'Ìdí rèé tí mo fi wà lẹ́yìn Tinubu amọ́ n ò ṣàtìlẹyìn fún sáà kejì Dapo Abiodun bótilẹ̀ jẹ́ pé APC la jọ wà'

Ibikunle Amosun

Gomina ipinlẹ Ogun nigba kan, to tun jẹ aṣofin agba Naijiria lọwọlọwọ, Ibikunle Amosun ti sọ pe oun ko ṣe atilẹ yin fun gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun lati ṣe saa keji.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC Yoruba ni Amosun ti sọ pe lootọ ni oun n ṣe atilẹyin fun oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) fun ipo aarẹ, Bola Tinubu, amọ oun ko sẹ bẹẹ fun Dapo Abiodun botilẹ jẹ pe ọmọ ẹgbẹ osẹlu kan naa ni wọn.

Sẹnetọ Amosun ni oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun lati inu ẹgbẹ oṣelu ADC, Biyi Otegbeye ni oun n ṣe atilẹyin fun lati di gomina.

O ni eyi ko ṣẹyin bi Abiodun ko ṣe ṣe daadaa fun gbogbo awọn to fi ara jiya fun ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun.

Lati ọdun 2019 ni ede aiyede ti n waye laarin Ibikunle Amosun ati Dapo Abiodun.

Eyi ko ṣẹyin bi ẹgbẹ osẹlu APC ṣe fun Abiodun ni tikẹẹti lati dije fun ipo gomina, dipo Adekunle Akinlade ti Amosun fẹ ko rọpo oun.

Akinlade si ni Amosun ṣe atilẹyin fun ninu eto idibo gomina ipinlẹ Ogun lọdun naa, botilẹ jẹ pe ninu ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement lo ti lọ dije.

Ibo ẹgbẹrun mọkandinlogun pere si ni Abiodun fi gba ipo naa mọ ọ lọwọ.

Afọwọfa wa ni idamu to ba Naijiria, kii ṣe amuwa Ọlọrun

Nigba ti akọroyin BBC bi Aṣofin Amosun lori ipenija Naijiria, paapaa bi nkan ṣe ri bayii lẹyin ọdun mejilelọgọta to gba ominra, o ni lootọ ni pe awọn orilẹ-ede to wa ni ipo ẹyin pẹlu Naijiria ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin, ti goke bayii.

"Pupọ ninu ẹbi ipo ti Naijiria wa bayii, wa lati ọdọ awọn oloṣelu ati awọn olori Naijiria, boya alagbada tabi ijọba ologun.

"Pupọ ninu adanwo Naijiria, awa oloṣelu lo ba wi.

Oloṣelu ko pupọ ninu ẹbi bi Naijiria ṣe ri, ṣugbọn iwa ibajẹ ko yọ awọn oṣiṣẹ ijọba naa silẹ."

Ara ilu la n fi owo ti awa aṣofin n gba tọju

Lori awuyewuye pe owo ti awọn aṣofin Naijiria n gba ti pọ ju, Sẹnetọ Ibikunle Amosun sọ pe lootọ ni owo ti wọn n gba pọ.

"Ṣugbọn ko tun pọ nitori pe funra wa la n pese awọn nkan ti a fi n ṣiṣẹ ilu, to fi mọ ipese omi, ina , ati awọn itọju mii fun awọn eeyan ni ẹkùn idibo wa."

Ipọnju lo mu ki ilẹ kaarọ ojiire ma a polongo Yoruba Nation

Amosun ni oun ko ro pe o ni ọmọ ilẹ kaarọ oojire ti yoo deede sọ pe awọn fẹ kuro ni Naijiria, ti kii ba ṣe ti bi nkan sẹ ri lọwọlọwọ.

O ni lootọ ni wiwa ni ẹkun ọtọọtọ le dara, amọ diduro ni odindi pẹlu ifọwọsowọpọ ṣe anfaani ju ki kaluku ṣe tiẹ lọtọ.

Amọ idi ti ọpọ ẹya fi fẹ da duro ni pe awọn kan ni ikunsinu nitori pe mudun-mudun ko kan wọn.

" Ṣugbọn mo ṣi ni igbagbọ pe naijiria yoo dara de ibi ti yoo di itẹwọgba laarin awujọ agbaye.

"Bi a ṣe n ba lọ yii, ko le pe ọdun meji si asiko yii ti awọn araalu yoo fi gbagbe pe Naijiria ti bajẹ. O ni ara yoo tu wọn.

'Mo fara mọ ki ipinlẹ kọọkan ni ọlọpaa tiẹ'

Lori idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ, Amosun sọ pe oun funra oun faramọ ki ipinlẹ kọọkan ni ileeṣẹ ọlọpaa tiẹ, ti oun si gbero rẹ nile aṣofin ni ọdun 2003.

O ni ti eto aabo Naijiria yoo ba ni ojuutu, ki ipinlẹ kọọkan ni ileeṣẹ ọlọpaa tiẹ yatọ si ti ijọba apapọ ni ọna abayọ.

"Ti iru awọn Amotekun yoo kan jẹ oluranlọwọ fun wọn."

O ni idi ni pe awọn ara adugbo lo mọ gbogbo kọọrọ ati gbangba to wa ni agbegbe wọn.