Xi Jinping kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ àkọ́kọ́ tó ṣe sáà kẹta ní China

Xi Jinping

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orilẹede China, Xi Jinping ti sọ pe “gbogbo agbaye nilo China”.

O sọ eyi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin to kede ara rẹ̀ faraye gẹ́gẹ́ bí ààrẹ àkọ́kọ́ tó ṣe sáà kẹta ní China.

“China ko lee ri idagbasoke lai si gbogbo agbaye bẹẹ si ni gbogbo agbalaaye naa nilo China”. Xi sọ eyi lẹyin ọpọlọpọ ọdun akitiyan fun atunto to le ni ogoji ni China.

Xi Jinping, aarẹ China ti di ẹni akọkọ to ṣe saa mẹta nipo arẹ orilẹ-ede naa.

Owurọ ọjọ Aiku ni ikede naa waye nibi eto kan nilu Beijing.

Nibi eto naa ni Jinping tun ti kede awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ tuntun ti yoo ba a ṣe saa kẹta ọhun.

Lara awọn to kede ni oloye kan ninu ẹgbẹ oṣelu Communist, Li Qiang, ẹni ọdun mẹtalelọgọta, ti yoo duro gẹgẹ bi igbakeji rẹ (olootu ijọba) nigba ti Li Keqiang ba fi ipo naa silẹ loṣu Kẹta, ọdun 2023.

Eeyan marun-un mii lo tun yan sinu igbimọ alaṣẹ naa – Zhao Leji, Wang Huning, Cai Qi, Ding Xuexiang ati Li Xi.

Amọ iroyin to n lọ ni pe gbogbo awọn to yan sinu igbimọ oluṣakoso naa lo jẹ awọn to n wáríí fun, to n ṣe baba rere, baba kẹ̀ fun.

Onimọ eto oṣelu kan nilẹ America sọ pe igbesẹ Xi tumọ si pe “ẹnikẹni ko ni le yẹ ẹ lọwọ wo to ba gbe igbesẹ ti ko yẹ”. Bakan naa ni gbogbo aṣẹ lori igbimọ naa ati awọn igbimọ oludari ẹgbẹ oṣelu Communist.

Ikede ifinijoye naa waye lẹyin ọjọ ipade gbogboogbo ẹgbẹ Communist , nibi ti wọn ti ṣe atunsẹ si awọn ilana ẹgbẹ naa lati le fi ontẹ lu saa kẹta Ọgbẹni Xi, ati awọn ojuṣe rẹ si ẹgbẹ.

Xi Jinping ree, pẹlu eeyan mẹfa to yan lati ṣe iṣakoso saa kẹta pẹlu rẹ.

Awọn ọmọ igbimọ iṣejọba Xi Jinping
Àkọlé àwòrán, Eeyan meje lo wa ninu igbimọ alaṣẹ to n dari orilẹ-ede China

Nkan to yẹ ki o mọ nipa Xi Jinping

Xi Jinping ati igbakeji rẹ tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn bi Xi Jinping ni ọdun 1953, o si jẹ ọmọ ẹnikan lara awọn to pilẹ ẹgbẹ oṣelu Communist.

Ọdun 2012 ni Jinping de ipo aarẹ orilẹ-ede China, lẹyin ti aṣiwaju rẹ Hu Jintao yan an.

O ti kọkọ ṣe igbakeji aarẹ Hu Jintao lọdun 2008.

Lati igba to ti de ipo naa lo ti wa agbara mọ aya, ti oun nikan si n da a paṣẹ tako ilana ijọba ajumọṣe ti wọn n lo tẹlẹ lati aye Mao Zedong.

Ni ọdun 2018, labẹ iṣakoso rẹ ni awọn adari ni China dibo lati pa ofin ti wọn ti n lo lati ọdun 1990, ti ko faaye gba ju saa meji lọ nipo aarẹ.

Inu oṣelu ẹgbẹ communist ni wọn bi Xi si, nitori pe baba rẹ, Xi Zhongxun jẹ ọmọ ẹgbẹ naa, to si ti dari ẹkun Guandong ri.

Bi i baba rẹ, Xi Jinping naa gbajumọ fun gbigbogun ti iwa ibajẹ, idagbasoke ọrọ aje, ati riri daju pe agbara ko kuro lọwọ ẹgbẹ oṣelu naa.