Àìsàn tó ń mú èèyàn fa irun ara rẹ̀ tu - Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa "Trichotillomania" nìyí

Gbajumọ olorin ọmọ orilẹede Morocco kan, Abir El Abed sọ pe ọmọ ọdun marundinlogun loun nigba ti awọn dokita sọ fun oun pe oun ni aisan trichotillomania to maa n mu ki eeyan fa irun ara rẹ tu.
“Awọn eeyan kan a maa bi mi pe iru iṣoro wo lo ni gan? Ṣe o laarun jẹjẹrẹ ni?
“Ṣugbọn iṣoro ti mo ni kọ niyi, inu ọkan mi ni iṣoro mi wa.
Mo maa n sọ fun won pe emi ko ni iṣoro kankan pẹlu irun mi o, mo kan faa yọ kuro ni.”

Awọn eeyan to ba ni arun Trichotillomania maa n fẹ lati maa sadede fa irun ara wọn tu. Aaarin awon obinrin at’awọn ọdọ wẹẹrẹ ni aisan yii pọju ti maa n jẹyọ ju. O ni lọpọ igba ti oun ba n la awọn iporuru ọkan kan kọja yala ni ibi iṣẹ ni tabi ohunkohun yoowu to lee jẹ, paapaajulọ ti oun ba ronu arokan ju, oun yoo kan ṣadede maa fa irun oun tu ni. “Ọpọ ni oye aisan yii ko tii ye. “Awon eeyan tilẹ maa n sọ fun mi nigba mii pe mo ni iṣoro pelu irun mi, mo kan maa n fi ibori mi boo ni. “ Wọn kii mọ pe iṣoro naa gan an niyẹn. Mi o fẹ bo nkankan mọra mo” ni alaye ti Abir ṣe.

Fun awon eeyan to ni irufẹ iṣoro to ni yii, Abir ṣalaye pe o di igba ti wọn ba ti gba ara wọn bi wọn wa ki wọn to le bọ si ipele to kan ninu ati ni iwosan. “ Ni ifẹ ara rẹ bi o ṣe wa, yala o ni irun lori ni o tabi bi o ko ba si ni irun lori, paapaajulọ awọn obinrin- ko yẹ ki wahala wa lori eyi! O rẹwa gẹgẹ bi o ṣe wa. Bi o ba si ti gba eyi fun ara rẹ gẹgẹ bi o ṣe wa, awọn eeyan pẹlu yoo bẹrẹ si nii tẹwọ gba ọ ṣe ri.
Ki lo n fa awọn aisan inu ero okan bii TTM yii?

Ki lo n fa awọn aisan inu ero okan bii TTM yii?
Awọn onimọ sọ pe awọn iriri igba ewe ti ko bojumu lo maa n fa aisan ọgbẹ ọkan yii. Dokita Dikra Raissoni to jẹ dokita akọṣẹmọṣẹ nipa arun ọpọlọ ṣalaye fun BBC pe eyi lee jẹ otitọ, o si tun le jẹ irọ. Amọṣa, otitọ ibẹ ni pe awọn iriri idamu maa n kun ara ohun to n fa aisan yii ṣugbọn kii ṣe igba gbogbo lo maa n jẹ pe eyi ni orirun rẹ. O ni awọn nnkan miran wa to tun maa n fa eyi bii ko jẹ ajogunba tabi awọn ohun miran to nii ṣe pẹlu iseda eeyan. Bakan naa lo ni awọn ohun miran bii awujọ, ẹkọ at’awọn nnkan miran to n ṣokunfa rẹ.
Bawo ni a ṣe le tọju aisan yii?
Dokita Dikra sọ pe ọna itọju meji lo wa fun aisan yii. Ọkan nii ṣe pẹlu itọju ọpọlọ. Eyi si ni awọn dokita maa n saba toka si fun awọn to laisan naa. O ni eyi yoo mu ki alaisan naa lee mọ bi ọna ironu wọn ṣe n lọ si lati lee ṣatunṣe iporuru tabi aniyan ọkan wọn. Ọna itọju keji ni ogun lilo, eyi si wa fun awọn ti ina aisan naa ti fẹ jo de ori koko fun. Nigba ti aisan naa ba ti de ori eyi, itọju ọpọlọ ati ogun lilo ni wọn maa n la kalẹ fun wọn.












