Kóo tó pé 30, o lè wọ ‘menopause’, ohun tó yẹ kóo tètè mọ̀ nìyí

Menopause

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Atẹjade kan lati ọọfisi ile igbimọ aṣofin ilẹ Gẹẹsi ti sọ pe o yẹ ki awọn obinrin maa ṣe ayẹwo ‘menopause’ wọn ti wọn ba ti wọ ọdun marundinlaadọta.

Ẹgbẹ kan, Menopause All-Party Parliamentary Group, lo sọ bẹẹ lẹyin iwadii ti wọn ṣe fun ọdun kan gbako.

Aṣofin kan, Carolyn Harris sọ pe oniruru idẹyẹsi lawọn obinrin ti wọn ko ri nnkan oṣu wọn maa n koju, eyii to maa n ṣakoba fun wọn lẹnu iṣẹ, laarin awọn ọrẹ ati ẹbi ati lọdọ ololufẹ wọn.

Ki ni wọn n pe ni ‘menopause’ gan?

Menopause

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Akoko yii jẹ igba ti awọn obinrin ko ni le ṣe nnkan oṣu wọn mọ, eyii to tun n tumọ si pe wọn ko ni le loyun.

‘Menopause’ yii maa n waye ti obinrin ba ti n dagba, o si maa n bẹrẹ lati ọdun marundinlaadọta si ọdun marundinlọgọta.

O tun le waye nipa iṣẹ abẹ, eyi ti wọn n pe ni ‘hysterectomy.’

Ti obinrin ko ba ri nnkan oṣu rẹ fun oṣu mejila gbako, o n tumọ si pe o ti wọ ‘menopause’ niyẹn.

Iye ọjọ ori ti obinrin ko fi ni ri nnkan oṣu rẹ mọ bẹrẹ lati ọdun mọkanlelaadọta, amọ o ṣeeṣe ki awọn obinrin kan ti ọjọ ori wọn ko tii wọ ọgbọn ọdun naa wọ menopause.

Ipele ti obinrin fi n wọ menopause ni wọn pe ‘Perimenopause.’

Awọn obinrin kan maa n ri apẹrẹ lara wọn pe menopause ti n sumọle, amọ awọn obinrin mii ki n ri titi di igba ti wọn ko fi ni ri nnkan oṣu naa mọ.

Awọn apẹrẹ menopause ati perimenopause

Menopause

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn apẹrẹ menopause ati perimenopause ni ipa nla ninu aye obinrin, paapaa lori iṣẹ ati ibaṣepọ wọn pẹlu awọn ẹlomiran.

Amọ awọn apẹrẹ naa ko dọgba, nitori oniruru eeyan lo maa n ri oniruru apẹrẹ tirẹ to si yatọ si ti ẹlomiran.

Awọn apẹrẹ naa maa jade fun ọpọ ọsẹ tabi oṣu ko to di pe nnkan oṣu naa ko ni waye mọ.

Apẹrẹ akọkọ ni pe nnkan oṣu irufẹ obinrin bẹẹ yoo maa ṣe segesege.

Bakan naa, o ṣeeṣe ki irufẹ obinrin naa maa binu si awọn eeyan ti ko yẹ ko binu si ati ni akoko ti ko yẹ ko binu.

Ohun ti awọn obinrin le ṣe ti wọn ko ba ri nnkan oṣu wọn mọ

Menopause

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onimọ nipa nnkan oṣu obinrin, Heather Currie sọ pe ko yẹ ki awọn obinrin foya ti wọn ko ba ri nnkan oṣu naa mọ.

Lara awọn nnkan to sọ ni pe wọn le lo awọn oogun to le dipo awọn ẹya ara wọn bii osetrogen ati progesterone to n jẹ ki nnkan oṣu wa.

O tun mẹnuba jijẹ awọn ounjẹ aṣaraloore ti wọn n pe ni ‘balanced diet.’

Dokita naa sọ pe ere idaraya ṣe pataki.

Lẹyin naa lo gba awọn obinrin niyanju lati sọra fun siga ati ọti mimu.