Tí ìgbẹ́ tóò ń yà bá rí báyìí? Àìsàn jẹjẹrẹ ikùn ló dé o! Wo bí wàá ṣe dàa mọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
- Role, Broadcast Journalist
Ìlera ní Yorùbá pè ní oògùn ọrọ̀, àláfíà ẹni kọ̀ọ̀kan wa kò sì ní di fíafìa.
Onírúurú àìsàn ló wà lóde òní tó jẹ́ wí pé àìní àkíyèsí àwọn ènìyàn tó ló jẹ́ kí ẹlòmíràn bá àìsàn náà lọ.
Lára àwọn àìsàn tí àwọn ènìyàn kò le tètè kọbi ara sí ni àìsàn jẹjẹrẹ inú ikún nítorí àwọn nǹkan tó rọ̀ mọ.
Àìsàn jẹjẹrẹ ikùn ni jẹjẹrẹ tó máa ń mú ènìyàn nínú ìfun. Òhun ni àwọn olóyìnbó ń pè ní Bowel cancer tàbí Colon/Rectal cancer.
Dame Deborah James, tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ jẹjẹrẹ ikùn lẹ́ni ogójì ọdún ní UK rọ àwọn ènìyàn ṣaájú kó tó kú láti máa yẹ ìgbẹ́ wọn wò nígbàkúgbà tí wọ́n bá ti ya ìgbẹ́.
Báwo ni ènìyàn ṣe le mọ̀ pé òun ní jẹjẹrẹ ikùn?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta ló ṣe pàtàkì jùlọ láti mọ̀ bóyá ènìyàn ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn.
Kò túmọ̀ sí pé tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣe ènìyàn onítọ̀hún ti ní àìsàn jẹjẹrẹ ikún àmọ́ ó ṣe pàtàkì fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti lọ rí àwọn dókítà fún àyẹ̀wò tó péye pàápàá tó bá ti lé ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí àwọn àpẹẹrẹ yìí bá ti ń wà lára.
Àwọn nǹkan náà nìyí:
- Kí ẹ̀jẹ̀ máa wà nínú ìgbẹ́ ènìyàn láìsí ìdí kan pàtó.
- Kí ènìyàn máa yàgbẹ́ fún ìgbà púpọ̀ lójúmọ́ yàtọ̀ sí bó ṣe máa ń yàá tẹ́lẹ̀, tí ìgbẹ́ náà sì ń ṣàn tàbí kó le jù.
- Kí inú máa dún ènìyàn tàbí kí inú ènìyàn kún láì jẹun kó sì le ní àlejù.
Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn ni
- Kí ènìyàn máa ṣàdédé rù
- Kí ó máa dàbí wí pé inú ṣì kún lẹ́yìn tí ènìyàn bá ya ìgbẹ́ tán
- Kí ó máa rẹ ènìyàn jù tàbí kí òyì máa gbéèyàn ní gbogbo ìgbà.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn àìsàn jẹjẹrẹ yòókù, tí ènìyàn bá tètè mọ̀ wí pé ó wà lára, ó ṣeéṣe kí ènìyàn rí ìtọ́jú tó péye gbà lórí àìsàn náà.
Bákan náà ni àìsàn jẹjẹrẹ ikùn lé ṣokùnfà kí ènìyàn má rì í ìgbẹ́ yà, tó sì lè dá àárẹ̀ sára ènìyàn.
Máa yẹ ìgbẹ́ rẹ wò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lára ohun tí ó dára kí ènìyàn máa ṣe ni yíyẹ ìgbẹ́ ènìyàn tí ènìyàn bá ti ya ìgbẹ́ tán láti mọ bí ó ṣe rí nítorí bí ìgbẹ́ ènìyàn bá ṣe rí jẹ́ ọ̀nà láti fi mọ ìlera ènìyàn.
Wò bóyá kò sí ẹ̀jẹ̀ nínú ìgbẹ́ rẹ tàbí ní ìdí rẹ.
Ìgbà mìíràn tó jẹ́ wí pé jẹ̀dí ló máa ń fa kí ẹ̀jẹ̀ wà nínú ìgbẹ́ ènìyàn àmọ́ àìsàn jẹjẹrẹ ikùn náà máa ń fà á.
Kí ló ń fa àìsàn jẹjẹrẹ ikùn?
Kò ì tíì sí ìwádìí kankan tó fi ohun tó ń fa àìsàn jẹjẹrẹ ikùn múlẹ̀ àmọ́ àwọn nǹkan wà tó le mú kí àìsàn yìí tètè dàgbà lára.
- Ọjọ́ orí: Bí ènìyàn ṣe ń dàgbà ní ìlera ẹni náà ń dàgbà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà àìsàn jẹjẹrẹ ikùn máa ń da àwọn tí ọjọ́ orí wọn bá ti lé ní àádọ́ta ọdún láàmú ju àwọn ọmọdé lọ.
- Oúnjẹ: Tí ènìyàn bá ń jẹ àwọn oúnjẹ tó ní ẹran jù le fa àìsàn jẹjẹrẹ ikùn.
- Sìgá: fífa sìgá jẹ́ ọ̀nà kan tí àwọn onímọ̀ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó máa ń fa àìsàn jẹjẹrẹ.
- Ọtí: mímu ọtí àmupara jẹ́ ohun tó le fa àìsàn jẹjẹrẹ ikùn.
- Ara àsanjù: Àwọn tó bá sanra púpọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ le ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn.
- Polyps: Ẹni tó bá ti ni àìsàn yìí le ṣeéṣe kó ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn.
Ǹjẹ́ àìsàn jẹjẹrẹ ikùn máa ń tọ ìran?
Gẹ́gẹ́ bí ibi tí ìwádìí mọ báyìí, àìsàn jẹjẹrẹ kò le ràn láti ìyá tàbí bàbá sọ́mọ àmọ́ ó ṣe pàtàkì kí ẹni tí wọ́n bá ti ní àìsàn yìí ní ìran rẹ̀ fi tó àwọn dókítà létí.
Bákan náà ẹni tó bá ní àìsàn Lynch syndrome ṣeéṣe kó ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn ṣùgbọ́n ó ṣe é mójútó tí àwọn dókítà bá tètè mọ̀.
Bákan náà tí ènìyàn bá ń gbé ìgbé ayé àláfíà, tó ń jẹ àwọn oúnjẹ tó le ṣe ara ní àǹfàní le mórí bọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ.
Bí wọ́n ṣe le mọ àìsàn jẹjẹrẹ ikùn àti ìtọ́jú rẹ̀
Colonoscopy jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n máa ń fi ẹ̀rọ ayàwòrán wo inú ènìyàn láti mọ irú nǹkan tó wà níbẹ̀.
Wọ́n le fi ẹ̀rọ yìí mọ̀ tí ènìyǹ bá ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn.
Àìsàn jẹjẹrẹ ṣe é tọ́jú tí wọ́n bá tètè ṣàwárí rẹ̀ nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
Ìdá àádọ́sàn-án ènìyàn tí wọ́n bá tètè mọ̀ wí pé ó ní àìsàn ló ní àǹfàní láti lo ọdún márùn-ún sí láyé nígbà kan àmọ́ wọ́n ní ẹni náà le lo ọdún mẹ́wàá sí báyìí.
Kò sí ìpele tí àìsàn náà bá wà tí kò sí ìtọ́jú fún gẹ̀gẹ̀ bí àwọn onímọ̀ ṣe ṣọ.
Àwọn ìpele wo ni jẹjẹrẹ le wà?
Ìpele mẹ́rin ni àìsàn jẹjẹrẹ máa ń wà
- Ìpele àkọ́kọ́: ó kéré kò sì tí ì ràn
- Ìpele kejì: ó ti tóbi àmọ́ kò ì tíì ran ibòmíràn
- Ìpele kẹta: ó ti ń ràn káàkiri àwọn ẹ̀yà ara tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀
- Ìpele kẹrin: ó ti ràn dé gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù tó sì ti fẹ́ máa fa jẹjẹrẹ sí ìbómìràn.
A lérò wí pé ẹ ti di ohun kan tàbí òmíràn mú, tí ẹ ó sì mú ìlera ara yín ní ọ̀kúnkúndùn, ẹ ò ní máa sáré dìde kúrò ní yàrá ìgbọ̀nsẹ̀ tí ẹ bá ti yàgbẹ́ tán.
Yẹ ìgbẹ́ rẹ wò kí o tó kúrò nílé ìgbọ̀nsẹ̀ fún ìlera ara rẹ.












