Wo obìnrin tó bí ìbaàrún lẹ́yìn tó bí ìbejì lẹ́ẹ̀mejì àti ọmọ mẹ́sàn-án mìí

Hajara ati awọn ọmọ marun-un to bi

Oríṣun àwòrán, SHUAIBU UMAR

Awọn eeyan kan nipinlẹ Katsina ti bẹrẹ si ni pe arabinrin kan, Hajara Shuaibu, ni obinrin ti ọmọ pọ lara rẹ julọ ni Naijiria.

Eyi waye lẹyin ti obinrin naa bi ọmọ marun-un lẹẹkan ṣoṣo ni Ọjọru.

Ṣaaju asiko yii, Hajara ti kọkọ bi ibeji lẹẹmeji, ọmọ mẹsan-an miran, ko tun to bi marun-un.

Hajara ba BBC sọrọ lori iriri rẹ to fi di iya ọlọmọ pupọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun o ko mọ pe ọmọ to wa ninu oun ju ẹyọkan lọ, ati pe gbogbo nkan to yẹ ni oun ṣe ninu oyun.

Hajara ko lọ si ileewosan ri fun itọju alaboyun, ante-natal, ile lo si bimọ si pẹlu iranlọwọ awọn iya agbẹbi ti wọn n pe ni Unguwan ni ede Hausa.

Lẹyin to bimọ sile ni wọn to gbe e lọ si ileewosan Funtua General Hospital.

O ni igba akọkọ ree ti wọn gbe oun lọ sileewosan nitori ọmọ bibi.

Hajara sọ pe oun ko ni ounjẹ kan gboogi tabi asejẹ kankan to mu ki oun maa bimọ bẹẹ.

Shuaibu Umar, to jẹ ọkọ Hajara sọ fun BBC pe meji lara awọn ọmọ tuntun naa kú lọjọ Ọjọbọ, to si ku mẹta ati iya wọn nileewosan ijọba apapọ nilu Katsina.

“Nitori wọn ko ni irinṣẹ fun awọn ọmọ tuntun ti ko gbó nileewosan ni Funtua, ni wọn ṣe sọ pe ka gbe wọn lọ si Katsina fun itọju to peye.”

Awọn ọmọ tuntun marun-un ti Hajara bi ni Ọjọru

Shuaibu to jẹ agbẹ ni abule Doma sọ pe ibukun ni oun ka ọmọ si lati ọdọ Ọlọrun.

Bakan naa lo sọ pe alaga ijọba ibilẹ Faskari nipinlẹ Katsina, ti fi ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira ran wọn lọwọ.

Ṣugbọn o ni awọn ṣi nilo iranlọwọ owo lati tọju ẹbi oun to jẹ elero pupọ.

Nigba ti akọroyin BBC beere lọwọ Hajara boya yoo tun bimọ si, o ni ọwọ Ọlọrun ni eto aye oun wa.

“To ba sọ pe kadara mi ni ki n tun bimọ si, dandan ni ko ri bẹẹ.”