Ohun tí à ń fẹ́ kí ìjọba ṣe rèé – Àwọn tó farapa lásìkò ìwọ́de EndSARS

EndSARS

Awọn to farapa nibi iwọde EndSARS lọ́dún 2020 ti pe fun imuṣẹ abajade esi igbimọ ti ijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ, lati da si ẹsun ifiyajẹni ti awọn araalu fi kan awọn ọlọpaa.

Awọn ti ọrọ naa kan sọ pe awọn yoo ṣe eto iranti fun awọn to padanu ẹmi wọn lasiko iwọde naa to waye ni iloro Lekki toll gate ati awọn agbegbe miiran kaakiri orilẹ-ede Naijiria.

Ọrọ yii lo jade nibi ipade awọn akọroyin kan to waye niluu Eko, ni iranti ayajọ ọdun keji ti awọn ologun ṣina ibọn bolẹ fun awọn oluwọde naa niluu Eko.

Lara awọn to ṣagbatẹru ipade ọhun, Ayoyinka Oni, sọ pe ireti pipẹ maa n ṣe ọkan laarẹ, nitori naa, akoko ti fun ijọba lati san owo gba ma binu fun awọn to farapa nibi iwọde ọhun.

EndSARS

Ohun ti a fẹ ree

"A fẹ ki ijọba tu gbogbo awọn to wa lẹwọn tori iwọde EndSARS silẹ"

Ayoyinka Oni, to jẹ adari ẹgbẹ “Take it back”, sọ pe ohun ti awọn n fẹ ni pe ki ijọba tu gbogbo awọn to wa lọgba ẹwọn lori ẹsun kikopa ninu iwọde EndSARS naa silẹ.”

O ni “A si tun fẹ ki ijọba fun wọn ni owo gba mabinu fun akoko ti wọn lo ninu ẹwọn.

“Sisan owo gba ma binu ni kikun fun awọn to farapa ati ẹbi awọn ti wọn ṣekupa nibi iwọde EndSARS ni ọna kan gboogi ti ijọba fi le wẹ ara rẹ mọ.”

“Ijọba tun gbọdọ ṣe amulo awọn aba ti igbimọ oluwadii EndSARS fi lede, eyii ti wọn yi kọ ṣaaju.”

O sọ siwaju si pe ijọba gbọdọ fi iya to tọ labẹ ofin jẹ gbogbo awọn agbofinro to ṣekupa araalu lasiko iwọde naa, wọn si gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ awọn araalu ni gbangba.