Ṣé lóòtọ́ọ́ ní pé ọmọ tí Bàbá rẹ̀ kán lápá ti kú?
Agbẹnusọ fún ilé ìwòsàn bá BBC sọ̀rọ̀ láti ṣe àfọ̀mọ́ ìròyìn yìí, àbọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Dorothy Nnaji
Iroyin ti gbalẹ kan ni ọsan ọjọ Ẹti pe ọmọ tuntun ti baba rẹ kan lapa, ti wọn sisẹ abẹ fun, ti jade laye.
Amọ Ile iwosan to n tọju ọmọ naa ti kede pe irọ to jinna sootọ ni pe ọmọ naa ti ku.
Nigba to n ba BBC sọrọ lori foonu, agbẹnusọ fun ile iwosan naa, Anchonu Jecinta salaye pe saka ni ara ọmọ naa ya, ti oun si ri ni aago mejọ alẹ ọjọ Ẹti.

“Nigba ti mo ka iroyin lori ayelujara pe ọmọ naa ti ku, ọkan mi bajẹ, mo si sare lọ sile iwosan lati mọ nnkan to n sẹlẹ.
Amọ mo ri iya ọmọ naa, to gbe lọwọ, to si n fun ni ọyan.
Ko si ohunkohun to se ọmọde ọwọ naa, ara rẹ ya gaga, ti ko si si ohun to se iya ati ọmọ nigba ti mo ri wọn lalẹ ọjọ Ẹti.”
Anchonu ni oun n pada lọ sile ni, nigba ti oun gbọ iroyin naa, eyi to gbe oun pada amọ iya ati ọmọ lo wa ni alaafia.
Ìyá ọmọ oṣù méjì tí bàbá rẹ̀ já apá rẹ̀ lóru ti ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ṣe ṣẹlẹ̀

Iya to bi ọmọ oṣu meji ti wọn ni baba rẹ fi ibinu lu titi to fi padanu ọwọ ọtun rẹ ri n pe fun idajọ ododo fun ọmọ naa.
Oun ati ọmọde jojolo naa wa nile iwosan nla ti ijọba apapọ, FMC nilu Owerri lẹtin ti awọn dokita ni lati ge apa ọmọ oṣu meji naa nitori iṣẹlẹ ọhun lati lee doola ẹmi rẹ.
Ni irọlẹ ọjọ Ẹti ọjọ kokanlelogun oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ. Iya rẹ si sọ pe oun gbe ọmọ naa ti baba rẹ ni pe ki oun sare lọ tọ ni ọmọ ohun fi bẹrẹ si nii sunkun.
“Igbe ọmọ yii lo mu mi sare pada sinu ile nibi ti mo ti ba baba rẹ to n fi ibinu naa lẹgba nitoripe o n sunkun. Nina yii lo pọ to bẹẹ to fi ṣeṣe lọwọ ọtun rẹ.
'Ọwọ ọmọ mi ti n run jijẹra nigba taa de ile iwosan'
Baba rẹ wa lo rọba ti wọn fi n di nnkan lati di ọwọ ọmọ naa, to si n sọ fun mi pe ki n fi ọkan balẹ, ọmọde ni, ọwọ naa yoo tete san pada.”
Iya ọmọ yii ni baba ọmọ naa ti oun ati ọmọde jojolo naa pa mọ ile, o si gba foonu ibanisọrọ rẹ pẹlu idukukulajamọni pe oun yoo ṣe kisa fun oun bi oun ba gbiyanju sọ fun aladugbo kankan.
Amọṣa lẹyìn ọjọ meji to ti wa ninu ile yii, lo gbiyanju lati jade lẹyin ri baba ọmọ yii jade sita. Igba yii lo fi ohun to ṣẹlẹ to awọn aladugbo leti ti wọn si baa wa owo ọkọ ro fi saregbe ọmọ naa lọ si ile iwosan.
‘Ọwọ ọmọ naa ti n run jijẹra nigba ti wọn maa fi gbe e de ileiwosan'
Iya ọmọ naa ni ile iwosan mẹta ọtọọtọ loun de ti wọn ko gba ọmọ naa lọwọ oun nitori wọn ni agbara awon ko ka ohun to n ṣe ọmọ naa mọ, ki oun to wa gbe e lọ si ileiwosan nla Federal Medical center, FMC to wa nilu Owerri.
Ki ni awọn Dokita sọ fun wọn?

Dokita Chiedozie Mbalewe, dokita akọṣẹmọṣẹ iṣẹabẹ egungun nileewosa. FMC Owerri ṣalaye fun BBC pe nigba ti wọn gbe de ti awọn si ṣe ayẹwo ọwọ ọmọ naa, awọn rii pe ọwọ naa ti bẹrẹ si nii run, o si ti jẹra nitori egbo to ni lẹyin lilu naa.
Nitori naa, lati lee doola ẹmi ọmọde jojolo naa ki kokoro to ti wọ inu ọwọ to ti jẹra naa ma baa wọ inu ẹjẹ rẹ, nitori awọn rii pe ọwọ naa ti yi awọ pada, o si ti jẹra, lawọn fi ge e kuro lati ibi ejika rẹ.
“A rii pe ọwọ ọmọ yii ti jẹra nitori pe ẹjẹ ko ri aye ṣan daadaa, ko gbe ọwọ naa, ọwọ naa si wa n dun gidi gan, I si ti n dudu bakanbakan.
A rii pe ko si bi a ṣe le ri ọwọ naa doola mọ, ko si nnkan ti a le ṣe nipa rẹ mọ, bi a ba si fi silẹ, awọn kokoro idibajẹ to wa ninu ọwọ naa nitori pe o ti n jẹra lee rapala wọ inu ẹjẹ rẹ ki o si tun da wahala miran silẹ. Nitori eyi la fi wa ba iya ọmọ naa sọrọ pe yoo dara ti a ba ge ọwọ ọmọ naa ki awọn kokoro idibajẹ naa to wọ inu ara rẹ yoku “
Dokita Mbalewe sọ pe lẹyin ti wọn ge ọwọ ọtun ọmọ naa kuro, ara ọmọde jojolo naa ti n balẹ, bayi awọn ti n tọju egbo ọwọ ti wọn ge naa. Awọn si n wo asiko ti wọn yoo tu wọn silẹ . Amọṣa o ni awọn n fikuluku pẹlu ẹka to n ri si itọju araalu nileewosan naa lati mọ nnkan ti wọn yoo ṣe fun ọmọ naa ati iya rẹ.
Iya ọmọ naa ni oun ati baba ọmọ yii ti n fẹ ara awọn, ti awọn si n gbe pọ lati nnkan bii odun mẹrin oun ko si lero pe yoo le ṣe iru nnkan to ṣe naa lati lu ọmọ ọkunrin awọn to je ọmọ oṣu meji titi to fi maa padanu ọwọ rẹ.
Wọn ṣi n wa baba to fi hanga aṣọ na ọmọ oṣu meji naa, biotilẹjẹpe iya ọmọ naa ti lọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.
Àlàyé rèé lórí bí bàbá ìkókó oṣù méjì ṣé bínú fà apá ọmọ já torí pé o sunkún lóru

Oríṣun àwòrán, NAWOJ IMO
Iroyin naa kọkọ dabi iranran ṣugbọn nigba ti imọlẹ bẹrẹ si ni tan si ohun to ṣẹlẹ niṣe lọpọ ọmọ Naijiria gbarata.
Ọrọ taa n sọ yi niṣe pẹlu iroyin pe baba kan binu fa apa ọmọ rẹ oṣu meji ja nitori pe o da oorun mọ loju loru.
Ọpọ awọn ajafẹtọmọniyan lo ti n kesi ijọba ipinlẹ Imo nibi ti iṣẹlẹ ti waye pe ki wọn paṣẹ fawọn agbofinro lati mu baba yi.
Ọwọ ọmọ taa lo ja naa la gbọ pe wọn pada ni lati ge kuro nitori ipalara ati inira ti iwa baba yi ko ba apa ọmọ naa.
Dorothy Nnaji,olori awọn akọroyin obinrin ni Imo fidi ọrọ mulẹ fun BBC pe Baba ọmọ yi binu fa apa ọmọ naa ja tori pe o n sunkun loru.
Arakunrin naa ti iroyinsọ pe orukọ rẹ n jẹ Confidence Amatobi jẹ ẹni ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn ti iya ọmọ naa Favor si jẹ ẹni ogun ọdun.
Miracle lorukọ ọmọ ikoko oṣu meji yi.
Amatobi si jẹ ọmọ ilu Amurie ni ijọba ibilẹ Isu ni ipinlẹ Imo.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Iroyin sọ pe iya ọmọ naa Favor ṣalaye pe lọjọ Keje oṣu Kẹwaa ọdun yi ni oun gbe ọmọ naa le baba rẹ lọwọ pe oun fẹ ṣe igbọnsẹ.
Favor ni ibẹ loun wa ti ariwo ọmọ ti mu ki oun pada wọ yara lati mọ nkan to ṣẹlẹ.
Nibẹ lo ni oun ti ri wi pe ọkọ rẹ ti da ọmọ lapa toun si ri pe ọwọ naa ti wu.
Nigba ti o beere lọwọ Amatobi pe ki lo ṣẹlẹ, alaye ti o ṣe ni pe ọmọ naa ko jẹ ki oun ri oorun sun loru pẹlu ẹkun rẹ.
Amatobi lẹyin igba naa wa fi okun ati igi so ọmọ naa lapa nigba to ri wi pe apa naa ti kan.
Ki awọn araadugbo ma ba mọ ohun to ṣẹlẹ, Favor ni Amatobi ti awọn mọ inu iyara fun odindi ọjọ meji.
Lẹyin ọjọ meji yi ni Favor sọ pe oun ribi sa jade ti oun si kesi awọn araadugbo to pada ba a gbe ọmọ naa lọ si ile iwosan.
Amatobi ti na papa bora
Ile iwosan ti wọn gbe ọmọ lọ ni wọn ti ri wi pe apa ọmọ naa ti daranjẹ ti o si n ko inira ba ikoko naa.
Lati le fi doola ẹmi ọmọ naa ni wọn fi pada wa ge apa naa eyi to sọ ọmọ di alaabọ ara bayi.
BBC gbiyanju lati ba alukoro ọlọpaa ipinlẹ Imo sọrọ ṣugbọn titi di akoko ta fi n ko iroyin yi jọ, ko gbe ipe lori ago rẹ.
A ko ti ribi ba iya ọmọ naa Favor sọrọ.
Kini kan to dajubayi ni pe baba ọmọ naa to hu iwa laabi yi ti na papa bora eyi to mu ki awọn ajọ ajafẹtọmọniyan lorisi ṣe nkesi ijọba lati paṣẹ kawọn agbofinro ṣawari rẹ.












