Gbogbo eͅnu la fi sóͅ pé a wà léͅyìn Peter Obi fún ààreͅ lóͅdún 2023 – Aféͅniféͅre

Oríṣun àwòrán, Google
Eͅgbeͅ Afeͅnifeͅre ti ni gbogbo ara ni awoͅn fi wa ni eͅyin oludije sipo Aareͅ ni eͅgbeͅ osͅelu Labour, Peter Obi ni idibo sipo gbogboogbo ti yoo waye ni oͅdun to n boͅ. Eͅgbeͅ ileͅ Yoruba naa n fesi si oͅroͅ ti gomina ipinleͅ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu soͅ wi pe eͅgbeͅ Afeͅnifeͅreͅ ko sͅoro fun gbogbo oͅmoͅ Yoruba nipa bibuwoͅlu Peter Obi.
Ninu ateͅjade ti eͅgbeͅ Afeͅnifeͅre fi sita ni woͅn ti fi ero woͅn ati atileͅyin woͅn han fun Peter Obi.
Eͅgbeͅ Afeͅnifeͅre ni igbeseͅ woͅn lati ti Obi leͅyin ko sͅeͅyin igbimoͅpoͅ awoͅn eͅgbeͅ to n sͅoju awoͅn eyͅa ni orileͅede Naijiria. Ninu oroͅ woͅn, eͅgbeͅ afeͅnifeͅre ni awoͅn ri pe Obi lo kunjuwoͅn lati di aareͅ orileͅede Naijiria.
Oͅdún kan la fi jíròrò eͅni tí eͅgbẹ́ Afeͅnifeͅre fẹ́ tẹ̀lé ní ìdìbò oͅdún 2023
‘’Obi ti di ipo gomina ipinleͅ Anambra mu fun saa meji, ti o si ni ipileͅ rere ni ilu naa , geͅgeͅ bi eͅni to fi ti ara ilu sͅe.’’
‘’Ni otitoͅ la gba pe ki ipo aareͅ sun loͅ si Guusu orileͅede Naijiria, amoͅ kii sͅe ileͅ Yoruba lo kan nitori awoͅn eͅya miran ti ko I tii sͅe lo sunkan’’
‘’Kii si sͅe eͅgbeͅ oͅmoͅ Yoruba nikan lo fi ero yii han nitori oͅdun kan gbako ni a fi jiroro lori eͅni ti a feͅ sͅe atileͅyin fun.’’
‘’Bio tileͅ jeͅpe a boͅwoͅ fun gomina ipinleͅ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ati awoͅn gomina to ku ni ileͅ Yoruba, igbagboͅ wa nipe leͅyin oͅdun meͅjoͅ aareͅ Buhari, iha Guusu ni eͅya Igbo ni ki aareͅ orileͅede Naijiria ti wa.’’
‘’A feͅ ki gbogbo aye moͅ pe eͅgbeͅ Afeͅnifeͅre kii sͅe ateͅmeͅreͅ ninu oͅroͅ osͅelu, igbagboͅ wa si ni pe bi baba wa Awolowo sͅe gbe kaleͅ fun wa ni ki a teͅle .’’
‘’Iyeͅn ni pe otitoͅ lai si ireͅjeͅ tabi iyannijeͅ ni eto osͅelu, ki ipo loͅ si ibi to yeͅ ko loͅ lai fi ti eͅya kankan ti si ibi kan.’’
Bakan naa ni eͅgbeͅ Afeͅnifeͅre naa roͅ gboͅgboͅto feͅ ki alaafia joͅba ni Naijiria lati moͅ pe Ariwa orileͅede nikan koͅ lo ni ijoͅba nikan.
Afenifere kò gbẹnu ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀ o, Tinubu la máa dìbò fún - Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu ti ní ẹgbẹ́ Afenifere kò gba ẹnu àwọn ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀ rárá lórí bí alága ẹgbẹ́ náà, Pa Ayo Adebanjo ṣe jan olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi ní òǹtẹ̀ fún ipò Ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2023.
Láti bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni alága ẹgbẹ́ Afenifere, Pa Ayo Adebanjo ti ní ẹ̀yìn Peter Obi ni òun pọ̀n sí láti dupò Ààrẹ Nàìjíríà.
Pa Adebanjo ní ìdí tí òun fi tò sẹ́yìn Obi ni wí pé ẹ̀yà Igbo ló kàn láti ṣe Ààrẹ orílẹ̀èdè yìí nítorí ẹ̀yà Yorùbá àti Hausa ti ṣe Ààrẹ kọjá àmọ́ Igbo kò ì tíì débẹ̀.
Ìpinnu Pa Adebanjo ti fa onírúurú awuyewuye láàárín àwọn ènìyàn pàápàá àwọn Yorùbá tó gbàgbọ́ wí pé ọmọ ẹni kò ní ṣe ìdí bẹ̀bẹ̀rẹ̀ ká wá kó ìlẹ̀kẹ̀ sídìí ọmọ ẹlòmíràn.
Ẹ̀wẹ̀, gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo Rotimi Akeredolu ní ohun tí ẹgbẹ́ Afenifere sọ náà kìí ṣe ohun tí gbogbo àwọn Yorùbá fọwọ́ sí.
Akeredolu ní kódà nínú ẹgbẹ́ Afenifere gan ìyapa ẹnu ti ń wà lórí ìpinnu yìí nítorí àwọn kàn nínú ẹgbẹ́ náà kò faramọ́ ìkéde Pa Adebanjo.
Ó ní olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Bola Tinubu nìkan ni olùdíje tó le mú àyípadà ọ̀tun bá gbogbo ìpèníjà tó ń bá orílẹ̀èdè Nàìjíríà fínra.
Ó fi kún un pé ṣíṣe ètò ìjọba àpapọ̀ tòótọ́ nìkan ni o le mú ìgbà tuntun bá Nàìjíríà tó sì le tẹ orílẹ̀ èdè yìí síwájú.
Akeredolu nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusó rẹ̀ Richard Olatunde fi síta ní òun ní ìgbàgbọ́ pé ti Tinubu bá di Ààrẹ ó ma ṣe ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gómínà ń bèèrè fún.
Ó tẹ̀síwájú pé Tinubu nìkan ló ní ìrírí ìjọba àwaarawa jùọ nínú gbogbo àwọn tí wọ́n jọ ń díje sípò Ààrẹ Nàìjíríà.
“Tinubu nìkan ló ní ìrírí tó péye láti ṣe àtúnṣe sí gbogbo ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà là kọjá gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣe nígbà tó wà nípò bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Eko.”
Bákan náà ló fi kun pé tí Tinubu bá di Ààrẹ gbogbo ẹ̀yà ni yóò ráyè nínú ìjọba rẹ̀ láìní fi ti tẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà ṣe.
“Nígbà tí Tinubu ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Eko gbogbo ẹ̀yà ló kó sínú ìjọba rẹ̀ tí èyí sì ṣokùnfà ìdí tí àwọn ẹ̀yà bíi Hausa, Igbo ṣe le wá sí ìpínlẹ̀ Eko fún ọrọ̀ ajé.”















