Bode George fẹ́ kí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú dáwọ́ ìpolongo ìbò dúró ná torí àjálù omíyalé

Asiwaju ẹgbẹ oṣelu PDP kan, Bode George ti ke s’awọn ẹgbẹ oṣelu lorilẹede
Naijiria lati dawọ duro na lori eto ipolongo ibo wọn nitori awọn eeyan to n foju
wina ajalu omiyale kaakiri orilẹede Naijiria bayii.
Ọrọ rẹ n jẹyọ lẹyin ti oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, sọrọ sita
pe o yẹ k’awọn ẹgbẹ oṣelu fi eto ipolongo ibo rọ sibikan naa nitori ajalu omiyale
to ti gbẹmi ọpọ, to si tun ti sọ ọpọ miran di alainilelori jakejado Naijiria.
Ninu ọrọ rẹ, Oloye Bode George sọ pe, “Bi irufẹ ajalu bayii ba ti waye, o yẹ ki a ba
awọn to ba kan kẹdun papaa fun ẹmi ati dukia awọn eeyan to wa nibẹ.”
Igbakeji alaga apapọ egbe PDP nigbakan ri naa wa slaye ninu ifọrọwọrọ kan
pẹl’awọn akọroyin pe Oun faramọ fifi ipolongo ibo ti sẹgbẹ kan fun igba diẹ naa
lati lee mọ ọna ti wọn lee gba da si wiwa ojuutu si ipenija awọn eeyan naa “lati
tubọ mu ki igbẹkẹle awọn eeyan wọnyi tubọ gbopọn sii pe lootọ la ni awọn
alakoso to dara ti yoo tukọ orilẹede yii fun wọn.”
Oloye Bode George tun sọ pe ṣiṣe ipolongo lasiko yii to pe awọn eeyan n fara gba
ajalu omiyale yii ko dara to.
O wa ke si ẹgbẹ oṣelu PDP to jẹ ẹgbẹ oṣelu rẹ lati ṣiwaju lori igbesẹ yii ki wọn si
ba awọn alẹnulọrọ lẹdi apo pọ lori ajalu naa ati didẹkun rẹ.















