Àwọn ẹ̀rí kàbìtì tó ní oògùn olóró nínú tó rọ̀ mọ Abba Kyari rèé - NDLEA

Oríṣun àwòrán, Screenshot
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Ọga agba fun ileeṣẹ ajọ to gbogun ti ogun oloro ni Naijiria, (NDLEA), Mohammed Ajia ti sọ nileẹjọ giga Abuja pe awọn ẹri to ni ogun oloro kokeni ninu ati ogun oloro miiran wa nilẹ, to ni nnkan se pẹlu igbakeji kọmisona ileeṣẹ ọlọpaa nigba kan ri, Abba Kyari,
Kyari ati awọn mẹrin miiran ninu ẹka ileeṣẹ ọlọpaa, IRT, Sunday Ubua, Bawa James, Simon Agirgba ati John Nuhu ni wọn dijọ n jẹjọ.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn ko ogun oloro pamọ, eyi to jẹ ẹsẹ nla ninu ofin orilẹede Naijiria.
Laipẹ yii ni Adajọ Inyang Ekwo wọgile ibeere agbẹjoro agba lati gbe Kyari lọ si ilẹ Amẹrika lori ẹsun to nii se pẹlu ogun oloro naa.
Nibi igbẹjọ, Ajia, ẹni to jẹ ẹlẹri kẹrin ni Ubua, to n dari ikọ ọlọpaa IRT lẹyin ti wọn ni ki Kyari lọ ma rọkun nile na, kọ lẹta si ajọ NDLEA lori bi wọn ṣe fi ofin mu Umeibe ati Ezaenwanne lori ẹsun pe wọn gbe ogun oloro kokeni.
“Kete ti a ṣe ayẹwo lori ẹri wọnyi, o fihan pe ida ọgọrin ninu rẹ ni ogun oloro kokeni ninu.
Awọn yoku si ni apẹẹrẹ pe ogun oloro wa ninu wọn , ti ida ogun yoku si ni ogun oloro miiran ninu.
Wọn tun fi ẹsun kan Kyari pe o lẹdi apo pọ pẹlu Hushpuppi lati lu jìbìtì lori ayelujara
Ẹri ti Ajia jẹ yii lo nii se pẹlu oogun oloro cocaine kilo mẹtadinlogun le diẹ, ti wọn ni wọn fẹ ta ati pe wọn gbọna ẹburu yọ ninu oogun oloro cocaine naa, eyi to le diẹ ni ogun kilogiramu.
Lara awọn ẹsun miiran ti wọn tun fi jan Kyari ni pe o gbiyanju lati tako isẹ ajọ NDLEA.
Kyari ni wọn lo na owo to to ẹgbẹrun lọna mọkanlelọgọta owo ilẹ okere si ọga agba kan labẹ ajọ naa ni Garki niluu Abuja..
Awọn ẹsun wọnyi ni ileẹjọ ni Kyari ati awọn mẹrin yoku jẹbi rẹ, to si ni ijiya ninu ofin orilẹede Naijiria to nii se pẹlu gbigbe ati lilo ogun oloro.
Adajọ Emeka Nwite wa ni ẹjọ naa yoo tẹsiwaju ni ogunjọ oṣu kẹwaa.
Nnamdi Kanu ṣì lẹ́jọ́ láti jẹ́ o, ilé ẹjọ́ kò ní kò jẹ̀bi ìdìtẹ̀gbàjọba - Ìjọba àpapọ̀

Ìjọba àpapọ̀ ti ní olorí ikọ̀ ajìjàgbara fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra, IPOB, Nnamdi Kanu ṣì ní ẹjọ́ láti jẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti pa gbogbo ẹ̀sùn tí ìjọba kà si lọ́rùn rẹ́.
Mínísítà fétò ìdájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Abubakar Malami ló sọ bẹ́ẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Umar Jibrilu Gwandu fi léde lọ́jọ́bọ̀.
Malami ní ohun tí àwọn adájọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lé lórí ni bí ìjọba ṣe gbé Kanu wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti wá jẹ́jọ́ kìí ṣe wí pé kò jẹ̀bi ìdìtẹ̀gbàjọba tí wọ́n fi kàn-án.
Ó ní gbogbo ẹ̀sùn tó wà lọ́rùn Kanu lórí bó ṣe sá kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti má kojú ìgbẹ́jọ́ nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ fún un ní ìdáǹdè ṣì wà lọ́rùn rẹ̀ tí yóò sì kojú ìgbẹ́jọ́ wọn.
Bákan náà ló fi kún un pé àwọn máa ṣàgbéyẹ̀wò ìdájọ́ náà daada láti mọ́ ìgbésẹ̀ òfin tó kàn láti gbé ọ̀rọ̀ náà gbà tí àwọn yóò sì fi ohun tí àwọn bá fẹnukò lórí léde fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà.
Malami tẹ̀síwájú pé ìjọba àpapọ̀ ní yóò jíròrò lórí ọ̀nà tí wọ́n yóò gbé ìgbẹ́jọ́ náà gbà láìpẹ́.
Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fòntẹ̀ lu ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu

Ẹ o ranti pe ni ana ni a mu iroyin wa pe Ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja ti ni ki wọn tu olori ikọ ajijagbara IPOB Nnamdi silẹ pe ko maa lọ sile lalaafia.
Adajọ ẹlẹni mẹta to gbẹjọ kotẹmilọrun to gbe wa sile ẹjọ ni ko lẹjọ lati dahun mọ nitori ile ẹjọ giga ko laṣẹ lati gbẹjọ rẹ.
Adajọ ni ọna ti ko tọ ni wọn fi gbe Kanu wọ Naijiria lati orileede Kenya ati pe wọn ko tẹle ilana to bofin mu nipa gbigbe daran wọ orileede rẹ pada.
Tori eyi, adajọ ni ko lẹjọ kankan ro ti wọn si wọgile gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an.
Idajọ yi n waye lẹyin agbẹjọro agba to n ṣoju Kanu,Mike Ozekhome bẹ ile ẹjọ pe ki wọn wgile awọn ẹsun meje to ku ti wọn fi kan Kanu ninu mẹẹdogun ti ile ẹjọ giga ti ṣaaju wọgile mẹjọ ninu rẹ.
Ṣaaju, adajọ Jummai Hannatu Saki wọgile iwe ti wọn mu wa pe ki wọn tete gbọ ẹjọ Kanu pẹlu alaye pe ọjọ ti re kọja lori rẹ.
Bẹẹ naa lo fi igbẹjọ beeli rẹ sẹgbẹ kan titi igba ti wọn yoo fi gbẹjọ kotẹmilọrun .
Ijọba Naijiria lo gbew Kanu lọsi ile ẹjọ lori ẹsun to da lori iditẹgbajọba,iyapa lọtọ ati pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ IPOB ti wọn ti fofin de pe ikọ agbesunmọmi ni.
Amọ ṣa losu Karun un, adajọ Binta Nyako ti ile ẹjọ giga Abuja wọgile mẹjọ ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an Kanu.
Ile ẹjọ giga ti o wa ni Abuja wọgile igbẹjọ beeli ti awọn agbẹjọro rẹ muwa nigba naa.















