Àwọn ọ̀dọ́ méjì gé ọkùnrin kan wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ láti fi ṣe oògùn owó - Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, POLICE
Ayé ń lọ à ń tọ̀ ọ́.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti fi ṣìkún òfin mú àwọn afurasí méjì kan ní agbègbè Owode Egba.
Àwọn afurasí méjéèjì tí orúkọ wọ́n ń jẹ́ Friday Abinya Odeh àti Poso Idowu ni wọ́n jẹ́ ọmọ ogún ọdún àti ọmọ ọdún mọ́kànlélógún.
Ẹ̀sùn wí pé àwọn méjéèjì pa ọkùnrin ẹni ogójì ọdún kan, Abdullahi Azeez tí wọ́n sì tún kun-ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ láti fi ṣe oògùn owó.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi léde ní àwọn ẹbí Azeez ló lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Owode Egba nígbà tí wọn kò ri kó padà sílé lẹ́yìn tó jáde nílé ní ọjọ́ Kẹjọ oṣù Kẹfà ọdún 2022.
Oyeyemi ní láti ìgbà náà ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti mọ ibi tí Azeez há sí.
Ó ní ọjọ́ Kejìlélógún ni ọwọ́ tẹ Friday Abinya Odeh níbi tí ó fara pamọ́ sí tí àwọn sì rí síìmù ìbánisọ̀rọ̀ Azeez lọ́wọ́ rẹ̀.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá fi kún un pé lẹ́yìn tí ọwọ́ tẹ Odeh ló mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ibi tí Poso Idowu náà faara pamọ́ sí tí àwọn sì fi ṣìkún òfin gbé àwọn méjéèjì.
Oyeyemi tẹ̀síwájú pé nígbà tí àwọn ń fi ọ̀rọ̀ wá àwọn afurasí náà lẹ́nu wò ni wọ́n jẹ́wọ́ pé ní ọjọ́ Kẹjọ oṣù Kẹfa ni àwọn jí Azeez gbé ní agbègbè Kobape ìpínlẹ̀ Ogun.
Ó ní nǹkan bí ago méje àbọ̀ alẹ́ ni àwọn afurasí náà ṣe iṣẹ́ láabi yìí tí wọ́n gbè lọ sí inú igbó kan níbi tí wọ́n pa á sí.
Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn tí àwọn afurasí náà pa Azeez tán ni wọ́n tun kun-ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ láti lo ẹ̀yà ara èyí tí wọ́n fẹ́ ní ara rẹ̀.
Bákan náà ló ní wọ́n tún jẹ́wọ́ pé oníṣègùn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Arab money” tí àwọn bá pàdé ní orí ayélujára Facebook ló júwe ògùn owó náà fún àwọn.
Oyeyemi ní gbogbo ìgbìyànjú àwọn láti rí ibi tí wọ́n si ẹ̀yà ara Azeez tó kpu sí tàbí ibi tí wọ́n gbe pamọ́ sí ló já sí pàbó nítorí àwọn afurasí náà ní àwọn ti sọ́ nù.
Ó sọ síwájú pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Ogun, Lanre Banke ti pàṣẹ pé kí àwọn gbé àwọn afurasí náà lọ sí ilé ẹjọ́ ní k;eté ti àwọn bá ti parí ìwádìí àwọn.















