Ìjọba ilẹ̀ Gẹẹsi kéde iye ọmọ Naijiria tó ti jápa lọ́dún yìí tí wọ́n tún kó mọ̀lẹ́bí wọn dání

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii kan ti fi han pe iye awọn ọmọ Naijiria to lọ silẹ Gẹẹsi lọdun yii pẹlu awọn mọlẹbi wọn pọ̀ ju ti awọn ọdun to ti kọja lọ.
Eyii ko ṣẹyin iye awọn eeyan to n gba Visa lati lọ kẹkọọ gboye nilẹ naa, ti wọn yoo si ko awọn ẹbi wọn dani.
Ninu atẹjade ti ijọba ilẹ Gẹẹsi fi lede, wọn ni awọn ọmọ orilẹ-ede India lo pọ ju ninu awọn to tẹkọ leti lọ silẹ naa lọdun yii lati lọ kawe.
Lẹyin India ni China, ti awọn orilẹ-ede mii si n tẹle wọn lẹyin.
Iye awọn ọmọ Naijiria to ti lọ si UK lati lọ kawe jẹ 34,000 nigba ti wọn ko awọn mọlẹbi wọn ti iye wọn jẹ 31,898 dani.
Ohun ti atẹjade ijọba ilẹ Gẹẹsi sọ
Atẹjade ijọba ilẹ Gẹẹsi fi han pe ida ogoji awọn to ko ẹbi wọn lọ kawe nilẹ Gẹẹsi laarin ọdun to kọja si oṣu Kẹfa ọdun yii lo jẹ ọmọ Naijiria.
Atẹjade naa ni “Ni ipari oṣu Kẹfa ọdun 2022, a ti fun eeyan 486,868 ni Visa lati kawe, pẹlu awọn mọlẹbi wọn, eyii to fi ida 71% ju ti ọdun to kọja lọ.”
“Iye Visa ti a fun awọn eeyan lati kawe lọdun yii lo ga ju ninu itan wa.”
“A fun awọn ọmọ India 117,965 ni Visa, eyii to fi 80,569 ju ti ọdun 2019 lọ.”
“Ni ti awọn ọmọ Naijiria, Visa ti a fun wọn fi ida +686% le ju ti atẹyinwa lọ.”

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki lo de ti ọpọ awọn ọmọ Naijiria fi n japa?
Ọpọ eeyan lo n fi Naijiria silẹ pẹlu awọn ẹbi wọn, paapaa ninu ọdun yii.
Igbesẹ naa gbode to bẹẹ ti awọn kan fi n pa owe kan pe “Oju la ri, a o mọ ẹni to n lọ UK.”
Yatọ si pe awọn eeyan n lọ kawe, pipese igbeaye to dara fun awọn ati awọn mọlẹbi wọn ni eredi ti ọpọ awọn ọmọ Naijiria ṣe n japa lasiko yii.
Lara awọn to ti lọ sọ pe awọn idi wọnyii ati idi mii lawọn ṣe n japa kuro ni Naijiria.
- Eto abo ti ko ṣe dede
- Eto ilera to ti dẹnukọlẹ eyii to n fa iku aitọjọ fun ọpọ araalu
- Eto ẹkọ ti ko ṣe mu yangan
- Dakudaji ina ọba to n pa ọrọ aje lara
- Titẹ ẹtọ araalu loju mọlẹ, ati bẹẹ lọ















