Ta ló kọlu Funkẹ Akindele àti Jandor, olùdíje gómìnà PDP l’ Eko?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Iroyin jade pe awon janduku kan kọlu ikọ ipolongo fun ipo gomina ipinlẹ Eko lẹgbẹ oselu PDP nibiti wọn ti n polongo ibo lagbegbe ijọba ibilẹ Badagry lagbegbe Ikonga nirọlẹ ọjọ Aiku.
Iroyin sọ pe oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu naa Abdul-Azeez Olajide Adediran-JANDOR pẹlu igbakeji rẹ Funkẹ Akindele wa ninu ọkan lara awọn ọkọ to n kọwọrin nibi ipolongo ibo naa nigba ti ikọlu ọhun waye.
Gẹgẹ bí ọrọ kan ti alukoro fun ikọ ipolongo ibo Jandor fun idibo gomina nipinlẹ Eko, Gbenga Ogunlẹyẹ sọ, lootọ ni ikọlu naa waye ti ọrọ si di boo lọ yaa mi.

O ni “akọroyin mẹta lo ṣe’ṣe ninu iṣẹlẹ ikọlu naa, meji ninu wọn di ero ile iwosan nibi ti ọkan ṣi wa” titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.
Ko sọ pe ijamba ṣe oludije ẹgbẹ oṣelu naa tabi igbakeji rẹ lasiko ikọlu naa.
Taa gan lo kọlu Jandor ati Funkẹ Akindele?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi sita lori iṣẹlẹ yii, wọn n tọka si ẹgbẹ oṣelu APC pe awọn lo ran awọn janduku lati kọlu ikọ ipolongo oun.
“Awọn tọọgi ti wọn kọlu ikọ ipolongo wa n pariwo APC bi wọn ṣe n yin ibọn ti wọn si nlo awọn ohun ija buruku.”
Akeem Amode to jẹ akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko tun ṣalaye ninu atẹjade naa pe o ti pẹ ti awọn ti n lọọgun pe ọga ọlọpaa nipinlẹ Eko pe awọn kan ti awọn fura si pe wọn n ṣiṣẹ fun APC n gbero lati kọlu oludije fun ipo gomina ipinlẹ Eko labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP Abdul-Azeez Olajide Adediran-JANDOR.
Amọṣa, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ko tiifidi eyi mulẹ pe lootọ ẹgbẹ oṣelu kan lawọn to ṣe ọṣẹ yii ti wa ta Io ṣiṣẹ fun.















