'A ti wo f́ídíò tó sͅàfihàn bí Chidinma sͅe pa Usifo Ataga olólùfeͅ rèͅ ní Eko'

Igbeͅjoͅ eͅsun ipaniyan ti woͅn fi kan arabinrin Chidinma Ojukwu teͅsiwaju ni ileeͅjoͅ ni Oͅjoͅ Koͅkanla, Osͅu Keͅwaa, oͅdun 2022 ni ileeͅjoͅ giga to wa ni agbegbe TBS ni ilu Eko.
Ileeͅjoͅ gboͅ eͅri oͅloͅpaa Olusegun Bamidele to sͅe iwadii isͅeͅleͅ naa, to si ka ohun arabinrin ti woͅn fi eͅsun kan.
Chidinma, aburo reͅ Chioma Egbuchu ati Adedayo Quadri kan ni woͅn n koju eͅsun ipaniyan, igbimoͅpoͅ sͅe ibi ati ole jija.
Awoͅn eͅleͅri fi aworan ati fidio ti ikoͅ ileesͅeͅ oͅloͅpaa to loͅ si ibi ti isͅeͅleͅ naa ti sͅeͅleͅ han.
Ileeͅjoͅ gba foͅto ati fidio naa geͅgeͅ bi eͅri, ti woͅn si sͅafihan reͅ ni ileeͅjoͅ.
‘Chidinma ti Usifo subu, o si gun un loͅbeͅ’
Geͅgeͅ bi oͅroͅ ti oͅloͅpaa Bamidele Chidinma soͅ, O ni Chidinma koͅkoͅ koͅ jaleͅ pe oun ko moͅ Usifo Utaga ri, ko to di pe woͅn fi fidio han.
Leͅyin naa lo sͅeͅsͅeͅ jeͅwoͅ to si soͅ orisirisi bi isͅeͅleͅ naa sͅe waye.
O ni awoͅn mu oͅtin ati oogun oloro Loud ati Raphinol ti woͅn fi si inu ohun eͅleͅrindodo ti woͅn mu.
Eͅleͅri naa ni Chidinma soͅ wi pe Utaga n bere ibalopoͅ loͅwoͅ oun lasiko ti o ti reͅ oun, ti oun ko si feͅ ibalopoͅ moͅ.
‘’Mo wa lori ibusun, ti Utaga si wa lori ijoko, a sͅeͅsͅeͅ ba ara wa lopoͅ tan ni o tun pada wa, ti mo si tii subu.’’
‘’Ori lo fi gba ileͅ ati eͅseͅ reͅ.Ataga dide peͅlu bi o sͅe sͅubu naa, ti o si di ni oͅrun mu, ti oun si mu oͅbeͅ ti oun si fi gun ni oͅrun.’’
‘’Leͅyin naa ni oun ro pe ti o ba tun dide, o le sͅe oun lese, ni ohun sͅe fi okun so oͅwoͅ reͅ mejeeji.’’
‘’Bakan naa ni oun tun fi oͅbeͅ naa gun ni eͅgbeͅ ati ikun.’’
Leͅyin naa ni Chidinma yi asͅoͅ reͅ pada, to gbe awoͅn nkan reͅ, to si gbe MacBook Utaga ati foonu reͅ, to si saloͅ.
Kini fidio sͅafihan ni ileeͅjoͅ
Fidio ti woͅn sͅafihan ni ileeͅjoͅ ni woͅn ti ri Chidinma ati Ataga ti woͅn joͅ woͅle si ibi ti ile igbe ti isͅeͅleͅ naa ti waye ni Oͅjoͅ Keͅtala, Osͅu Keͅfa, oͅdun 2021.
Woͅn koͅkoͅ joko si gbagede ki woͅn to wa joͅ rin jade pada.
Ibeͅ ni woͅn tigbe oku reͅ leͅyin isͅeͅleͅ isͅekupani naa.
Fidio naa tun sͅafihan yara ti woͅn joͅ ba oku Osifo naa to ni ibusun kan, aga kan, ile ounjeͅ ninu yara oͅun ati aga meji to ti kan.
Bakan naa ni fidio ohun sͅafihan oku Usifo Utaga nibi to ti woͅ asͅoͅ penpe, ti woͅn si fibo aya reͅ, ati ikun reͅ peͅlu asͅoͅ funfun.
Aworan naa sͅafihan oogun to wa ninu ilewoͅ Ataga, eͅjeͅ ni ileͅͅ to fimoͅ ileͅkun to ti ja naa.
Awoͅn nkan miran ti woͅn ri nibeͅ ni asͅoͅ, oogun ati igo waini meͅta.
Ibusun naa kun fun eͅjeͅ, okun eͅyoͅkan ati eͅjeͅ naa wa lara ogiri ati igberi.
Fidio ijeͅwoͅ Chidinma
Ileeͅjoͅ tun sͅafihan fidio miran nibi ti Chidinma ti joko ni oͅfisi awoͅn oͅloͅpaa to si sͅalaye oun to sͅeͅleͅ.
Fidio naa sͅafihan bi Chidinma sͅe sͅoͅ bi oun sͅe fi oͅbeͅ gun Utaga to si ku.
O ni awoͅn mu oͅpoͅloͅpoͅ oͅti, oogun oloro Loud,eleyii to mu ki Osifo ma moͅ ara moͅ, to si n beere ibalopoͅ ni oͅwoͅ reͅ lemoͅlemoͅ.
Ninu fidio naa lo ti sͅalaye pe ibeͅru lo jeͅ ki oun saloͅ leͅyin ti oun danikan pa arakunrin naa tan. O ni ko si enͅikeͅni to ran oun loͅwoͅ lati pa ati pe nisͅe lohun woͅ oͅkoͅ loͅ si ile ti ibeͅru bojo si ba oun.
Adajoͅ ti sun igbeͅjoͅ si Oͅjoͅ Kejila, Osͅu Keͅwaa, oͅdun 2022.












