nifẹ Tinubu sugbọn oun ko rira rẹ gẹgẹ bii oloselu.

"Ko ki n ṣe irọ pe mo nifẹ Tinubu sugbọn mo tako ọna isejọba rẹ gẹgẹ bii oloselu. Ko ki n ṣe igba akọkọ rẹ ti ma sọrọ nita pe nko fẹ fẹran Tinubu gẹgẹ oloselu.

"Ni bi ọdun diẹ sẹyìn, mo ma ri ọkunrin takuntakun fun awọn araalu sugbọn ọkunrin yii fi awọn eeyan rẹ lẹ nigba isoro. Gbogbo awọn to yika ni ko ni anfani lati ba sọ otitọ ọrọ."

Momodu ni Tinubu fẹ lo gbogbo ọna lati di aarẹ Orilẹede Naijiria lẹyin to padanu awọn alatilẹyin rẹ.

"O mọ ara rẹ sugbọn o fẹ di aarẹ Orilẹede Naijiria pẹlu agídí sugbọn awọn ọmọ Orilẹede Naijiria ni anfani lati ṣe akoba fun erongba Tinubu.

"Nigba ti Tinubu jẹ Gomina, mo gbarukudi lati oke okun nigba to awọn eniyan to n dibo pe awọn nifẹ rẹ mọ ra."Nigba ti o pin ile fun awọn akọroyin ni Ipinlẹ Eko, mo kọ lati gba iwe naa nítorí mo fẹ ominira mi."

Àpàṣẹ wà á ni Bola Tinubu yóò jẹ́ tí o bá wọlé gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ Nàìjíríà

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Bakan an ni Dele Momodu tun ṣe ni ikilọ fun awọn ọmọ orile-ede Naijiria pe ki wọn yago ninu didi ibo wọn fun oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu nitori apasẹ wa ni yoo jẹ to ba di aarẹ.

Momodu, ẹni to jẹ oludasile iwe royin Ovation Magazine, sísọ loju ọrọ naa nigba to n kopa ninu ifọrọwerọ kan lori Channels TV lana.

O ni Gomina ana ni Ipinlẹ Eko ni jẹ apasẹ to fẹ ki gbogbo eeyan ma bọ gẹgẹ bii olorì wọn, ti wiwọ ile rẹ gẹgẹ bi aarẹ Orilẹede Naijiria yoo ṣe ọpọlọpọ ifasẹyin fún orilẹede Naijiria.

Gẹgẹ bii o ṣe sọ, o ni Aarẹ ile igbimọ aṣòfin nigba kan rí, Bukola Saraki, awọn gomina ipinlẹ Eko nigba kan rí, Akinwunmi Ambode, Babatunde Fashola àti awọn igbakeji Gomina rẹ wa lara awọn to fi oju wina iwuwasi Tinubu si ìṣejọba.

"Tinubu nnkan ni mo mọ to ni igbakeji Gomina meji tí awọn mejeeji si ko sinu wahala."Mo na ika si bi o ṣe jẹ apasẹ wa. Emi ko ni fọwọsowọpọ pẹlu apasẹ wa. Ko si ninu iwe temi."