Ìjà ńlá bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ láàrin ọlọ́jà àti agbèrò ni Alaba l‘Eko, ọ̀pọ̀ èèyàn fara pa, dúkìá bàjẹ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Ni ọsan ọjọru, ọjọ kọkandinlogun, osu kẹwaa ni awọn ọlọja ati awọn ọmọ ẹgbẹ ibudokọ ero wọya ija lori owo ori sisan ni ọja Alaba ni ipinlẹ Eko.

Iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC News Yoruba lọwọ ni ija naa bẹrẹ lẹyin tawọn ọmọ ẹgbẹ ibudokọ ero ọkọ ọja kede fun awọn ọlọja pe, awọn ti fi kun awọn owo ti wọn san fun idagbasoke ọja.

Osojumikoro to ba BBC News Yoruba ni awọn ọlọja ko faramọ igbesẹ naa, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu bi awọn alamojuto ọja ṣe kede afikun owo ọhun.

O ni eyi lo fa ija naa, ti eeyan meji si ti padanu ẹmi wọn, nigba ti ọpọ mii si farapa yanna-yanna.

O tẹsiwaju pe isẹlẹ naa ti fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ, ti wọn si ti gba agbadagodo si ẹnu ọja naa bayi.

Awọn ọlọpa to wa ni Alaba

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin

Ileesẹ ọlọpaa Eko ni ko sẹni to ku ninu isẹlẹ naa

Ninu atẹjade ti Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin fi si ori ayelujara, o ni alaafia ti jọba pada ninu ọja naa, ti iwadi si ti bẹrẹ lori nkan to fa ija naa.

O ni “Alaafia ti pada. Ti nkan si ti lọ ni irọrun.

Awọn ikọ ileeṣẹ ọlọpaa lati Ojo labẹ isakoso ZCP Igbafe Afegbai, ti wa ni ikalẹ.

“Ki ẹnikẹni maṣe bẹru nitori pe ileeṣẹ ọlọpaa ti balẹ si bẹẹ.”

Ni bayi gbogbo ọlọja ni wọn ti gba ile wọn lọ, ti wọn si titi ọja naa paa.

Ikede ti agbẹnusọ ọlọpaa se

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin