Àṣírí tú! Ìlò ìyà ni wọ́n ń lo àwọn dókítà ọmọ Nàìjíríà tó ń lọ sí UK fún iṣẹ́

Awọn dokita onimọ iṣegun oyinbo to n ṣiṣẹ ni orilẹ-ede United Kingdom, amọ ti wọn gba lati awọn orilẹ-ede ti ko rọwọ họri sọ pe wọn n lo wọn ni ilokulo.
Iwadii kan ti BBC ṣe, tu aṣiri pe ileeṣẹ eto ilera kan ni orilẹ-ede Britain, n lo awọn dokita ti wọn gba lati Naijiria ni ilokulo.
Awọn ileewosan aladani ni wọn n gba awọn dokita naa si, Ṣugbọn ilana ti wọn fi ni ki wọn maa ṣiṣẹ tako ofin ẹka ilera ni UK.
Ẹgbẹ awọn dokita ni orilẹ-ede naa, British Medical Association (BMA) sọ pe iyalẹnu nla ni nkan naa jẹ fun awọn.
BBC ba lara awọn dokita ti ọrọ naa kan sọrọ. Lara wọn ni Augustine Enekwechi, ọ̀dọ́kùnrin dokita to wa lati Naijiria.
Enekwechi sọ pe nileewosan Nuffield Health Leeds ni oun ti kọkọ ṣiṣẹ lọdun 2021.
Nigba to wa nibẹ, o ni wakati mẹrinlelogun ni oun fi n ‘ṣiṣẹ’ loojọ fun ọsẹ kan gbako – to si ṣoro fun oun lati fi ọgba ileewosan silẹ nigba kọọkan. O ni bi igba ti oun wa ni ọgba ẹwọn ni iṣẹ ti oun n sẹ.
Ṣugbọn awọn alaṣẹ ileewosan naa sọ pe irọ ni.
Wọn sọ fun BBC pe awọn n tọju awọn oṣiṣẹ awọn daadaa, ti wọn si n fun wọn ni aaye isinmi.
Taa lo n gba awọn dokita siṣẹ ni UK lati Naijiria?
Ileeṣẹ kan, NES Healthcare lo gba Augustine lati Naijiria.
Nkan ti ileeṣẹ yii ma n ṣe ni pe wọn ma n gba awọn dokita ṣiṣẹ lati awọn orilẹ-ede ilẹ okeere, pupọ ninu wọn lo si n wa lati Naijiria.
Awọn dokita naa ni wọn ma n gba lati maa gbe ni ọgba ileewosan.
Augustine sọ pe idunnu ko jẹ ki oun ka ilana ati ofin to de iṣẹ naa nigba ti wọn gba oun. Eyi ti ko jẹ ko ṣakiyesi pe awọn ilana wọn tako ofin ẹka eto ilera ni UK, paapaa ofin to tako ṣiṣe isẹ fun ọpọlọpọ wakati.
Akọsilẹ kan to jẹyọ lati ara iwadii ẹgbẹ awọn dokita ni Britain, eyi ti wọn fun BBC fihan pe ìdá 92% awọn dokita ti wọn gba lati ilẹ okeere lo wa lati Africa – pupọ ninu wọn, 81% si wa lati Naijiria..
Ọpọ ninu awọn ti wọn ba sọrọ lo fi ẹdun ọkan han lori iṣẹ aṣeju ati pe wọn ma n yọ lara owo oṣu wọn.
Ileewosan ọtọọtọ ni wọn n ba a ṣiṣẹ, ṣugbọn ileeṣẹ agbani siṣẹ NES lo gba gbogbo wọn.
Lootọ ni ajọ ilera ni agbaye, WHO, tako eto gbigba ọpọ dokita ati nọọsi ṣiṣẹ lati awọn orilẹ-ede to ṣẹṣẹ n goke, ti wọn ko si ni oṣiṣẹ ilera to to.
Ninu orilẹ-ede mẹtadinlaadọta ti WHO darukọ, pupọ wọn lo wa ni Africa.
UK paapaa fi sinu ofin rẹ, eyi to sọ gbigb dokita lati Naijiria di eewọ.
Amọ, bawo ni awọn dokita naa ṣe n rapala wọ UK?
Irinajo BBC si Naijiria, tu aṣiri ibudo idanwo kan nilu Eko, nibi ti a ti ri ọgọọrọ awọn dokita to tò lati ṣe idanwo kan ti wọn pe ni Professional and Linguistic Assessment Board Test – tabi PLAB 1.
Ajọ to n risi eto ilera nilu London, General Medical Council nilu London, lo n mojuto idanwo naa, esi rẹ si ni nkan akọkọ ti awọn alaṣẹ ilera ni Britain ma n wo lati fun eeyan ni iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ dokita ni UK.
Awọn dokita ti a ba sọrọ ni, owo oṣu gọbọi ati igbe aye idẹrun lo mu wọn joko fun idanwo naa.
Awọn oṣiṣẹ ajọ ilẹ Britain, British Council si lo dari idanwo ọhun nilu Eko.
Ajọ GMC ṣe iru idanwo naa ni Ghana, Sudan, Pakistan ati Bangladesh.
Ṣugbọn ati GMC ati British Council sọ pe awọn ko kopa ninu gbigba ọgọọrọ dokita siṣẹ.

Dokita mii to jẹ ọmọ Naijiria ti BBC tun ba sọrọ ni Femi Johnson. Ileewosan aladani to yatọ si ti Augustine ni wọn pin si, lẹyin NES gba a.
O ni wakati mẹrinla si mẹrindinlogun ni oun fi n ṣiṣẹ lojumọ, ti wọn si tun ma n pe fun iṣẹ loru.
"Ko si aaye fun isinmi, amọ ọjọ to ba pinnu lati sinmi, wọn ma n yọ lara owo oṣu rẹ."
Ileeṣẹ NES sọ pe awọn n fi owo naa gbọ bukaata dokita ti yoo rọpo ẹni to ba lọ fun isinmi ni.
Ilana wo ni awọn dokita ijọba ni UK fi n ṣiṣẹ?
Aṣoju ẹgbẹ awọn dokita ni UK< Dokita Jenny Vaughan sọ pe ko si dokita ajọ NHS (ileeṣẹ eto ilera ijọba) to n ṣiṣẹ ju wakati mejidinlaadọta ni ọsẹ. Eyi to ba beere fun afikun ọjọ iṣẹ rẹ, kii ṣe ju wakati mejilelaadọrin lọ.
“Ko si dokita kankan ni NHS to n ṣe ju isẹ alẹ mẹrin leralera, nitori a mọ pe o lewu.”
O ṣapejuwe ilana ti awọn ileeṣẹ aladani fi n ṣiṣẹ gẹgẹ bi imuni lẹru, to si lewu fun dokita ati alaisan.












