Ọdún kan àbọ̀ sẹ́yìn yìí le gaan fún mi àmọ́ ... – Igboho sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho Instagram
O ti ṣe diẹ ti ọpọ eeyan ti gbohun gbajugbaja ajafẹtọ ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo ti gbogbo eniyan mọ si Sunday Igboho lẹyin gbogbo wahala to rọ mọ fifi ofin muu ati itusilẹ rẹ.
Sunday igboho fi ọrọ bii owe sita loju opo ayelujara rẹ wipe bo tilẹ jẹ pe nkan bii ọdun kan ati abọ sẹyin jẹ eyi to wa pẹlu ọpọlọpọ ipenija fun oun amọ oun ri itura ọkan gba ninu pe gbogbo nkan ti oun n ṣe, nitori awọn eeyan oun ni.
“Ọdun kan abọ sẹyin jẹ ipenija nla fun mi amọ mo ri ifọkanbalẹ pe ninu wiwa ọna ati gba awọn eeyan mi silẹ ati pe tori awọn eeyan mi dide pe ija yii, ti gbogbo ọmọ Yoruba ni”.

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho Instagram
Igboho tun ṣalaye sibẹ latari bo ṣe n mura ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ pe ayẹyẹ ti ọdun to kọja ba oun ninu ahamọ ijọba orilẹede Benin Republic nibi ti wọn ti oun mọ amọ o fi ọpẹ fun Ọlọrun ninu ohun gbogbo.
“... amọ mo dupẹ fun Ọlọrun ati awọn eeyan kan to tu mi silẹ”.
Ẹwẹ, bi awọn kan ṣe n kan sara sii fun iṣẹ takuntakun rẹ lawọn kan n ni gbogbo ohun to ṣẹlẹ sii ko kan aye o.
Ọjọ Kẹwa Osu Kẹwa ni ọjọ ibi ajafẹtọ yii ti yoo si pe ẹni aadọta ọdun lọdun 2022 yii.

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho Instagram











