'Àwa Ebira tí wà ní Owo fún "Donkey years" ẹ má na ìka àbùkù sí wa lórí ìkọlù Kátólíìkì Owo'
"Bí Ọ́lọ́run bá ṣeé tí ọwọ wa tẹ àwọn tó páàyàn ní Ìjọ Kátólíìkì Owo, a ò lu jẹ̀jẹ̀rẹ̀ sí wọn lára ká tó pe agbófinró"
Awọn Ebira Ondo ti sọrọ pe ki awọn eeyan ma na ika abuku si awọn lori ikọlu ijọ Katoliiki ilu Owo nipinlẹ Ondo to waye loṣu bii melo kan sẹyin.
Olubadamọran tẹlẹri fun gomina ipinlẹ Ondo lori ọrọ to kan awọn ẹya Ebira, to n gbe ni ipinlẹ naa, Hassan Ahette ba BBC Yoruba sọrọ to ṣi ṣalaye iha ti awọn ẹya Ebira ni Ondo kọ si iṣẹlẹ to waye ni ijọ Katoliiki ilu Owo.
Iṣẹlẹ naa jẹ eyi ti awọn to ṣekọlu sibẹ pa ọpọlọpọ eniyan.
Eyi jẹ esi si ero awọn eeyan kaakiri ti wọn ro pe awọn eeyan Ebira lo ṣe ikọlu si ijọ Katoliiki Owo naa.














