A ti tú akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Chibok méjì míì sílẹ̀ àmọ́ wọ́n ti bímọ ... – Ológun

Oríṣun àwòrán, Chibok
Ileeṣẹ ologun Naijria ti fi ọrọ sita pe awọn tun ti doola ọmọbinrin meji lara awọn akẹkọbinrin Chibok ti awọn agbesunmọmi jigbe nipinlẹ Borno.
Yana Pogu ati Rejoice Sanki ni awọn mejeji yii.
Adari ikọ apapọ ọmọ ogun Ila Oorun Ariwa ti wọn n pe ni Hadin Kai, Ọgagaun Christopher lo ṣipaya eyi fun awọn oniroyin to si tun fidi rẹ mulẹ fun BBC.
O sọ fun BBC pe ọkan lara awọn obinrin mejeji naa ni wọn ri ni ọjọ Kọkandinlọgbọn Oṣu Kẹsan ti wọn si baa pẹlu ọmọ mẹrin.
Yana Pogu lo wa ni nọmba ikọkandinlogun akọsilẹ awọn akẹkọbinrin ileewe Chibok ti wọn ji gbe nigba naa lọhun.
Ipo wo ni wọn ba awọn mejeji?
Ọgagun Christopher ṣalaye pe ọmọ obinrin meji to ti bi ati ọmọ ọkunrin ikoko meji to ṣẹṣẹ bi ni wọn ri pẹlu rẹ.
Adari ọwọ ogun keje ni Maiduguri, Ọgagun Shuaibu Waidi to fi wọn han fun awn oniroyin sọ pe wọn yoo ko wn le ijọba ipinlẹ Maiduguri lọwọ lẹyin ti wọn ba ṣe ayẹwo ilera tan pẹlu awọn ọmọ wọn.
Waidi sọ pe bi awọn ṣe ri Pogu ni ilu Mairari, ijọba ibilẹ Bama ninu oṣu Kẹsan naa ni awọn ri Rejoice Sanki to wa ni nọmba aadọrin lori akọsilẹ ni ọjọ Keji Oṣu Kẹwa ọdun 2022 pẹlu mọ rẹ meji ni agbegbe Kawuri.
Musa fi kun un pe ibudo tuntun ti wọn ṣi lati gba awọn ọmọ ẹgbẹ boko Haram to ba ronupiwada to si juwọ lẹ wa ni agbegbe ti aabo rẹ daju ti awn ologun si lee moju to o.
Laarin oṣu marun, ikọ ologun Naijiria ti doola akẹkọbinrin Chibok mẹtala ninu ọọdunrun-din-mẹrindinlọgbọn ti wọn ji gbe lọ lati ọdun 2014. Nkan bii mẹrindinlọgọrun lo ṣi wa lahamọ bayii.















