Ayé mi ti dojúrú – Ọkùnrin tí ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ mẹ́ta bá omi lọ figbe ta

Oríṣun àwòrán, OGOCHUKWU ABS
Ọkunrin kan ti iyawọ rẹ ati ọmọ mẹta jade laye ninu ijamba ọkọ oju omi to danu ni nipinlẹ Anambra ti sọ iriri rẹ.
Iyawo ati awọn ọmọ ọkunrin naa wa lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ni Umunnakwo, ni ijọba ibilẹ Ogbaru, ni ipinlẹ naa.
Ọjọ Ẹti to kọja ni iṣẹlẹ ọhun waye lẹyin ti ikun omi gba apakan ipinlẹ naa.
Nigba ti yoo fi di ọjọ Aiku, ijọba ni awọn ti yọ oku eeyan mẹwaa jade ninu ẹkun omi naa.
Bi ijamba naa ṣe ṣẹlẹ
Orukọ ọkunrin to wa ọkọ oju omi naa ni Desmond Amaugo, lati Ogwuaniocha, amọ ko ba ijamba naa lọ.
O sọ fun awọn akọroyin niluu Onitsha pe eeyan mejidinlaadọta pere ni oun ko sinu ọkọ naa tako iroyin to n lọ nigboro pe eeyan marundinlaadọrun ni oun ko.
Awakọ naa ṣalaye pe awọn obinrin ti oun gbe ṣe wa sile oun, ti wọn si bẹbẹ pe ki oun gbe awọn.
O ni “Wahala naa bẹrẹ nigba ti iji bẹrẹ si n ja lori omi, mo si gbiyanju lati dari ọkọ naa ko ma ba danu.”
“Iji naa pọ to bẹẹ ti ọkọ ọhun fi lọ fori sọ afara Umunnakwo/Ossomala.”
“Amọ lẹyin gbogbo igbiyanju lati mu ọkọ naa duro lori omi, o papa danu.”
Iroyin ni awọn obinrin ati ọmọde lo pọ ju ninu ọkọ oju omi ọhun.
Aye mi ti dojuru
Ọgbẹni Benard Achonu, to padanu eeyan mẹrin ninu ijamba ọkọ naa ni aye oun ti dojuru.
Lara awọn ti ẹni ọgọta ọdun naa padanu ni iyawo rẹ, ati ọmọ mẹrin.
O ni ọjọ ori awọn ọmọ oun ko ju ọdun meji si mẹfa lọ, gbogbo wọn si wa papọ lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye.
Ọkunrin naa ni “Ọtọ ni ibi ti ẹbi mi n gbe tẹlẹ ki omi to le wọn kuru nibẹ.”
“Ibi ti wọn ti n gbiyanju lati sa asala kuro nibi ti omi naa wa ni wọn ti kagbako iku ojiji yii, aye mi ti dojuru bayii.”
Èrò bíi 40 lèmi gbé nínú ọkọ̀ ojú omi mi, òkú 9 ni wọ́n ti rí yọ jáde - Awakọ̀ ojú omi

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Iroyin to kan kaakiri ni pe kò dín ní àádọ́rin ènìyàn tó pàdánù ẹ̀mi wọn bí ọkọ̀ ojú omi kan ṣe dànù.
Ẹwẹ, nigba ti BBC ri anfani lati ba awakọ to wa ọkọ oju omi naa sọrọ, Desmond Amaugo sọ pe lootọ ni ọkọ oun maa n gba to aadọrun eniyan amọ oun ko gbe to bẹẹ lọjọ Ẹti ti iṣẹlẹ laabi naa waye.
Lẹyin naa lo ṣalaye pe nkan bii eeyan ogoji loun gbe. Nibayii, o ni eeyan mẹwa pere ni wọn tii ri oku wọn yọ jade ninu omi ọhun.
Àwọn ènìyàn náà ló jẹ́ àwọn ọlọ́jà àti àwọn ènìyàn tó ń sá fún omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ní agbègbè wọn.
Níbi afárá Onukwu ní Umunankwo ní ìjọba ìbílẹ̀ Ogbaru, ìpínlẹ̀ Anambra ni ọkọ̀ ojú omi náà ti dànù nígbà tó ń kó àwọn ènìyàn náà láti Ossomala lọ sí ọjà Ogbakuba.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣojú wọn ṣe sọ, ọkọ̀ ojú omi náà léfòó fún ìgbà díẹ̀ kó tó di wí pé ó dànù sínú omi ọ̀hún.
Nínú èrò márùndínláàdọ́rùn-ún tó wá nínú ọkọ̀ ojú omi náà, àwọn mẹ́sàn-án ni wọ́n móríbọ́ tí àwọn yòókù sì rì sínú omi.
Alákoso ikọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Anambra, Nnamdi Esimai tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní àwọn kò ì tíì rí òkú àwọn tó rí sínú omi náà yọ báyìí.
Esimai ní ètò ti wà nílẹ̀ láti yọ wọ́n kúrò nínú omi ní kété tí àwọn bá ti ń rí òkú wọn tó lé sórí omi.
Ó ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀ máa wáyé fún àwọn ènìyàn tó bá ń gun ọkọ̀ ojú omi láti máa wọ aṣọ ààbò nítorí irúfẹ́ ìjàmbá báyìí.
Soludo bá àwọn ènìyàn tó lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ náà kẹ́dùn
Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra, Charles Soludo ti ba ẹbí àwọn ènìyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmba ọkọ̀ ojú omi náà kẹ́dùn.
Soludo nínú àtẹ̀jáde kan ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu àti ohun tó ba ni lọ́kàn jẹ́ pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ láabi bẹ́ẹ̀ wáyé.
Gómìnà náà ni onírúurú ìgbésẹ̀ ni àwọn ti gbé láti ri pé àwọn ènìyàn tó ń ṣe àtìpó ní àwọn ibùgbé àwọn tí kò nílé lórí mọ́ ń gbé ìgbé ayé tó rọrùn.
Bákan náà ló sọ àrídájú rẹ̀ pé ìjọba yóò tún tẹ̀síwájú láti mú àdínkù bá ìṣòrò tí àwọn ènìyàn ń kojú nípa omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù.















