"Mo mọ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa ọmọ mi lásìkò EndSARS, ó sì wà ní tésàn tó ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ lọ"
EndSARS: Àwọn ẹ̀bí tọ́mọ wọn wà ní àhámọ́ lẹ́yìn ọdún méjì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáǹdè wọn

Nibayiii to ti pe ọdun meji ti iwọde EndSARS waye, ọpọlọpọ awọn ọdọ ti awọn agbofinro gbe si ahamọ nigba naa, ni ko tii ri idande titi di akoko yii.
Awọn mọlẹbi mẹrin ninu awọn ọdọ mọkanla to wa ni ahamọ awọn ọlọpaa nipinlẹ Oyo, ke gbajare tọ BBC Yoruba wa lori isẹlẹ yii.
Bakan naa ni awọn mọlẹbi Isiaka Jimoh, ti ibọn ba lasiko iwọde EndSARS lọdun 2020 nilu Ogbomoso naa ba BBc Yoruba sọrọ lori ohun ti oju wọn ti ri laarin ọdun meji ti ọmọ wọn ku.
Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, gbogbo awọn ẹbi ti ọmọ wọn wọn wa ni ahamọ lo sọ pe awọn agbofinro to wa gbe awọn ọmọ awọn fi asọ dudu bo oju wọn.
Wọn ni ni bii ọsẹ meji lẹyin ti iwọde EndSARS pari tan, lawọn agbofinro naa n wọle wa ko awọn ọdọ ninu ile kọọkan ni adugbo ọọtọọ yika ipinlẹ Oyo.

Pẹlu omije si ni awọn ẹbi naa fi n salaye awọn igbesẹ lorisirisi ti wọn ti gbe lati gba idande awọn ọmọ wọn lati ọdun meji sẹyin, eyi to n ja si pabo.
Koda, ọkan lara awọn mọlẹbi ti ọmọ wọn gbẹmi mi lasiko iwọde EndSARS ni oun da ọlọpaa to yinbọn pa ọmọ oun mọ, ẹni to sọ pe o si n sisẹ lọ ni tesan ọlọpaa bayii.
Gbogbo awọn ẹbi naa lo n gbara ta pe ipo ti awọn afurasi naa wa ko dara rara, ti wọn si n bẹ ijọba ipinlẹ Oyo ati awọn alasẹ ileesẹ ọlọpaa lati fi awọn ọmọ wọn silẹ ni ahamọ.
Ki lo fa iwọde EndSARS?
Isẹlẹ manigbagbe, ti yoo wa ni iranti awọn ọmọ orilẹede Naijiria, ni iwọde EndSARS jẹ, paapaa lẹkun guusu orilẹede yii.
Iwọde naa, to waye losu kẹwa ọdun 2020 ni awọn ọdọ fi n tako iwa ifijajẹni ti ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa idigunjale (SARS) n hu si wọn laarin ilu.
Awọn ọdọ naa si lo tu jade lọpọ yanturu fun bi ogunjọ lati fi ẹhonu han tako iwa ibajẹ awọn ọlọpaa SARS naa, ti wọn si n beere pe ki ijọba tu wọn ka.
Idi ree ti wọn fi pe akori iwọde naa ni EndSARS.
Gbogbo awọn olu ilu awọn ipinlẹ to wa ni guusu Naijiria atawọn ilu nla nla miran ni awọn ọdọ naa kora jọ si lati fi ẹhonu han.

Lara ibudo ti wọn si korajọ si lati se iwọde ni ẹnu iloro Lekki to wa nilu Eko, ti wọn si dena lilọ bibọ ọkọ ati ero lopopona naa fun ọ́jọ melo kan.
Amọ nigba to di ogunjọ osu Kẹwa ọdun 2020 naa, ni awọn ologun ya bo awọn ọdọ naa lẹnu iloro Lekki naa, ti awọn eeyan kan sì kú, tí ọ̀pọ̀ mii si ṣese.
Eyi lo mu kawọn janduku ja iwọde naa gba lọjọ keji, ti wọn si n jo awọn dukia ijọba ati ti aladani, to fi mọ awọn agọ ọlọpaa kaakiri awọn ipinlẹ lkun guusu Naijiria.
Koda awọn ọlọ̀paa kan gbẹmi mi lasiko iwọde naa, tawọn mii si fi ara gba ọgbẹ.
Lẹyin iwọde naa si ni awọn agbofinro n sa awọn eeyan kan ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu iwọde naa.






