Ooni, Deji, Akarigbo àtàwọn ọbalayé ilẹ̀ Yorùbá míràn tó gba àmì ẹ̀yẹ àpapọ̀ Nàìjíríà rèé

Aworan Ooni ati aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, BuhariSallauOnline

Eto ayẹyẹ ami ẹyẹ apapọ orilẹede Naijiria waye lọjọ Isegun.

Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari lo lewaju ayẹyẹ naa nibi ti o ti fun ojilelerinwo ati mẹsan an awọn eekan ọmọ Naijiria lami ẹyẹ .

Ooni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji lolewaju awọn ọba lati ilẹ Yoruba ti wọn fun lami ẹyẹ nibi ayẹyẹ naa.

Ooni Adeyẹye Ogunwusi gba ami ẹyẹ CFR fun ipa ribiribi to n ko ninu iṣọkan ati idagbasoke orilẹede Naijiria.

Lara awọn ọbalaye ilẹ Yoruba to tun gba ami ẹyẹ nibẹ ni Deji ilu Akure , Oba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi, Odundun keji togba ami ẹyẹ CFR;

Ọba Babatunde Adewale Ajayi, Akarigbo ti ilu Rẹmọ ni ipinlẹ Ogun pẹlu ami ẹyẹ CFR; Bakan naa lami ẹyẹ tun kan Oba Gabriel Adewọn Oniṣan ti ilu Iṣan Ekiti (CFR); Oba Adefarakanmi Agbede, Olowa of Igbara-Oke (OFR).

Awọn eekan ọmọ Yoruba miran to gba ami ẹyẹ nibẹ ni olori ile aṣojuṣofin, Họnọrebu Femi Gbajabiamila CFR; gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ to tun jẹ minisita fun iṣẹ ode bayii, Amofin agba Babatunde Fashola SAN CON, gomina ipinlẹ Ondo, Amofin agba Rotimi Akeredolu SAN, CON; Oludasilẹ ileeṣẹ tẹtẹ baba ijebu, Oloye Adebutu Kessington CFR, Femi Adeṣina OON.

Bakan naa ni ijọọba apapọ Naijiria tun ranti gbajumọ atamatase agbabọọlu Naijiria to ti di Oloogbe, Rashidi Yekini pẹlu ami ẹyẹ MON.

Gbajumọ akọrin Fuji, Wasiu Ayinde Marshal MON pẹlu Abike Dabiri Erewa OON at’awọn miran naa gba ami ẹyẹ nipele n pele gbogbo.

Bẹẹ naa ni Teniola Akpata naa gba ami ẹyẹ fun ipa to ko lagbo orin Naijiria.

Aworan awọn ti aarẹ Buahrifi ami ẹyẹ da lọla

Oríṣun àwòrán, BuhariSallauOnline

Aworan awọn ti aarẹ fi ami ẹyẹ da lọla

Oríṣun àwòrán, BuhariSallauOnline

Aworan awọn ti aarẹ Buhari da lọla ami ẹyẹ

Oríṣun àwòrán, BuhariSallauOnline