Atiku ló ṣàwárí Peter Obi jádé, Atiku nìkan sì ni olùdíje tí gbogbo ẹ̀yà leè kí kúàbọ̀ sílù wọn – Dino

Atiku Abubakar ati Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Others

“Ajọ to korajọ lasan ni APC jẹ, PDP ni ẹgbẹ oṣelu to dagba julọ ni Naijria”. Sẹnetọ tẹlẹri nile igbimọ aṣofin agba Naijiria to tun jẹ adari ikọ ipolonogo fun idibo yan Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ti kẹnu bọ ọrọ lori idi ti oludije ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu wọn Alhaji Atiku Abubakar ko ṣe fi tara tara sọrọ lori gbogbo rogbodiyan ati iyapa to n ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ.

Dino Melaye n sọ eyi ni idahun si ibeere pe kilode ti ẹgbẹ PDP ṣe yan ipinlẹ Akwa Ibom lati bẹrẹ ipolongo idibo wọn.

Dino ni tori pe Atiku wa lati iha Ariwa Naijiria lo ṣe roo pe ki wọn ma fi ilu oun bẹrẹ bakan naa lo ni “Atiku nikan ni gbogbo ẹya ati ilu orilẹede Naijiria lee ki kaabọ si ilu wọn”.

Pẹlu bi Atokun ṣe jẹ ko di mimọ fun un pe oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi naa n lọ kaakiri orilẹede Naijiria lati ṣepade pẹlu awọn eekan oloṣelu ti Tinubu naa si ti kan si agbami ipolongo, Dino Melaye ni otubantẹ lasan ni gbogbo ẹ.

“Tinubu o tilẹ le lọ si iha Ila Oorun nigba to n lọ kaakiri nigba idibo abẹnu wọn, ọpọlọpọni ko tilẹ mọ ọ ni awọn ilu to wọnu ni iha Ariwa gan”.

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Others

Dino ni Bakan naa lo jẹ fun oludije aarẹ, Rabiu Musa Kwankwaso ati Peter Obi. Ẹwẹ, Dino ni bii ẹni mo owo tabi ọti ẹlẹrindodo to gbayi kaakiri ju ni wọn ṣe mọ Atiku Abubakar kaakiri Naijiria to si ni oun lawọn eeyan n pariwo pe awọn n fẹ.

Melaye ni ko si idarudapọ kankan ninu ẹgbẹ awọn tori awọn lawọn jẹ akọkọ ninu ọpọlọpọ ipinu ati aato ti gbogbo ẹgbẹ oṣelu n ṣe to si tọka si pe bi aarin awọn ko ba to, bawo lawọn ṣe n ri igbesẹ akin fun ipolongo yii gbe.

Ẹ o le maa fi PDP we LP, fi Atiku we Obi - Ẹgbẹ taa ni wọn?

Atiku tun bu ẹnu atẹ lu awọn ipolongo ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party ti ṣe ṣaaju to si ni wọn kan n san owo fawọn eeyan lati wa ba wọn pe jọ ni.

PDP ni Wike n ṣiṣẹ fun!

Dino jẹ ko di mimọ pe ni ọjọ diẹ sẹyin ṣi ni Atiku ati gomina ipinlẹ Rivers, Nyesome Wike jọ ṣepade pọ.

“Mo si fẹ fi daa yin loju pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni Wike n ṣiṣẹ fun tori iṣẹ akanṣe kan to n ṣe nipinlẹ Rivers, fun ipolongo ibo fun PDP ni.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Gomina Nyesome Wike ti da bii akara oyinbo ti gbogbo oloṣelu fẹ ninpin ninu rẹ latari awọn ọrọ ati igbesẹ to gbe nigba kan lodi si ipinu ẹgbẹ oṣelu rẹ, PDP.

O ni ko si wahala kankan laarin ẹgbẹ awọn, aarin alaga ati oludije aarẹ si danmọran torinaa, ohun gbogbo n lọ ni tubi n nubi.

“Ko si ko ma si ikunsinu laarin ẹgbẹ amọ mo n sọ fun yin pe digbi ni ẹgbẹ PDP wa ninu isọkan”.