Báyìí ni ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ lórí àṣẹ ‘Stay of execution’ tí ìjọba fẹ́ gbà lórí òmìnira Kanu

Nnamdi Kanu lasiko ti awọn oṣiṣẹ alaabo mu lọdun 2016

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja ti gbọ ẹjọ 'stay of execution' ti ijọba Naijiria pe tako adari ikọ ajijagbara IPOB, Nnamdi Kanu, ki wọn o ma baa tu silẹ ni ẹwọn ṣaaju idajọ ile ẹjọ to ga julọ.

Aṣẹ 'stay of execution' naa tumọ si pe ijọba fẹ ki ile ẹjọ ṣi ni ki Kanu w ani ahamọ.

Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa, ni ile ẹjọ kotẹmilọrun naa kọkọ dajọ pe Kanu ko ni ẹsun kankan lati jẹ. Ṣugbọn idajọ naa ko dun mọ ijọba Naijiria ninu, eyi to mu ko pe ẹjọ sile ẹjọ to ga julọ.

Amọ ki ile ẹjọ naa to joko lori ipẹjọ naa, ijọba kọkọ lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun pada, lati gba aṣẹ pe ko gbọdọ yọnda Kanu ṣaaju idajọ ile ẹjọ to ga julọ.

Nibi igbẹjọ naa to waye ni ọjọ Aje, agbẹjọro ijọba, David Kasuwe sọ fun ile ẹjọ pe “ewu nla ni fun awọn eniyan ẹkun Ila oorun Gusu ati Naijiria ni apapọ ti awọn ba fi yọnda Kanu”.

O ṣalaye pe Kanu ma n salọ ni, ti yoo si nira lati gbe e pada sile ẹjọ ti awọn ba fun ni ominira.

Ṣugbọn agbẹjọro Nnamdi Kanu, Mike Ozekhome sọ fun awọn adajọ mẹta to gbọ ẹjọ naa pe irọ ni nkan ti David Kasuwe sọ.

“Niṣe ni inu awọn eeyan ẹkun Ila oorun Gusu dùn, ti wọn si ṣe ajọyọ ni ọjọ ti ile ẹjọ tu Kanu silẹ.

“Igbiyanju ẹjọ ‘stay of execution’ ti ijọba pe ni lati da idajọ nu. Itusilẹ Kanu oo mu alaafia wa si ẹkun rẹ ni”.

Agbẹjọro Ozekhome sọ pe Kanu ko ni ẹjọ kankan lati jẹ mọ, ati pe ko salọ ri lẹyin beeli.

Kini idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun sọ lori ominira Kanu?

Nibi idajọ to waye ni ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, awọn adajọ mẹta nile ẹjọ kotẹmilọrun wọgile gbogbo ẹsun ti ijọba Naijiria fi kan olori ẹgbẹ IPOB naa.

Wọn tun fẹnuko pe ko ba ofin mu lati ṣi fi Kanu si ahamọ, wọn si paṣẹ itusilẹ rẹ.

Bakan naa ni ijọba tun sọ pe ọna ti ijọba gba gbe Kanu wa si Naijiria lati ilẹ okeere, tako ilana awujọ agbaye.

Amọ Kanu ṣi wa ni ahamọ lẹyin ọsẹ bii meji ti ile ẹjọ tu u silẹ.