Àwọn gómìnà ló lẹ̀bi omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù tó ń bá àwọn ìpínlẹ̀ wọn fínra - NIHSA

Àgbàrá òjò

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Àjọ tó ń mójútó ojú ọjọ́ ní Nàìjíríà ti di ẹ̀bi omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ́bù tó ń bá àwọn ìpínlẹ̀ kan fínra ní orílẹ̀ èdè yìí ru àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ náà.

Adarí àjọ Nigeria Hydrological Services Agency, NIHSA, Clement Nze ló sọ bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí àgbàrá òjò kò ṣe ń bá àwọn ìpínlẹ̀ kan jà lórí ètò iléeṣẹ́ Channels TV lọ́jọ́ Kẹjọ oṣù Kẹwàá, ọdún 2022.

Nze ní láti ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kejì ọdún ni àjọ Nigeria Meteorological Agency, NiMet ti fi ìkìlọ̀ léde pé omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù yóò ṣọṣẹ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ náà.

Ó ní lẹ́yìn ìkìlọ̀ NiMet ni NIHSA náà fi ìkìlọ̀ síta lórí àwọn nǹkan tó le wáyé tí òjò bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rọ̀.

Ó kọminú pé àwọn ìjọba ìbílẹ̀ àti ìpínlẹ̀ ló ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bi lórí bí àgbàrá òjò ṣe ń ṣọṣẹ́ báyìí nítorí àwọn ni kò tẹ̀lé gbogbo ìkìlọ̀ àwọn.

Bákan náà ló tún fi kun pé Mínísítà fọ̀rọ̀ omi, Suleiman Adamu náà tún kọ ìwé ránṣẹ́ sí àwọn gómínà náà láti ṣàlàyé ìpèníjà tí omíyalé ọ̀hún le fà ṣùgbọ́n tó ní wọn ò gbọ́ ìkìlọ̀.

Ó ní Mínísítà nínú ìwé tó kọ ránṣẹ́ sí àwọn gómìnà náà ló tún ti ṣàlàyé àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ kí wọ́n gbé ṣaájú kí òjò tó bẹ̀rẹ̀.

Nze ní tó bá jẹ́ wí pé àwọn gómìnà náà gbọ́ ìkìlọ̀ ni, tí wọ́n sì ṣe àmójútó tó péye, ó ní gbogbo àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí kò ní pọ̀ tó báyìí.

Yàtọ̀ sí àwọn gómìnà, ó ní mínísítà tún fi ìkìlọ̀ ranṣẹ́ sí àwọn iléeṣẹ́ bíí ètò ọ̀gbìn, àyíká àti òfurufú láti fi agbègbè tó ṣeéṣe kí omíyalé náà ti wáyé tó wọn létí.

Àwọn ọṣẹ́ tí omíyalé ti ṣe

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ káàkiri Nàìjíríà bíi Kogi, Jigawa, Delta, Gombe, Anambra, Kwara, Eko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló ti fojú winá omíyal;e àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló ti ṣokùnfà pípàdánù ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló ti di aláìnílé lórí mọ́ tí oko ẹlòmíràn sì tún ti bá a lọ.

Yàtọ̀ sí ẹ̀mí àti dúkìá tí àwọn ènìyàn ti pàdánù, omíyalé náà yóò tún ṣe àkóbá fún ìpèsè oúnjẹ.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, akọ̀wé àjọ HEDA Resource Centre, Sulaimon Arigbabu tí òun náà kópa níbi ètò náà ní omíyalé náà ti ń ṣeàkóbá fún oúnjẹ báyìí.

Arigbabu ní àsìkò yìí ló yẹ kí àwọn àgbẹ̀ máa kó èrè oko tí wọ́n dá ṣùgbọ́n àgbàrá kò jẹ́ kí wọ́n le ṣe bẹ́ẹ̀.

“Ọ̀wọ́n gógó máa bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oúnjẹ báyìí, àsìkò yìí ló yẹ kí ìjọba mú àdínkù bá àwọn òfin kan lórí kíkó àwọn oúnjẹ kan wọlé láti ilẹ̀ òkèrè.”

Àwọ gómìnà gbọdọ̀ gbé ìgbésẹ̀ akin ní kíákíá

Adarí ẹ̀ka kan ní àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Nàìjíríà, NEMA, Onimode Abdullahi ní àwọn gómìnà gbọdọ̀ dìde láti ṣe ojúṣe wọn.

Abdullahi ní iléeṣẹ́ tó ń ṣàmójútó ààtò ìlú àti ẹ̀ka tó ń mójútó àwọn ìdọ̀tí ti yẹ láti wá nǹkan ṣe kí àgbàrá òjò tó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣọṣẹ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ náà.

Ó ní ó yẹ kí ìjọba ti kó àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ́ pé àgbàrá òjò le ṣàkóbá fún kúrò nínú agbègbè wọn lọ sí ibòmíràn tí kò ní jẹ́ etí odò.

Ó fi kun pé òun gbàgbọ́ wí pé pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún yìí àwọn gómìnà àti ìjọba lápàpọ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ tí wọ́n yóò sì ṣe àmójútó rẹ̀ kí irú rẹ̀ má baà wáyé nígbà mìrán.