EndSARS: Ìdí tí MC Oluomo fi ní kí ẹ kó òkú èèyàn yín jáde tó bá dáa yín lójú pé sọ́jà pa wọ́n ní Lekki Tollgate rèé

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lootọ ni alaga igbimọ alamojuto gbogbo ibudokọ atawọn gareeji ọkọ nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti ọpọlọpọ mọ si MC Oluomo sọ pe ko si irẹpọ kankan to wa laarin ọrọ ipaniyan lasiko ifẹhonuhan EndSARS ati oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu.
Ninu Fidio to jade lori ayelujara lọjọ ti MC Oluomo dari awọn eeyan ni ipinlẹ Eko ninu iwọde ẹlẹni miliọnu marun-un (5 million march), Oluomo ni iṣẹ ọwọ awọn akẹgbẹ Tinubu ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ati Labour Party, Atiku Abubakar ati Peter Obi ni eyi.
“Wọn ni eeyan ku nibi EndSARS, nibo ni awọn oku yẹn wa, nibo ni wọn sin wọn si?
Ṣe awọn oku to ku yẹn, ṣe wọn o ni ẹbi ni Naijiria ni?
Ṣe Naijiria ti lọ fun awọn abiyamọ to daju ni abẹtẹlẹ ti awọn to kun o tun wa ni aburo to le maa pariwo lori ayelujara?
Ati pe ṣe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu jẹ ọga awọn ologun tabi aarẹ ti yoo fi paṣẹ pe ki wọn lọ yinbọn ni Tollgate?”
Musiliu n sọ fun awọn ọdọ ti wọn jọ ṣe iwọde yii pe irọ ni awọn ọrọ ti wọn gbọ nipa iṣẹlẹ Lekki Tollgate pe wọn kan fẹ sọ Yoruba di ẹdun arinlẹ ni to si tun ni ere gele inu oṣelu ni.
“Awọn Atiku ati Peter Obi lo parapọ nigbayẹn ni wọn n ṣe gbogbo nkan ti wọn n ṣe amọ oju ti la bayii”.
O n ṣalaye fun awọn ọdọ pe ko ṣeeṣe ko jẹ pe ipaniyan waye nibi iwọde EndSARS ki awọn si ma ri oku awọn eeyan naa tabi ki mọlẹbi wọn pariwo sita pe lootọ lo ṣẹlẹ.
Lọjọ Aiku to kọja yii ni MC Oluomo fi gbogbo ọrọ juwe atilẹyin rẹ fun oludije aarẹ to yan laayo, Bola Tinubu ati Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu.
Ninu Oṣu Kẹwa Ọdun 2020 ni ẹgbẹgbẹrun awọn ọdọ tu jade si igboro kaakiri Naijria ati loke okun lati fẹhonuhan lodi si ipaniyan lọna aitọ to n wa latọwọ awọn Ọlọpaa paapaa awọn ikọ Ọlọpaa Kogberegbe EndSARS ti ijọba gbe kalẹ.
Latari iṣẹlẹ Lekki Tollgate yii ni ijọba wa gbe igbimọ olugbẹjọ kan kalẹ latọwọ awọn gomina ipinlẹ kaakiri lati ṣe iwadi awọn oniruuru ẹsun iwa ika ti awọn Ọlọpaa ti ṣe sawọn araalu nipinlẹ wọn.












