Ìbẹ̀rẹ̀ akòbá fún ìlera ni kí oorun rẹ̀ má pé wákàtí márùn-ún

Ẹni to sun sori ibusun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Broadcast Journalist

Ki eeyan maa sun oorun ti ko ju wakati marun-un lọ ni oru, le fa aisan to le ni aadọta, gẹgẹ bi awọn onimọ ṣe sọ.

Lootọ ni aisan le mu idiwọ ba oorun, ṣugbọn ki eeyan o ma sun daadaa paapaa jẹ ewu funra rẹ.

iwadii ijinlẹ kan ti PloS Medicine ṣe lori ilera ati oorun sisun awọn oṣiṣẹ ijọba ni UK.

Ninu iwadii naa, wọn beere lọwọ ẹgbẹrun mẹjọ eeyan pe wakati melo ni wọn fi n sun ni oru lojoojumọ.

Bakan naa ni awọn kan lara wọ aago ọwọ to n tọpinpin iye wakati oorun wọn.

Ẹwẹ fun iwadii naa, wọn tun ṣe ayẹwo awọn aisan bii itọ ṣuga, jẹjẹrẹ ati aisan ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba ọhun, pẹlu ayẹwo oore-koore fun ogun ọdun.

Awọn nkan ti iwadii fihan ree:

Awọn to n sun oorun wakati marun-un tabi kere ju bẹẹ lọ, ti ọjọ ori wọn si ti to aadọta, wa ninu ida ọgbọn ewu lati ni oriṣiriṣi awọn aisan, ju awọn to n sun fun wakati meje.

Awọn to ti pe ẹni aadọta ọdun, ti kii sii sun daadaa tun ni ewu iku ju awọn yooku wọn lọ, paapaaa awọn aisan gbẹmi-gbẹmi.

Ọjọ ti pẹ ti awọn onimọ nipa ilera ti n polongo pe oorun wakati meje si mẹjọ lo ṣe anfaani julọ fun ara.

Bẹẹ naa ni awọ̀n oluwadii kan lati Fasiti ilu London ati Fasiti ilu Paris, ṣe sọ.

Ki ni idi ti a fi n sun?

Awọn onimọ sayẹnsi sọ pe oorun sisun ma n ran ọpọlọ lọwọ lati le ṣiṣẹ daadaa, o si tun ma n fun agọ ara paapaa ni isinmi, ija fafa ati okun.

Oorun sisun tun jẹ ọna kan ti ọpọlọ fi n fọ ara rẹ mọ́.

Awọn imọran to le mu ki o ri oorun sun daadaa

Ẹni to sun sori tabili

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Rii daju pe o ṣiṣẹ karakara ni ọsan, tabi ṣe oriṣiriṣi awọn nkan to mu ki o lo ara rẹ, amọ din wọn ku to ba ti n to asiko oorun. Máa sun oorun ọsan, to ba ṣeeṣe.
  • Bẹrẹ, ki o jẹ ko mọ ọ lara lati maa sun oorun alẹ ni akoko kan naa lojoojumọ
  • Bakan naa, ri i daju pe yaara ibusun rẹ wa ni ipo to bojumu, ti yoo jẹ ki oorun tete kun ọ
  • Asiko ti o ba fẹ sun, kii ṣe asiko lati maa tẹ foonu rẹ lori ibusun
  • Mu adinku ba tabi ki o fi opin si awọn nkan mimu to ni eroja caffeine ati ọti ninu, ti asiko oorun ba ti n sunmọ
  • Ti oorun ko ba tete wa, gbiyanju lati ka iwe titi oorun yoo fi maa kun ọ diẹdiẹ
  • Ti o ba jẹ oniṣẹ alẹ, gbiyanju lati sun diẹ ṣaaju asiko iṣẹ. Ki o si rii daju pe o sun daadaa lẹyin ti iṣẹ ọsẹ naa ba pari.