Àádọ́ta èèyàn kú níbi ìwọ́de takò ìjọba tó wáyé ní Chad

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ologun ni Chad ti sọ pe aadọta eeyan ni wọn pa, ti ọọdunrun si farapa lasiko iwọde to waye ni Ọjọbọ nibi ti awọn aráàlú ti n bere fun dida orile-ede naa pada si ijọba alagbada.
Olootu ijọba tuntun, Saleh Kebzabo sọ pe àwọn kan lara awọn oluwọde naa mu nkan ìjà dani.
Ijọba sọ pe awọn oṣiṣẹ alaabo wa lara awọn ti wọn pa.
Iṣẹlẹ naa ti mu ki ijọba kede isede ni olu ilu orile-ede naa ati ilu nla meji mii.
O si ni iwadii ti n waye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
A ko ni fopin si iwọde titi wọn o fi ṣe nkan ti awọn n fẹ - Olori ẹgbẹ́ alatako
Olori ẹgbẹ́ alatako kan sọ fun BBC pe àwọn ko nii fi opin si iwọde titi wọn o fi ṣe nkan ti awọn n fẹ.
Wahala bẹrẹ nigba ti awọn ọlọpaa kọlu awọn oluwọde n'ilu N'Djamena, olu ilu Chad.
Awọn oluwọde naa dana sun taya ọkọ, wọn si tun dí awọn ojupopo nlanla n'ilu naa, botilẹ jẹ pe ijọba fi ofin de iwọde.
Chad ti wa ninu rogbodiyan lati oṣù Kẹrin, ọdun 2021 ti wọn pa Aarẹ Idriss Deby lasiko abẹwo to ṣe si awọn ọmọ ogun to n koju àwọn ikọ ọlọtẹ.
Ọpọ igba ni àwọn ọmọ ogun ti kọlu araalu, eyi to yọrí si iku ọpọ eeyan.
Ijọba fidihẹ naa si ni ijọba orile-ede France n ṣe atilẹyin fun.
Ìjọba alatako mii dide ni Chad
Oṣù Kẹrin, ọdun 2021 ni wọn kede ijọba naa lẹ́yìn ti wọn pa Aarẹ Idriss Deby.
Inu ibẹru-bojo si ni araalu wa pe o ṣe e ṣe ki iwọde naa tàn de àwọn ilu mii.












