Wo ìpèníjà márùn ún tó ń kojú BBC bó ṣe pé ọgọ́rùn ún ọdún

Oṣiṣẹ BBC kan niwaju ẹrọ igbohunsafẹfẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ BBC ṣe n ṣayẹyẹ ọgọrun ọdun ti wọn da a silẹ, olootu awọn eto wa kan ṣe agbeyẹwo awọn ipenija to n dojukọ.

Paapaa latọdọ awọn ileeṣẹ akẹgbẹ rẹ ti wọn n lo awọn oju opo iroyin ayelujara igbalode bii TikTok, lati kan sawọn ọdọ pẹlu igbohunsafẹfẹ wọn.

Awọn ileeṣẹ nlanla, gẹgẹ bi iwe litireṣọ nla nla, kii ṣadede waye bikoṣe nipasẹ awọn ehonu to wa nilẹ lati dahun si awọn ẹhonu to ba n waye lasiko bẹẹ.

Gẹgẹ bi iwe ‘The Waste Land’ ti TS Eliot kọ lọdun 1922, bẹẹ gẹgẹ ni ọrọ BBC ri.

Nigba ti Ẹniọwọ Lord Reith - ti wọn yinbọn fun ni oju lasiko ogun agbaye akọkọ- di ọga agba akọkọ fun ileeṣẹ BBC, igbayegbadun orilẹede lo wa lookan aya rẹ.

Ọmọ orilẹede Scotland ni, o si ṣiṣẹ gẹgẹbi Onimọ ẹrọ nilu London lẹyin ogun agbaye akọkọ.

Erongba rẹ si ni lati lo awọn imọ ẹrọ igbalode nigba naa lati mu idagbasoke ba orilẹede ti ọwọja ogun ti fẹ jẹ run.

Loni, iwọnba eeyan ni yoo mu aba wa fun agbekalẹ ileeṣẹ iroyin ijọba.

Iwọnba ni awọn eeyan ti yoo si tun gba pe ki wọn maa fi owo ori ti awọn n san, fi yanju iṣuna ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ bẹẹ.

Sibẹ, pẹlu gbogbo oriyin to wọ tọ ọ lẹyin fun ọna ara to gba ṣeto gbigbe eto isinku Ọbabinrin Elizabeth keji saye fun gbogbo agbaye lati rii, o fihan gedegbe pe ileeṣẹ iroyin BBC ṣi jẹ odu lagbaye.

Fun ọgọrun ọdun, BBC ko ṣai jẹ ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ti awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi lee gbe ẹmi le lawọn asiko pataki, ninu eto orilẹede wọn ati agbaye.

Ọrọ apilẹkọ ti Churchill ba orilẹede naa sọ lasiko ogun agbaye; Ayẹyẹ ifinijoye Ọbabinrin Elizabeth, idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 1966; irinajo eniyan sinu oṣupa, iṣubu odi Berlin, Berlin Wall; atawọn eto miran.

Aworan ifinijoye Ọbabinrin Elizabeth keji

Oríṣun àwòrán, universal history archive/getty images

Ohun to mu ki Ọpọ awọn eeyan lorilẹede Gẹẹsi ri awọn iṣẹlẹ manigbagbe wọnyi gbọ ni ileeṣẹ BBC.

Amọ ṣa, ipenija kan to wa lorilẹede Gẹẹsi bayii ni iṣọkan orilẹede naa, paapaa nitori bi ilẹ Gẹẹsi ṣe yipada nitori ayipada to de ba ileeṣẹ iroyin pẹlu.

Fun ọgọrun ọdun, ileeṣẹ iroyin BBC ti lo oniruuru ohun elo igbalode lati mu adehun rẹ pẹlu araalu ṣẹ.

Asiko igbohunsafẹfẹ redio ni wọn da a silẹ, wọn si fun wa ni itanṣan tẹlifiṣan oniruuru ayipada imọ ẹrọ -

Ayelujara, foonu ilewọ, ati bẹẹ lọ eyi to ti fa iyatọ diẹ lori ipa ti ileesẹ BBC n ko lori aṣa.

Igbẹkẹle

Aworan

O rọrun lati pa igbẹkẹ̀le run, ṣugbọn lati mu ki igbẹkẹle waye a maa nira pupọ -

Jimmy Saville ni ninu ifọrọwerọ Martin Bashir pẹlu Ọmọọbabinrin Diana, atawọn nnkan miran - ti mu ki igbẹkẹle araalu ninu BBC o walẹ.

Pẹlu bi iroyin ofege ṣe gbode kan bayii, ti irọ si n rin ju otitọ lọ, awọn oju opo ayelujara ti ṣe ọpọ akoba fun iṣẹ iroyin.

Anfani niyi fawọn akọroyin lati tubọ lo akoko, ilakaka lati fidi otitọ mulẹ eyi ti awọn eeyan ṣi n ni igbagbọ fun.

Amọ igbẹkẹle to n relẹ n ṣe ọpọ ọṣẹ fun BBC.

Ko si ẹni ti yoo sanwo fun ohun ti ko ni igbẹkẹle ninu rẹ.

Iṣuna

Awọn eeyan nibi ode ijo kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pẹlu bi awọn akẹgbẹ orogun owo rẹ ṣe n na owo nlanla, bii Netflix, Disney, agbara kaka ni BBC n lo.

Gbogbo owo to n la kalẹ fun iṣuna ko ju biliọnu marun un pọun.

Dandan ni fun BBC lati ṣe awọn ohun ti awọn akẹgbẹ rẹ wọnyii ko le ṣe, (Iroyin, redio, eto fawọn ẹlẹsinjẹsin).

Sibẹ awọn igbesẹ oṣelu kan wa to n dari igbesẹ rẹ.

Kikan si awọn ọdọ

Awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹrindinlogun si mẹrinlelogun n lo ọpọ akoko lori Tiktok nikan ju wiwo mohunmaworan lọ.

Lawọn ọdun diẹ sẹyin, iye asiko tawọn eeyan n lo lati wo mohunmaworan ti lọ silẹ gidigidi pẹlu ida meji ninu mẹta.

Ijaya to pọju fun BBC bayii ni biba afẹfẹ igba lọ.

Sibẹ eyi ṣi ni gbedeke.

Ohun ti BBC gbọdọ ṣe ni lati rii daju pe nigba ti awọn iṣẹlẹ gbankọgbi ba yọju, o wa nikalẹ lati rii pe araalu lanfani si ohun gbogbo to tọ.

Oselu

Aworan awọn eeyan kan to n jo

Lọpọ igba ni BBC ma n tẹ ọka ijọba niru mọlẹ. Loni, iyatọ nla meji lo wa.

Akọkọ ni ikorira latọdọ ijọba eleyi to n gbona girigiri, ayelujara pẹlu da kun eyi.

Ikeji ni awọn ọta alafijin ti BBC ni, ti wọn le lo awọn eto igbohunsafẹfẹ ayelujara fun awijare ara wọn lati sọ pe ko si iwulo fun sisan owo ori igbohunsafẹfẹ mọ.

Imọ ẹrọ ni wọn n gbe awijare wọn le lori.

Awọn ipenija wọnyi lo n para pọ fẹ maa doju ija kọ BBC.

Amọ, awọn iṣẹlẹ ẹnu ọsẹ diẹ sẹyin bayii n fihan pe ayo ṣi ni BBC jẹ, o si lee tayọ ninu ọpọlọpọ nnkan.

Awọn adari rẹ bayii ṣetan, wọn si n gbaradi lati koju awọn ipenija wọnyi.

Gẹgẹbi ireti Ẹniọwọ Reith ti wi lọdun 2022, wọn ti to lẹyin ọrọ BBC.

Igbamuṣe iṣẹ rẹ, dipo bi o ti pọ to, ni ireti rẹ fun ọjọ iwaju.