'Ọmọ ọdún méje ni mo wà tí mo fi fọ̀ lójú'

Oríṣun àwòrán, MISS PORTHARCOURT CITY 2022.
Yoruba bọ, wọn ni ohun to n dun ni, lo n pọ lọla ẹni.
Bẹẹ ni ọrọ ri fun Arabinrin Favour Rufus, to jẹ afọju, amọ to ni afojusun lati di arinrinoge tabi bori ninu idije lọjọ kan.
Lati mu ki afojusun naa wa si imuṣẹ, o kopa ninu idije obinrin to rẹwa julọ nipinlẹ Rivers. O si ṣe ipo keji.
Ohun ati omidan mejidinlogun mii lo kopa ninu idije naa, eyi to mu ko di Miss Portharcourt City Humanity 2022.
Favour sọ fun akọroyin BBC Pidgin pe ọpọlọpọ eeyan, paapaa awọn ẹbi rẹ, lo ni ki oun ma kopa ninu idije ọhun.
“Awọn kan ti ẹ sọ pe iwọ to jẹ afọju, o jẹ ma lọ fi igi to fi n rin lu adari eto naa lori itage.”
Arinrinoge naa sọ pe amọ iya oun ṣatilẹyin fun oun, botilẹ jẹ pe o kọkọ ya a lẹnu nigba ti oun fẹ dije.
O ni oun ti ẹ tun ṣiyemeji, amọ awọn adari eto naa fun oun ni igboya lati tẹsiwaju.

Bawo ni Favour ṣe padanu oju rẹ?

Nigba to wa ni ọmọ ọdun meje, ni awọn dokita sọ pe o ni aisan oju, glaucoma.
“Bi ọmọ dun meje si mẹjọ ni mo wa nigba ti dokita sọ fun wa pe oju mi kan ti fọ.”
“Nkan to ṣẹlẹ nigba naa ko ye mi, mo kan ṣa mọ pe mi o ki n ri nkan.”
Favour sọ pe olukọ kan nile ẹkọ rẹ lo ṣakiyesi ipenija oju naa, lẹyin ti ko ṣe daadaa mọ ninu eto ẹkọ rẹ.
Olukọ naa si lo gba iya rẹ ni imọran lati gbe lọ sileewosan oju, nibi ti dokita ti fun wọn ni iroyin ibanujẹ naa.
“Dokita naa sọ fun wa pe ko si atunṣe kankan mọ, nitori o ti pẹju ka to o wa.”
Bakan naa ni dokita naa sọ pe oju rẹ ọtun nikan lo ku, ti wọn si gbọdọ ma a ra oogun olomi si oju naa, bibẹẹkọ, oun naa yoo ku pi bi ina abẹla.
Nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹẹdogun ni iya rẹ fi si ile ẹkọ awn afọju. Ibẹ si lo ti kọ lati ma a fi irinṣẹ kan ti wọn n pe ni ‘Braille’ lati ma a fi kawe, to fi mọ imọ kọmputa ati awọn nkan mii.
O si tun kawe de ile ẹkọ girama.
Favour sọ pe oju rẹ ọtun naa ti n wo baibai, to si jẹ pe ẹkọ to kọ ni ile ẹkọ afọju lo n mu ko le rin kaakiri.

Nkan to yẹ ki o mọ nipa aisan Glaucoma
Glaucoma jẹ aisan to ma n ba àwò oju jẹ awo oju naa ni irinṣẹ to ma n ranṣẹ si ọpọlọ lati wo nkan.
Awọn onimọ ṣaba ma n sọ pe aisan ẹjẹ riru lo ṣaba ma n ba awo oju naa jẹ. Amọ aisan Glaucoma le mu ẹnikẹni.
Bakan naa ni ko si ọjọ ori ti ko ti le mu eeyan ni oju. Oun lo si wọpọ ninu nkan to n fa ifọju fun awọn to ọjọ ori wọn ti le ni ọgọta ọdun.
Iwadii sọ pe aisan yii ki fi apẹẹrẹ kankan han, debi pe o le ma a ri iyatọ kankan ninu bo ṣe n riran titi oju yoo fi fọ.
Nitori naa lo sẹ ṣe koko lati ma a ṣe ayẹwo oju rẹ ni igba gbogbo.












