Olórí ilé aṣòfin l‘Ekiti kú lọ́jọ́ kẹta sí ìgbéyàwó ọmọ rẹ̀ - Mọ̀lẹ́bí

Àwọn ẹbí Afuye fẹ́ ṣèpàdé láti mọ̀ bóyá ìgbéyàwó ọmọ rẹ̀ yóò tẹ̀síwájú tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́

Ile Afuye

Ọpọ Olubanikẹdun lo ya bo ile olori ile igbimọ asofin nipinlẹ Ekiti, Funminiyi Afuye to jade laye lọjọru.

Nigba ti BBC Yoruba se abẹwo si ile naa to wa nilu Ikere Ekiti, a ri awọn ẹbi ati alasepọ oloogbe naa lagbo oselu ti wọn joko sibẹ.

Amọ gbogbo iyanju BBC Yoruba lati ri aya atawọn oloogbe naa lo ja si pabo nitori a gbọ pe wọn ti lọ silu Eko.

Ẹnikan to ba wa sọrọ, amọ ta fi orukọ bo ni asiri salaye pe ọjọ Satide ọtunla lo yẹ ki igbeyawo ọmọ oloogbe naa waye nilu Eko.

Idi si ree tawọn ọmọ ati aya rẹ fi rinrin ajo wa silu Eko fun ipalẹmọ igbeyawo naa ti yoo ko ni ọjọ Kejilelogun osu Kẹwa yii.

Ilu Eko si la gbọ pe wọn wa, ti wọn fi gbọ pe asofin naa ti jẹ ipe Ọlọrun lasiko aisan ranpẹ to se e.

Awọn olukẹdun nile Afuye

Afuye ni ara oun n se bakan-bakan lo se ni ka gbe oun lọ sile iwosan – Mọlẹbi

Ọkan lara mọlẹbi oloogbe naa to ba BBC Yoruba sọrọ, Ope Afuye, ti ọpọ mọ si Ọpẹ Age lo wa pẹlu olóògbé naa ki ọlọjọ to de.

Ninu ọrọ rẹ, Ope ni “Ọnarebu ri pe ara awọn nṣe bakan-bakan ni wọn se pe olori awon oṣiṣẹ rẹ, lati wa tẹle lọ sí ile-iwosan.

Amọ o ni aisan lo se wo, a ko ri ti ọlọjọ se, ti asofin naa si jade laye nile iwosan naa lẹyin wakati diẹ ti wọn debẹ.

Ọpẹ Age ni ile iwosan ijọba to wa nilu Ado Ekiti ni wọn kọkọ gbe oloogbe naa lọ, ki wọn to dari wọn lọ si ile iwosan fasiti ipinlẹ Ekiti.

O fikun pe lati fasiti ipinlẹ Ekiti naa si ni wọn ti ni ka maa gbe wọn lọ si ile iwosan fasiti Afe Babalola fun àwọn ayẹwo kan.

O ni lẹyin ayẹwo naa ni wọn tun da awon pada sile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti ipinlẹ Ekiti fun itọju.

Ope tẹsiwaju pe lasiko itọju naa ni Afuye ku ni ile-iwosan fasiti ipinlẹ Ekiti naa ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ Ọjọbọ.

O sọ pe awọn molẹbi yoo sẹsẹ se ìpàdé lati se ipinnu lori ayẹyẹ igbeyawo ti wọn fẹ ṣe ni ọjọ Satide ni.

O ni oun ko tii le sọ boya igbeyawo naa yoo tẹsiwaju tabi bẹẹkọ titi ti ẹbi yoo fi se ipade lori igbesẹ to kan nipa rẹ.

Aworan Afuye

Onirẹlẹ ati ololufẹ alaafia ni Afuye – Awọn eeyan Ekiti

Awon olugbe ipinlẹ Ekiti ti sapejuwe olori ile igbimo asofin ipinle Ekiti naa, Funminiyi Afuye gege bi onirele ati eniyan alaafia, ti o fi ìgbésí ayé sin awọn eniyan.

Wọn sọ awọn ọrọ wọnyi ni Ojobo nilu Ikere Ekiti nile oloogbe naa nígbà tí àwọn ọpọ èèyàn wa ṣe ìdàrò pẹlu awọn mọlebi olóògbé.

Wọ́n tun ṣe apèjuwé rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún iṣẹ́ ìsìn àwọn èèyàn rẹ̀.

Funminiyi Afuye ni ọmọ ile igbimo asofin ipinle Ekiti keji ti yoo ku, eyi to waye larin ọdun méjì sí ara wọn.

Ohun tó pa Funminiyi Afuye, agbẹnusọ ilé aṣòfin Ekiti tó kú rèé

Wo awọn nnkan pataki nipa Funminiyi Afuye

Funminiyi Afuye

Oríṣun àwòrán, @ekitistategov

Agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti, Funminiyi Afuye, ti jade laye lẹni ọdun mẹrindinlaadọrin.

Afuye lo n ṣoju ẹkun idibo Ikere kinni ko to jade laye lọjọru.

Ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun ipinlẹ Ekiti, Ekiti State Teaching Hospital, ni Afuye dakẹ si.

Funminiyi Afuye

Oríṣun àwòrán, @ekititrends

Ohun to mu ẹmi Afuye lọ

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ gomina ipinlẹ Ekiti, Yinkan Oyebode fi lede, o ni oloogbe naa jade laye lẹyin ti ọkan rẹ ṣadede kọṣẹ.

Atẹjade naa ni “Pẹlu ibanujẹ ọkan i ijọba ipinlẹ Ekiti fi kede iku agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin, Funminiyi Afuye.

“Afuye jade laye lalẹ Ọjọru nile iwosan ijọba ipinlẹ Ekiti, to wa niluu Ado Ekiti, nibi to ti n gba itọju lẹyin ti ọkan rẹ ṣadede kọṣẹ.

Awọn araalu n daro Afuye

Ọpọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lo ti bẹrẹ si n daro Afuye bayii lẹyin iku rẹ.

Lara wọn ni ijọba ipinlẹ naa, to fi mọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo, Adebo Ogundoyin fi lede, o ni Afuye jẹ ọkan pataki lara awọn agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin dantọ julọ ni Naijiria.

Lẹyin naa lo ba awọn eeyan ipinlẹ Ekiti kẹdun, to si tun gbadura pe ki eledua tu awọn ẹbi oloogbe naa ninu.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa Afuye ati iṣẹ to ṣe kẹyin

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Afuye ku lẹyin to tẹle gomina Oyebamiji lọ ṣabẹwo sawọn opopona kan to n fẹ atunṣe niluu Ado Ekiti

Afuye ti ṣiṣẹ gẹgẹ bii kọmiṣọna ri nipinlẹ Ekiti nileeṣẹ to n ri si ọrọ iroyin.

Ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii ni wọn burawọle fun oloogbe naa gẹgẹ bii aṣofin ipinlẹ Ekiti.

Oloogbe naa wa nibi eto isin idupẹ gomina tuntun, Biodun Oyebanji lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, lẹyin naa lo tun dari ijoko awọn aṣofin lọsan lọjọ kan naa.

Iṣẹ to ṣe kẹyin ni bo ṣe tẹle gomina Biodun Oyebamiji lọ ṣabẹwo si awọn opopona kan to n fẹ atunṣe niluu Ado Ekiti.