Irú ààbò tó wà ní Naijiria lásìkò yìí ló tì dara jù láti ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn - Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, Federal ministry of information and culture
Ijọba apapọ Naijiria ti ni ki awọn araalu fi ọkan balẹ lori eto aabo wọn.
Minisita fun eto iroyin ati aṣa, Alhaji Lai Mohammd, lo sọ ọrọ idaniloju naa nibi idanilẹkọ ọlọdọọdun ti ajọ UNESCO to n waye nilu Abuja.
O sọ ọrọ naa lẹyin ọjọ meji ti ileeṣẹ aṣoju America nilu Abuja kilọ fun awọn araalu lati maa ṣọra nitori awọn ikọlu ti awọn agbesunmọmi fẹ ṣe.
Lai Mohammed sọ pe awọn ileeṣẹ eto aabo Naijiria n ṣe gbogbo nkan to yẹ lati daabo bo ẹmi awọn ọmọ Naijiria ati ajoji to n gbe nibẹ.
O ni lọwọlọwọ, agbara awọn agbesunmọmi ti dinku, nitori ogun ti ileeṣẹ ologun gbé ti wọn.
“Aabo to wa ni orilẹ-ede wa lasiko yii lo tii dara ju lati nnkan bi asiko diẹ sẹyin.”
Alhaji Mohammed sọ pe lootọ ni awọn oniṣẹ ibi yoo maa wa gbogbo ọna lati da alaafia ati aabo Naijiria ru, “ṣugbọn awọn oṣiṣẹ alaabo wa koju osunwọn lati pe aabo fun ọmọ ilu ati ajoji”.
Ẹ ṣọ́ra o! US Embassy, Àjọ DSS fi ìkìlọ̀ síta lórí ìdúnkokò ìkọlù nílùú Abuja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ alaabo ọtẹlẹmuyẹ DSS ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati ma sun asunpiye, ki wọn si maa fi to awọn oṣiṣẹ alaabo leti nipa awọn afurasi ọdaran to wa ni agbegbe wọn.
Ikede naa waye lẹyin ọjọ diẹ ti ileeṣẹ aṣoju ilẹ America fi ikilọ ranṣẹ si awọn ọmọ orilẹ-ede naa nipa awọn ikọlu to ṣe e ṣe ko waye ni awọn agbegbe kan ni Naijiria, paapaa nilu Abuja.
Ileeṣẹ aṣoju Amẹrika kilọ pe ki wọn o ṣọra fun irinajo ti ko ba ṣe pataki lasiko yii.
Iwe iroyin abẹle the Punch jabọ pe alukoro DSS, Peter Afunanya, sọ ninu atẹjade kan to fi sita ni alẹ ọjọ Aiku pe, oriṣiriṣi iwe ibeere ni ajọ naa ti ri gba nipa ikilọ ti ileeṣẹ aṣoju America nilu Abuja fi sita ni ọjọ Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.
“Ẹ o ranti pe ajọ DSS paapaa ti fi iru awọn ikilọ bẹẹ sita ri. Amọ ẹ̀ ma jẹ́ ki ẹru bayin rara, nitori pe gbogbo igbesẹ to yẹ lati dena iru ikọlu bẹẹ la ti gbé.”
Ṣugbọn o ni ki awọn araalu funra wọn ma a kiyesara, ki wọn o si ma a fi ohun gbogbo ti wọn ba fura si gẹgẹ bi iwa ọdaran tabi irinsi awọn oniṣẹ ibi ni ayika wọn to awọn oṣiṣẹ alaabo leti.
Ọgbẹni Afunanya sọ pe DSS ti n ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ alaabo yooku lori ọrọ yii.
Ọpọlọpọ iṣẹlẹ lo ṣi n waye, eyi to n kọ awọn eeyan lominu.
Awọn ikede yii n waye lasiko ti ipenija aabo n koju Naijiria.
Ninu oṣu Kẹjọ, ni awọn olugbe ilu Abuja sọ pe awọn gbọ iro ibọ nitosi apata Zuma to wa nilu naa.
Bakan naa, ninu oṣu Keje, ni awọn agbebọn kan kọlu ọgba ẹwọn to wa ni agbegbe Kuje nilu Abuja.
Ko si din ni irinwo ẹlẹwọn ti awọn alaṣẹ sọ pe o salọ lasiko ikọlu naa.
Awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn sọ pe ẹlẹwọn mẹrin kú, mẹrindinlogun si farapa.
Awọn ọdaran nla, to fi mọ awọn afurasi agbesunmọmi, awọn oloṣelu lo wa ninu ọgba ẹwọn naa lasiko ikọlu.
Minisita fun eto aabo, Bashir Magashi sọ fun awọn akọroyin pe o ṣeeṣe ko jẹ ikọ Boko Haram lo ṣe ikọlu na, nitori pe ọmọ ikọ naa mẹrinlelọgọta to wa ni ẹwọn lo sa kuro.











