Ìjàmbá iná sọ ní Ọ́fíìsì WAEC l’Eko

Ọ́fíìsì WAEC

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Iroyin to n tẹ wa lọwọlọwọ sọ pe ijamba ina ṣẹlẹ ni ile iṣẹ to n boju to idanwo aṣekagba ile ẹkọ giga, West African Examination Council (WAEC).

Awọn iroyin kan sọ pe awọn oṣiṣẹ afara jọ panapana kan ti wa nibẹ amọ a ko mọ aridaju eleyi.

Bakan naa ni awọn oniroyin to ba diẹ lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa sọrọ jabọ pe o da bii pe mọnamọna ẹlẹtiriiki lo ‘sokunfa ijamba ina ọhun.

“A saba maa n wọ iṣẹ ni ago meje abọ owurọ amọ nigba ti a wa ninu ọfiisi la dede rii ti ina kan bugbamu”.

Ko tii si aridaju iroyin kankan boya awọn eeyan farapa tabi dukia bajẹ titi di asiko ti a ko iroyin yii jọ.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ wa fun yin bo ba ṣe n lọ.