Ọlọ́pàá n wá ìyá òóṣà tó di ajínhìnrere Jesu fún ẹ̀sùn sísọ owó di ìlọ́po méjì

Oríṣun àwòrán, Other
Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii ẹsun sogun-dogoji ti wọn fi kan wolii obinrin kan to ti pada di ajinhinrere ni orilẹ-ede Ghana.
Obinrin naa to pe ara rẹ ni ajinhinrere, Patricia Asiedua, ni wọn fi ẹsun kan pe o leri fun awọn ọmọ ijọ rẹ lati sọ owo di ilọpo meji fun wọn, to si ni oun yoo pin owo ọfẹ fun wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa Ghana sọ pe ninu ile ijọsin rẹ, Heaven Way Church, to wa ni agbegbe Wejia nilu Accra, ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Patricia, ti ọpọ eeyan mọ si Nana Agradaa, ogboju iya alawo to di ajinhinrere, ṣeleri pe oun yoo fun awọn ọmọ ijọ rẹ ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun owo ilẹ Ghana, lẹyin ti oun ba sọ owo ti wọn ba da fun oun ni ṣọọṣi di ilọpo meji.
Lẹyin ti awọn eeyan gbọ ileri naa, iroyin sọ pe wọn bẹrẹ si ni ko gbogbo owo ọwọ wọn lọ si ṣọọṣi, pẹlu ireti pe Nana Agradaa yoo sọ ọ di ilọpo meji fun wọn.
Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ nigba ti wọn n pada si ile ijọsin naa lati wa a gba ilọpo meji owo wọn, Ajinhinrere Patricia ti salọ.
Ninu fidio kan to n lọ lori ayeluyara, awọn olujọsin naa sọ pe owo ti awọn fi pamọ, owo iṣẹ ati idokoowo, to fi mọ owo ti awọn yá, ni awọn ko fun un lati sọ di ilọpo meji.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa sọ pe awọn rọ gbogbo ẹni to ba ni ẹkunrẹrẹ iroyin nipa jibiti naa, lati ran wọn lọwọ ninu iṣẹ iwadii wọn.
Bakan naa ni wọn ni awọn rọ gbogbo awọn to kagbako ninu iṣẹlẹ naa, lati mu suuru, ki wọn o ma si ṣe idajọ lọwọ ara wọn.
Bawo ni Nana Agradaa ṣe yipada kuro ni iya alawo, to si di ajinhinrere?
Ọdun to kọja ni Nada Agradaa kede pe oun ko ṣe iṣẹ awo, ati oogun ika mọ, ti oun si ti gba iṣẹ ihinrere.
O kede igbesẹ naa lẹyin ti awọn ọlọpaa gba beeli rẹ lẹyin ti wọn mu u fun ẹsun pe o ni ileeṣẹ tẹlifisan meji ti ko ba ofin mu.
Ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Cedis owo Ghana, ni ile ẹjọ kan ni Accra gba ni beeli rẹ. Ṣugbọn ọpọ eeyan gbagbọ pe oogun sogun-dogoji to n polongo ni wọn ṣe mu.
Nana Agradaa ma n ṣe irubọ oriṣiriṣi lori amohunmaworan rẹ, Thunder TV ati Ice TV, to si ma n sọ pe awọn oriṣa oun le sọ owo di ilọpo meji.
Lẹyin iṣẹlẹ naa lo deede kede pe oun ko sin awọn oriṣa naa mọ, ti oun si ti di atunbi.
O ni “mi o ni ṣiṣẹ awo mọ, bẹẹ ni orukọ mi kii ṣe Nana Agradaa mọ..... Oore kekere kọ ni Oluwa ṣe fun mi, o pe mi, o tun fun mi ni igbala.”
Ikede naa jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan ni Ghana.
Awọn kan si sọ lori ayelujara nigba naa pe ọna lati fi ẹsin Kristẹni boju, maa tẹsiwaju ninu owo sogun-dogoji rẹ ni ikede naa.
Lẹyin ikede rẹ lo da ile ijọsin Heaven Way Church silẹ ni agbegbe Wejia, nilu Accra.














