Rishi Sunak di olóòtú ìjọba UK tuntun

Wọ́n ti kéde Rishi Sunak bí i olóòtú ìjọba kẹtàdínlọ́gọ́ta lẹ́yìn tó ṣèpàdé pẹ́lù Ọba Charles.
Oba Charles ránṣẹ́ pé Sunak ní òwúrọ̀ òní láti mọ bí Sunak yóò ṣe ṣàkóso ètò ìjọba.
Sunak ni olóòtú ìjọba kẹta tí orílẹ̀ èdè UK yàn nínú ọdún yìí.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó kúrò ní ààfin Buckingham, Sunak ní ìpèníjà gbòógì tó ń bá UK fínra ni àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé.
Ó ní òun mọ̀ nípa ìpèníjà yìí èyí àjàkálẹ̀ àìsàn COVI9-19 kó bá orílẹ̀ èdè náà àti pé àwọn gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà láti kojú ìpèníjà yìí ní kíákíá.
O fi kun pé òun gbà pé Liz Truss tí òun gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ ṣe àwọn àṣìṣe kan ṣùgbọ́n òun kò da lẹ́bi nítorí ìlọsíwájú orílẹ̀ èdè àwọn ló ń wá.
Sunak ní òun gbóríyìn fun lórí akitiyan rẹ̀ láti mú àyípadà ọ̀tun bá orílẹ̀ èdè àwọn.
Ó wá sọ àrídájú rẹ̀ pé i’sẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ lẹ́yẹ ò sọkà láti wá ojútùú sí gbogbo àwọn ìpèníjà náà.
Ó tẹ̀síwájú pé òun máa ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru láti ri dájú pé àwọn gbé àwọn ètò tí yóò mú àyípadà ọ̀tun bá okoowò àti ìgbé ayé àwọn ènìyàn ní orílẹ̀ èdè náà.
Bákan náà ló ní òun máa ri dájú pé ìṣọ̀kan orílẹ̀ èdè náà kò yinjẹ rárá.
Sunak ni òun ìjọba máa ń ṣíṣe ìjọba èyí tí àwọn àrá ìlú yóò ní ìgbẹkèlé nínú rẹ̀ ní òkúnkúndùn nítorí òun mọ bí nǹkan ṣe le fún àwọn ará ìlú lásìkò yìí.
Ó jẹ́jẹ̀ẹ́ ètò ìlera tó péye, ẹ̀kọ́ tó yè kooro, ètò ààbò, pípèsè àyíká tó dùnńgbé àti ṣíṣe àtìlẹyìn fún àwọn ọmọ ogun.
Bákan náà ló tún ṣe ìlérí wí pé òun kò ní gbé òṣèlú lékè àwọn nǹkan tí ará ìlú ń fẹ́ àti pé ìjọba tí yóò ṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú òun dáradára ni òun gbèrò láti ṣe.
Lẹ́yìn náà ló bèèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ará ìlú láti lè gbé orílẹ̀ èdè náà dé èbúté ògo.
Rishi Sunak yóò gbàkóso ìjọba UK lẹ́yìn ìpàdé pẹ̀lú King Charles

Oríṣun àwòrán, EPA
Olootu ijọba tuntun fun ilẹ Gẹẹsi, Rishi Sunak yoo ni anfaani lati gbakoso ọfiisi olootu ijọba ilẹ naa, lẹyin to ba ṣe ipade pẹlu King Charles.
Sunak ni yoo gba iṣakoso orilẹ-ede ọhun bayii lẹyin ti Liz Truss kọwe fi ipo naa silẹ lọsẹ to kọja.
Sunak yii ni yoo jẹ olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi to kere julọ lọjọ ori lati nnkann bii igba ọdun sẹyin.
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Rishi Sunak ree
Ọjọ kejila, oṣu Karun un, ọdun 1980 ni wọn bi ọkunrin naa, to n tumọ si pe o ti pe ẹni mejilelogoji bayii.
Ile iwosan gbogbogbo, General Hospital, to wa niluu Southampton, nilẹ Gẹẹsi ni wọn bi si, amọ ọmọ orilẹ-ede India ni awọn obi rẹ.
Orukọ iyawo rẹ ni Akshata Murthy, wọn ṣe igbeyawo lọdun 2009, wọn si bi ọmọ meji, Krishna Sunak ati Anoushka Sunak.
Ilu London ati Yorkshir lo fi n ṣebugbe, o si jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Conservative.
Sunak kawe gboye lawọn ile ẹkọ bii Winchester College, Oxford University ati Stanford University, ti gbogbo wọn wa nilẹ Gẹẹsi.
Sunak ṣiṣẹ nile ifowopamọsi investment bank Goldman Sachs laarin ọdun 2001 si 2004 ko to tun ṣiṣẹ lawọn ileeṣe nla mii to lorukọ.
O wa lara awọn to faramọ eto Brexit, iyẹn awọn to n fẹ ki ilẹ UK kuro lara European Union.
Lọdun 2019, wọn yan gẹgẹ bii ọkan lara awọn alabaṣiṣẹ pọ olootu ijọba atijọ, Boris Johnson.












